2 Kíróníkà 17:1-19

17  Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀, ó sì mú ipò rẹ̀ lágbára lórí Ísírẹ́lì. 2  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi àwọn ẹgbẹ́ ológun sínú gbogbo ìlú ńlá olódi ti Júdà, ó sì fi àwọn ẹgbẹ́ ogun sí ilẹ̀ Júdà àti sínú àwọn ìlú ńlá Éfúráímù tí Ásà baba rẹ̀ ti gbà.+ 3  Jèhófà sì ń bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú Jèhóṣáfátì,+ nítorí pé ó rìn ní àwọn ọ̀nà àtijọ́ ti Dáfídì baba ńlá rẹ̀,+ kò sì wá àwọn Báálì.+ 4  Nítorí pé Ọlọ́run baba rẹ̀ ni ó wá+ àti pé inú àṣẹ rẹ̀ ni ó ti rìn,+ kì í sì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìṣe Ísírẹ́lì.+ 5  Jèhófà sì fìdí ìjọba náà múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọwọ́ rẹ̀;+ gbogbo Júdà sì ń bá a lọ láti fi ẹ̀bùn+ fún Jèhóṣáfátì, ó sì wá ní ọrọ̀ àti ògo ní ọ̀pọ̀ yanturu.+ 6  Ọkàn-àyà rẹ̀ sì di aláìṣojo ní àwọn ọ̀nà+ Jèhófà, ó tilẹ̀ mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ kúrò ní Júdà. 7  Ní ọdún kẹta ìgbà ìjọba rẹ̀, ó ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ aládé rẹ̀, èyíinì ni, Bẹni-háílì àti Ọbadáyà àti Sekaráyà àti Nétánélì àti Mikáyà, pé kí wọ́n máa kọ́ni ní àwọn ìlú ńlá Júdà, 8  àti pẹ̀lú wọn àwọn ọmọ Léfì náà, Ṣemáyà àti Netanáyà àti Sebadáyà àti Ásáhélì àti Ṣẹ́mírámótì àti Jèhónátánì àti Ádóníjà àti Tóbíjà àti Tobu-ádóníjà àwọn ọmọ Léfì, àti pẹ̀lú wọn Élíṣámà àti Jèhórámù àwọn àlùfáà.+ 9  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni+ ní Júdà, ìwé òfin Jèhófà+ sì wà pẹ̀lú wọn; wọ́n sì ń bá a nìṣó ní lílọ yí ká gbogbo àwọn ìlú ńlá Júdà, wọ́n sì ń kọ́ni láàárín àwọn ènìyàn náà. 10  Ìbẹ̀rùbojo+ Jèhófà sì wá wà lára gbogbo ìjọba àwọn ilẹ̀ tí ó wà yí ká Júdà, wọn kò sì bá Jèhóṣáfátì+ jà. 11  Wọ́n sì ń mú ẹ̀bùn+ àti owó gẹ́gẹ́ bí owó òde+ wá fún Jèhóṣáfátì láti ọ̀dọ̀ àwọn Filísínì. Àwọn ará Arébíà+ pẹ̀lú ń mú àwọn agbo ẹran wá fún un, ẹgbàárin àgbò ó dín ọ̀ọ́dúnrún àti ẹgbàárin òbúkọ ó dín ọ̀ọ́dúnrún.+ 12  Jèhóṣáfátì sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú, ó sì di ẹni ńlá+ dé ìwọ̀n gíga lọ́lá; ó sì ń bá a lọ ní kíkọ́ àwọn ibi olódi+ àti àwọn ìlú ńlá ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí+ ní Júdà. 13  Ọ̀pọ̀ sì ni ìpín ìṣúra tí ó di tirẹ̀ ní àwọn ìlú ńlá Júdà; àwọn jagunjagun,+ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin,+ sì wà ní Jerúsálẹ́mù. 14  Ìwọ̀nyí sì ni ipò iṣẹ́ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá wọn: Ti Júdà àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, Ádínáhì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.+ 15  Lábẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Jèhóhánánì olórí, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 16  Lábẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Amasáyà ọmọkùnrin Síkírì tí ó fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda+ ara rẹ̀ fún Jèhófà, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 17  Láti inú Bẹ́ńjámínì,+ Élíádà akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin sì ń bẹ, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá ọkùnrin tí wọ́n fi ọrun àti apata gbára dì sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.+ 18  Lábẹ́ ìdarí rẹ̀ sì ni Jèhósábádì, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ọkùnrin tí wọ́n ti dira láti wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. 19  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba, yàtọ̀ sí àwọn tí ọba fi sínú àwọn ìlú ńlá olódi+ jákèjádò gbogbo Júdà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé