2 Kíróníkà 30:1-27

30  Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí ránṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì+ àti Júdà, ó tilẹ̀ kọ lẹ́tà sí Éfúráímù+ àti Mánásè,+ pé kí wọ́n wá sí ilé Jèhófà+ ní Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe ìrékọjá+ sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 2  Àmọ́ ṣá o, ọba àti àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀ àti gbogbo ìjọ+ ní Jerúsálẹ́mù pinnu láti ṣe ìrékọjá náà ní oṣù kejì;+ 3  nítorí wọ́n kò tíì lè ṣe é ní àkókò yẹn,+ nítorí pé ní ọwọ́ kan, iye àwọn àlùfáà+ tí ó ti sọ ara wọn di mímọ́ kò tó, ní ọwọ́ kejì, àwọn ènìyàn náà kò tíì kó ara wọn jọ sí Jerúsálẹ́mù. 4  Ohun náà sì tọ̀nà ní ojú ọba àti ní ojú gbogbo ìjọ.+ 5  Nítorí náà, wọ́n pinnu láti mú kí ìpè+ náà la gbogbo Ísírẹ́lì já, láti Bíá-ṣébà+ dé Dánì,+ pé kí wọ́n wá ṣe ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù; nítorí wọn kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀+ gẹ́gẹ́ bí ògìdìgbó ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé rẹ̀.+ 6  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn sárésáré+ lọ jákèjádò gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà pẹ̀lú àwọn lẹ́tà láti ọwọ́ ọba àti àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀, àní ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ọba, wí pé: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ padà+ sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, kí ó lè padà sọ́dọ̀ àwọn olùsálà+ tí ó ṣẹ́ kù lára yín láti inú àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọba Ásíríà.+ 7  Ẹ má sì dà bí àwọn baba ńlá+ yín àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, tí ó fi jẹ́ pé ó sọ wọ́n di ohun ìyàlẹ́nu,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń rí i. 8  Wàyí o, ẹ má ṣe mú ọrùn+ yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín ti ṣe. Ẹ fi àyè fún Jèhófà,+ ẹ sì wá sínú ibùjọsìn+ rẹ̀, èyí tí ó ti sọ di mímọ́+ fún àkókò tí ó lọ kánrin kí ẹ sì máa sin+ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ìbínú rẹ̀ jíjófòfò+ lè yí padà kúrò lọ́dọ̀ yín. 9  Nítorí pé nígbà tí ẹ bá padà+ sọ́dọ̀ Jèhófà, àwọn arákùnrin yín àti àwọn ọmọ yín yóò jẹ́ àwọn tí a fi àánú+ hàn sí níwájú àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè, a ó sì yọ̀ǹda fún wọn láti padà sí ilẹ̀ yìí;+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ olóore ọ̀fẹ́+ àti aláàánú,+ òun kì yóò sì yí ojú kúrò lọ́dọ̀ yín bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 10  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn sárésáré+ ń bá a lọ, tí wọ́n ń kọjá lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá jákèjádò ilẹ̀ Éfúráímù+ àti Mánásè, àní dé Sébúlúnì; ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ̀rọ̀ sí wọn ṣáá lọ́nà ìfiniṣẹlẹ́yà, wọ́n sì ń fi wọ́n ṣẹ̀sín.+ 11  Kìkì àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan+ láti Áṣérì àti Mánásè àti láti Sébúlúnì ni ó rẹ ara wọn sílẹ̀+ tí wọ́n fi wá sí Jerúsálẹ́mù. 12  Ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sì wà ní Júdà pẹ̀lú láti fún wọn ní ọkàn-àyà+ kan ṣoṣo láti pa àṣẹ+ ọba àti ti àwọn ọmọ aládé mọ́ nínú ọ̀ràn Jèhófà.+ 13  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọpọ̀ sí Jerúsálẹ́mù,+ àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye, láti ṣe àjọyọ̀+ àwọn àkàrà aláìwú ní oṣù kejì,+ ìjọ tí ó jẹ́ ògìdìgbó púpọ̀ gan-an. 14  Nígbà náà ni wọ́n dìde, wọ́n sì mú àwọn pẹpẹ+ tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù kúrò, gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí+ sì ni wọ́n mú kúrò lẹ́yìn náà, wọ́n sì sọ wọ́n sínú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì.+ 15  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n pa ẹran ẹbọ ìrékọjá+ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì; àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pàápàá ni a sì ti tẹ́ lógo, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n sọ ara wọn di mímọ́,+ wọ́n sì mú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun wá sí ilé Jèhófà. 16  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní dídúró+ ní ipò wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àfilélẹ̀ wọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, àwọn àlùfáà+ ń wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbà ní ọwọ́ àwọn ọmọ Léfì. 17  Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ náà tí kò tíì sọ ara wọn di mímọ́; àwọn ọmọ Léfì+ sì ni ó wà ní àbójútó pípa àwọn ẹran ẹbọ ìrékọjá+ fún gbogbo àwọn tí kò mọ́, láti sọ wọ́n di mímọ́ fún Jèhófà. 18  Nítorí iye àwọn ènìyàn púpọ̀ ní ń bẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti inú Éfúráímù+ àti Mánásè,+ Ísákárì àti Sébúlúnì,+ tí kò tíì wẹ ara wọn mọ́,+ nítorí wọn kò jẹ ìrékọjá ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé rẹ̀;+ ṣùgbọ́n Hesekáyà gbàdúrà fún wọn+ pé: “Kí Jèhófà olóore+ fi àyè ìyọ̀ǹda sílẹ̀ fún 19  olúkúlùkù tí ó ti múra ọkàn-àyà+ rẹ̀ sílẹ̀ láti wá Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà, Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láìsí ìwẹ̀mọ́gaara fún ohun tí ó jẹ́ mímọ́.”+ 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fetí sí Hesekáyà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá.+ 21  Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jerúsálẹ́mù fi ayọ̀ yíyọ̀+ ńláǹlà ṣe àjọyọ̀+ àwọn àkàrà aláìwú ní ọjọ́ méje; àwọn ọmọ Léfì+ àti àwọn àlùfáà+ sì ń fi àwọn ohun èlò orin olóhùn gooro mú ìyìn wá fún Jèhófà lójoojúmọ́, àní fún Jèhófà.+ 22  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Hesekáyà bá ọkàn-àyà+ gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ń fi ọgbọ́n inú tí ó dára púpọ̀ gbé ìgbésẹ̀ fún Jèhófà sọ̀rọ̀.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àsè tí a yàn kalẹ̀ náà fún ọjọ́ méje,+ wọ́n ń rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀,+ wọ́n sì ń ṣe ìjẹ́wọ́+ fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 23  Nígbà náà ni gbogbo ìjọ pinnu+ láti ṣe é fún ọjọ́ méje sí i,+ bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ṣe é fún ọjọ́ méje pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀. 24  Nítorí Hesekáyà ọba Júdà alára fi ẹgbẹ̀rún akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn ṣe ìtọrẹ+ fún ìjọ náà, àwọn ọmọ aládé+ alára sì fi ẹgbẹ̀rún akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àgùntàn ṣe ìtọrẹ fún ìjọ náà; iye púpọ̀ àwọn àlùfáà+ sì ń bá a nìṣó ní sísọ ara wọn di mímọ́. 25  Gbogbo ìjọ Júdà+ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì+ àti gbogbo ìjọ tí ó wá láti Ísírẹ́lì+ àti àwọn àtìpó+ tí ó wá láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì+ àti àwọn tí ń gbé ní Júdà sì ń bá a lọ ní yíyọ̀.+ 26  Ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà sì wá wà ní Jerúsálẹ́mù, nítorí pé láti ọjọ́ Sólómọ́nì+ ọmọkùnrin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì kò sí ọ̀kan bí èyí ní Jerúsálẹ́mù.+ 27  Níkẹyìn, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, dìde dúró, wọ́n sì súre+ fún àwọn ènìyàn náà; a sì fetí sí ohùn wọn, tí ó fi jẹ́ pé àdúrà wọ́n dé ibùgbé rẹ̀ mímọ́, ní ọ̀run.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé