2 Kíróníkà 20:1-37

20  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn kan lára àwọn Ámónímù+ pẹ̀lú wọn wá láti dojú kọ Jèhóṣáfátì nínú ogun.+  Nítorí náà, àwọn ènìyàn wá sọ fún Jèhóṣáfátì, pé: “Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti wá gbéjà kò ọ́ láti ẹkùn ilẹ̀ òkun, láti Édómù;+ àwọn sì nìyẹn ní Hasasoni-támárì, èyíinì ni, Ẹ́ń-gédì.”+  Látàrí ìyẹn, àyà fo+ Jèhóṣáfátì, ó sì gbé ojú rẹ̀ lé wíwá Jèhófà.+ Nítorí náà, ó pòkìkí ààwẹ̀ gbígbà+ fún gbogbo Júdà.  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ti Júdà kóra jọpọ̀ láti ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Àní láti gbogbo ìlú ńlá Júdà ni wọ́n ti wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.+  Nígbà náà ni Jèhóṣáfátì dìde dúró nínú ìjọ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù nínú ilé Jèhófà+ níwájú àgbàlá tuntun,+  ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé:+ “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa,+ ìwọ ha kọ́ ni Ọlọ́run ní ọ̀run,+ ìwọ kò ha sì ń jọba lé gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè,+ agbára àti agbára ńlá kò ha sì sí ní ọwọ́ rẹ, tí kò fi sí ẹnì kankan tí ó lè kò ọ́ lójú?+  Ìwọ fúnra rẹ, Ọlọ́run wa,+ ha kọ́ ni ó lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí lọ kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì+ tí o sì wá fi fún+ irú-ọmọ Ábúráhámù, olùfẹ́ rẹ,+ fún àkókò tí ó lọ kánrin?  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú rẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti kọ́ ibùjọsìn fún orúkọ rẹ sínú rẹ̀ fún ọ,+ wọ́n wí pé,  ‘Bí ìyọnu àjálù,+ idà, ìdájọ́ aláìbáradé, tàbí àjàkálẹ̀ àrùn+ tàbí ìyàn+ bá dé bá wa, ẹ jẹ́ kí a dúró níwájú ilé+ yìí àti níwájú rẹ (nítorí tí orúkọ+ rẹ wà nínú ilé yìí), kí a lè ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ nínú wàhálà wa, kí o sì gbọ́ kí o sì gbà wá là.’+ 10  Wàyí o, kíyè sí i, àwọn ọmọ Ámónì,+ àti Móábù+ àti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì,+ àwọn tí o kò yọ̀ǹda fún Ísírẹ́lì láti gbógun tì nígbà tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì, ṣùgbọ́n wọ́n yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n rẹ́,+ 11  bẹ́ẹ̀ ni, kíyè sí i, wíwọlé wá láti lé wa jáde kúrò nínú ohun ìní rẹ tí o mú kí a ní+ ni wọ́n fi ń san wá lẹ́san.+ 12  Ìwọ Ọlọ́run wa, ìwọ kì yóò ha mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lé wọn lórí?+ Nítorí pé kò sí agbára kankan nínú wa níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí tí ń bọ̀ wá gbéjà kò wá;+ àwa alára kò sì mọ ohun tí à bá ṣe,+ ṣùgbọ́n ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.”+ 13  Ní gbogbo àkókò yìí, gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ti Júdà wà lórí ìdúró níwájú Jèhófà,+ àní àwọn ọmọ wọn kéékèèké,+ àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn pàápàá. 14  Wàyí o, ní ti Jahasíẹ́lì ọmọkùnrin Sekaráyà ọmọkùnrin Bẹnáyà ọmọkùnrin Jéélì ọmọkùnrin Matanáyà ọmọ Léfì láti inú àwọn ọmọ Ásáfù,+ ẹ̀mí+ Jèhófà wá bà lé e ní àárín ìjọ. 15  Nítorí náà, ó wí pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo Júdà àti ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù àti Jèhóṣáfátì Ọba! Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún yín, ‘Ẹ má fòyà+ tàbí kí ẹ jáyà nítorí ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí; nítorí pé ìjà ogun náà kì í ṣe tiyín, bí kò ṣe ti Ọlọ́run.+ 16  Lọ́la, ẹ sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dojú kọ wọ́n. Kíyè sí i, wọ́n ń gba ọ̀nà àbákọjá Sísì gòkè bọ̀; dájúdájú, ẹ óò rí wọn ní òpin àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ní iwájú aginjù Jérúélì. 17  Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà+ nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́+ kí ẹ sì rí ìgbàlà+ Jèhófà fún yín. Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà.+ Lọ́la, ẹ jáde sí wọn, Jèhófà yóò sì wà pẹ̀lú yín.’”+ 18  Ní kíá, Jèhóṣáfátì tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìdojúbolẹ̀,+ gbogbo Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà láti wárí fún Jèhófà.+ 19  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì+ láti inú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kóhátì+ àti nínú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kórà+ dìde láti fi ohùn dídún ròkè lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ yin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 20  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, wọ́n sì jáde lọ sí aginjù+ Tékóà.+ Bí wọ́n sì ti ń jáde lọ, Jèhóṣáfátì dìde dúró, ó sì wí nígbà náà pé: “Ẹ gbọ́ mi, Júdà àti ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù!+ Ẹ ní ìgbàgbọ́+ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín kí ẹ lè wà pẹ́. Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì+ rẹ̀, kí ẹ sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àṣeyọrí sí rere.” 21  Síwájú sí i, ó fọ̀ràn lọ+ àwọn ènìyàn náà, ó sì yan àwọn akọrin+ fún Jèhófà sípò àti àwọn tí ń mú ìyìn+ wá nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́+ bí wọ́n ti ń jáde lọ ṣíwájú àwọn ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra,+ tí wọ́n sì ń wí pé: “Ẹ fi ìyìn fún Jèhófà,+ nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 22  Ní àkókò tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ igbe ìdùnnú àti ìyìn, Jèhófà fi àwọn ènìyàn sí ibùba+ de àwọn ọmọ Ámónì, Móábù àti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì tí ń bọ̀ ní Júdà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.+ 23  Àwọn ọmọ Ámónì àti Móábù sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun àti láti pa wọ́n rẹ́ ráúráú; gbàrà tí wọ́n sì ti yanjú àwọn olùgbé Séírì+ tán, wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ ẹnì kìíní láti run ẹnì kejì rẹ̀.+ 24  Ṣùgbọ́n ní ti Júdà, ó dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní aginjù.+ Nígbà tí wọ́n yíjú sí ogunlọ́gọ̀ náà, họ́wù, àwọn nìyẹn, tí òkú wọ́n ṣubú sí ilẹ̀+ láìsí ẹnikẹ́ni tí ó sá àsálà. 25  Nítorí náà, Jèhóṣáfátì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wá láti piyẹ́ ohun ìfiṣèjẹ+ tí ń bẹ lára wọn, wọ́n sì wá rí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹrù àti aṣọ àti àwọn ohun èlò fífani-lọ́kàn-mọ́ra lára wọn; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ wọn kúrò fún ara wọn títí wọn kò fi lè kó wọn mọ́.+ Ọjọ́ mẹ́ta sì ni wọ́n fi ń piyẹ́ ohun ìfiṣèjẹ náà, nítorí pé ó pọ̀ yanturu. 26  Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ pọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Bérákà, nítorí ibẹ̀ ni wọ́n ti fi ìbùkún fún Jèhófà.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe orúkọ+ ibẹ̀ ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Bérákà—títí di òní. 27  Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin Júdà àti Jerúsálẹ́mù padà dé, pẹ̀lú Jèhóṣáfátì ní iwájú wọn, láti fi ayọ̀ yíyọ̀ padà dé sí Jerúsálẹ́mù, nítorí pé Jèhófà ti mú kí wọ́n yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.+ 28  Nítorí náà, wọ́n dé sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti pẹ̀lú háàpù+ àti kàkàkí+ sí ilé Jèhófà.+ 29  Ìbẹ̀rùbojo+ Ọlọ́run sì wá wà lára gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀ wọnnì nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti bá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jà.+ 30  Nípa báyìí, ilẹ̀ ọba Jèhóṣáfátì kò ní ìyọlẹ́nu, Ọlọ́run rẹ̀ sì ń bá a lọ láti fún un ní ìsinmi yí ká.+ 31  Jèhóṣáfátì+ sì ń bá a lọ ní jíjọba lé Júdà lórí. Ẹni ọdún márùndínlógójì ni ó jẹ́ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà+ ọmọbìnrin Ṣílíháì. 32  Ó sì ń bá a nìṣó ní rírìn ní ọ̀nà Ásà+ baba rẹ̀, kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, nípa ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.+ 33  Kìkì pé àwọn ibi gíga+ kò di àwátì; àwọn ènìyàn náà kò sì tíì múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá+ wọn. 34  Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóṣáfátì, ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jéhù+ ọmọkùnrin Hánáánì,+ èyí tí a kọ sínú Ìwé+ Àwọn Ọba Ísírẹ́lì. 35  Àti lẹ́yìn èyí, Jèhóṣáfátì ọba Júdà ní àjọṣe pẹ̀lú Ahasáyà+ ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó hùwà burúkú.+ 36  Nítorí náà, ó fi í ṣe alájọṣe pẹ̀lú ara rẹ̀ ní kíkan àwọn ọkọ̀ òkun tí yóò lọ sí Táṣíṣì,+ wọ́n sì kan àwọn ọkọ̀ òkun ní Esioni-gébérì.+ 37  Bí ó ti wù kí ó rí, Élíésérì ọmọkùnrin Dódáfáhù ti Márẹ́ṣà sọ̀rọ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Jèhóṣáfátì, pé: “Níwọ̀n bí o ti ní àjọṣe pẹ̀lú Ahasáyà,+ dájúdájú, Jèhófà yóò fọ́ àwọn iṣẹ́ rẹ túútúú.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkọ̀ òkun náà fọ́ bà jẹ́,+ wọn kò sì ní agbára láti fi lọ sí Táṣíṣì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé