2 Kíróníkà 21:1-20

21  Níkẹyìn, Jèhóṣáfátì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ sí Ìlú Ńlá Dáfídì; Jèhórámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 2  Ó sì ní àwọn arákùnrin, àwọn ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì, Asaráyà àti Jéhíélì àti Sekaráyà àti Asaráyà àti Máíkẹ́lì àti Ṣẹfatáyà, gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ọba Ísírẹ́lì. 3  Nítorí náà, baba wọn fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀+ tí ó jẹ́ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun ààyò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà;+ ṣùgbọ́n Jèhórámù+ ni ó fi ìjọba fún, nítorí òun ni àkọ́bí.+ 4  Nígbà tí Jèhórámù dìde sórí ìjọba baba rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí mú ipò rẹ̀ lágbára, nítorí náà, ó fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin+ rẹ̀ àti àwọn kan lára àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì pẹ̀lú. 5  Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni Jèhórámù nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́jọ sì ni ó fi jọba+ ní Jerúsálẹ́mù. 6  Ó sì ń bá a lọ ní rírìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilé Áhábù ti ṣe; nítorí ọmọbìnrin Áhábù ni ó di aya rẹ̀,+ ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ 7  Jèhófà kò sì fẹ́ run ilé Dáfídì,+ nítorí májẹ̀mú+ tí ó ti bá Dáfídì dá, àti gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò fún òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní fìtílà nígbà gbogbo.+ 8  Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, Édómù+ dìtẹ̀ kúrò lábẹ́ ọwọ́ Júdà,+ wọ́n sì wá fi ọba jẹ lé ara wọn lórí.+ 9  Nítorí náà, Jèhórámù pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí rẹ̀ ré kọjá àti bákan náà gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ó dìde ní òru, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọmọ Édómù tí ó yí i ká balẹ̀ àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú. 10  Ṣùgbọ́n Édómù ń bá ìdìtẹ̀ rẹ̀ nìṣó kúrò lábẹ́ ọwọ́ Júdà títí di òní yìí. Ìgbà náà ni Líbínà+ bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ ní àkókò kan náà kúrò lábẹ́ ọwọ́ rẹ̀, nítorí tí ó ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀.+ 11  Òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ṣe àwọn ibi gíga+ lórí àwọn òkè ńlá Júdà, kí ó lè mú kí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe,+ kí ó sì lè lé Júdà lọ.+ 12  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìwé kan+ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èlíjà+ wòlíì, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ wí, ‘Nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ kò rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhóṣáfátì+ baba rẹ tàbí ní àwọn ọ̀nà Ásà+ ọba Júdà, 13  ṣùgbọ́n ìwọ ń rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ o sì mú kí Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe+ ní ọ̀nà kan náà tí ilé Áhábù fi ṣokùnfa níní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe,+ àwọn arákùnrin tìrẹ pàápàá, agbo ilé baba rẹ, àwọn tí ó sàn jù ọ́ lọ, ni o sì ti pa;+ 14  wò ó! Jèhófà yóò mú ìyọnu àgbálù ńlá+ bá àwọn ènìyàn rẹ+ àti àwọn ọmọ rẹ+ àti àwọn aya rẹ àti gbogbo ẹrù rẹ. 15  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn yóò sì ṣe ọ́, pẹ̀lú àrùn+ kan nínú àwọn ìfun rẹ, títí àwọn ìfun rẹ yóò fi tú jáde nítorí àìsàn náà ní ọjọ́ dé ọjọ́.’”+ 16  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà ru ẹ̀mí+ àwọn Filísínì+ àti ti àwọn ará Arébíà+ tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ará Etiópíà+ dìde sí Jèhórámù. 17  Nítorí náà, wọ́n gòkè wá sí Júdà, wọ́n sì fi ipá wọ inú rẹ̀, wọ́n sì kó gbogbo ẹrù tí ó wà nínú ilé+ ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀+ pẹ̀lú ní òǹdè, wọn kò sì ṣẹ́ ọmọkùnrin kan kù fún un bí kò ṣe Jèhóáhásì,+ ọmọkùnrin rẹ̀ àbíkẹ́yìn. 18  Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhófà fi àìsàn kan tí kò ṣeé wò sàn mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá a nínú àwọn ìfun rẹ̀.+ 19  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní àwọn ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, àní nígbà tí sáà ọdún méjì gbáko parí, ìfun+ rẹ̀ tú jáde nígbà àìsàn rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú nínú àwọn àrùn búburú rẹ̀; àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣe ìfinásun fún un bí ìfinásun+ tí wọ́n ṣe fún àwọn baba ńlá rẹ̀. 20  Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó jẹ́ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́jọ sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Níkẹyìn, ó lọ láìdunni.+ Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe sí àwọn ibi ìsìnkú àwọn ọba.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé