2 Kíróníkà 33:1-25
33 Ẹni ọdún méjìlá ni Mánásè+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún márùn-dín-lọ́gọ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+
2 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
3 Nítorí náà, ó tún àwọn ibi gíga+ tí Hesekáyà baba rẹ̀ bì wó kọ́,+ ó sì gbé àwọn pẹpẹ kalẹ̀+ fún àwọn Báálì,+ ó sì ṣe àwọn òpó ọlọ́wọ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba+ fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,+ ó sì ń sìn wọ́n.+
4 Ó sì mọ àwọn pẹpẹ+ sí ilé Jèhófà, èyí tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni orúkọ mi yóò máa wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+
5 Ó sì ń bá a lọ láti mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run+ sí àgbàlá méjì+ nínú ilé Jèhófà.+
6 Òun alára sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ la iná+ kọjá ní àfonífojì ọmọ Hínómù,+ ó sì ń pidán,+ ó sì ń woṣẹ́,+ ó sì ń ṣe iṣẹ́ oṣó,+ ó sì mú kí àwọn abẹ́mìílò+ àti àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀+ ìṣẹ̀lẹ̀ wà. Ní ìwọ̀n tí ó bùáyà ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, láti mú un bínú.+
7 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó gbé ère gbígbẹ́+ tí ó ṣe sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ èyí tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti fún Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn+ nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni èmi yóò fi orúkọ mi+ sí fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
8 Èmi kì yóò sì tún ṣí ẹsẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo fi fún+ àwọn baba ńlá wọn,+ kìkì bí wọ́n bá sáà ti kíyè sí àtiṣe gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ+ ní ti gbogbo òfin+ àti àwọn ìlànà+ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́+ láti ọwọ́ Mósè.”+
9 Mánásè+ sì ń bá a nìṣó ní sísún Júdà+ àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù dẹ́ṣẹ̀ láti ṣe ohun tí ó burú ju+ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
10 Jèhófà sì ń bá Mánásè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣáá, ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀.+
11 Níkẹyìn, Jèhófà mú àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí í ṣe ti ọba Ásíríà+ wá láti gbéjà kò wọ́n,+ nítorí náà, wọ́n mú Mánásè ní àwọn ibi jíjinkòtò,+ wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é,+ wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì.
12 Gbàrà tí ó sì ti fa wàhálà bá a,+ ó tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú,+ ó sì ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀+ gidigidi nítorí Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀.
13 Ó sì ń gbàdúrà sí I ṣáá, tí ó fi jẹ́ pé Ó jẹ́ kí ó pàrọwà+ sí òun, Ó sì gbọ́ ìbéèrè rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba+ rẹ̀; Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+
14 Lẹ́yìn èyí, ó mọ ògiri ti ẹ̀yin òde+ fún Ìlú Ńlá Dáfídì,+ síhà ìwọ̀-oòrùn Gíhónì+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá àti títí dé Ẹnubodè Ẹja,+ ó sì mọ ọ́n lọ dé Ófélì,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí ó ga gan-an. Síwájú sí i, ó fi àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun sí gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà.+
15 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè+ àti ère òrìṣà+ náà kúrò ní ilé Jèhófà àti gbogbo àwọn pẹpẹ+ tí ó mọ sí òkè ńlá ilé Jèhófà àti sí Jerúsálẹ́mù, ó sì mú kí a sọ wọ́n sí òde ìlú ńlá náà lẹ́yìn náà.
16 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó pèsè pẹpẹ Jèhófà sílẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́+ lórí rẹ̀, ó sì ń bá a lọ ní sísọ fún Júdà pé kí wọ́n máa sin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
17 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn náà ṣì ń rúbọ lórí àwọn ibi gíga;+ kìkì pé ó jẹ́ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn nìkan.
18 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Mánásè àti àdúrà+ rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwọn olùríran+ tí ń bá a sọ̀rọ̀ ṣáá ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ibẹ̀ ni wọ́n wà nínú àwọn àlámọ̀rí àwọn ọba Ísírẹ́lì.+
19 Ní ti àdúrà+ rẹ̀ àti bí a ṣe fún un ní àwọn ohun tí ó pàrọwà+ fún àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀+ àti ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀+ àti àwọn ibi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga+ sí, tí ó sì gbé àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ nà ró sí àti àwọn ère fífín+ kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,+ ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú ọ̀rọ̀ àwọn olùríran rẹ̀.
20 Níkẹyìn, Mánásè dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín+ sí ilé rẹ̀; Ámọ́nì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.
21 Ẹni ọdún méjìlélógún ni Ámọ́nì+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún méjì sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+
22 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Mánásè baba rẹ̀ ti ṣe;+ Ámọ́nì sì rúbọ+ sí gbogbo àwọn ère fífín+ tí Mánásè+ baba rẹ̀ ṣe, ó sì ń bá a lọ ní sísìn wọ́n.+
23 Kò sì rẹ ara rẹ sílẹ̀+ nítorí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Mánásè baba rẹ̀ ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,+ nítorí Ámọ́nì jẹ́ ẹni tí ó mú kí ẹ̀bi pọ̀ sí i.+
24 Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí i, wọ́n sì fi ikú pa á nínú ilé rẹ̀.+
25 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ṣá+ gbogbo àwọn tí ó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí Ámọ́nì Ọba+ balẹ̀, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà+ sì fi Jòsáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

