2 Kíróníkà 15:1-19
15 Wàyí o, ní ti Asaráyà ọmọkùnrin Ódédì,+ ẹ̀mí+ Ọlọ́run wá bà lé e.
2 Nítorí náà, ó jáde lọ síwájú Ásà, ó sì wí fún un pé: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀;+ bí ẹ bá sì wá+ a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀.+
3 Ọjọ́ púpọ̀ sì ni Ísírẹ́lì+ fi wà láìní Ọlọ́run tòótọ́ àti láìní àlùfáà tí ń kọ́ni+ àti láìní Òfin.
4 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ nínú wàhálà+ wọn, tí wọ́n sì wá a, nígbà náà, ó jẹ́ kí wọ́n rí òun.+
5 Ní àkókò wọnnì, kò sí àlàáfíà fún ẹni tí ń jáde lọ tàbí fún ẹni tí ń wọlé bọ̀,+ nítorí pé rúgúdù púpọ̀ wà láàárín gbogbo olùgbé ilẹ̀ wọnnì.+
6 A sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè+ àti ìlú ńlá lòdì sí ìlú ńlá, nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fi gbogbo onírúurú wàhálà+ kó wọn sínú rúgúdù.
7 Àti ẹ̀yin, ẹ jẹ́ onígboyà,+ ẹ má sì jẹ́ kí ọwọ́ yín rọ jọwọrọ,+ nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.”+
8 Gbàrà tí Ásà sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ódédì+ wòlíì, ó mọ́kànle, ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí àwọn ohun ìríra+ pòórá ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ní àwọn ìlú ńlá tí ó gbà láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù,+ ó sì sọ pẹpẹ Jèhófà tí ó wà níwájú gọ̀bì Jèhófà+ dọ̀tun.
9 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì+ jọpọ̀ àti àwọn àtìpó+ pẹ̀lú wọn láti Éfúráímù àti Mánásè àti Síméónì, nítorí pé wọ́n ti ya wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì ní iye púpọ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.+
10 Nítorí náà, wọ́n kóra jọpọ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Ásà.
11 Nígbà náà, wọ́n rúbọ sí Jèhófà ní ọjọ́ yẹn láti inú ohun ìfiṣèjẹ tí wọ́n kó wá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin àgùntàn.
12 Síwájú sí i, wọ́n wọnú májẹ̀mú+ láti fi gbogbo ọkàn-àyà wọn àti gbogbo ọkàn wọn wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn;+
13 pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni a ó fi ikú pa,+ yálà ẹni kékeré tàbí ńlá,+ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin.+
14 Nítorí náà, wọ́n fi ohùn rara àti igbe ìdùnnú àti kàkàkí àti ìwo búra+ fún Jèhófà.
15 Gbogbo Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀+ lórí ohun tí wọ́n ṣe ìbúra lé; nítorí pé gbogbo ọkàn-àyà wọn ni wọ́n fi búra àti pé ìdùnnú kíkún níhà ọ̀dọ̀ wọn ni wọ́n fi wá a, tí ó fi jẹ́ kí wọ́n rí òun;+ Jèhófà sì ń bá a lọ láti fún wọn ní ìsinmi yí ká.+
16 Ní ti Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá, Ásà Ọba fúnra rẹ̀+ mú un kúrò ní jíjẹ́ ìyáàfin,+ nítorí tí ó ṣe òrìṣà bíbanilẹ́rù kan fún òpó ọlọ́wọ̀;+ nígbà náà ni Ásà gé òrìṣà+ rẹ̀ bíbanilẹ́rù lulẹ̀, ó sì lọ̀ ọ́ lúúlúú, ó sì sun ún+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì.+
17 Àwọn ibi gíga+ kò sì di àwátì ní Ísírẹ́lì.+ Kìkì pé ọkàn-àyà Ásà pé pérépéré ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀.+
18 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ohun+ tí baba rẹ̀ sọ di mímọ́ àti àwọn ohun tí òun fúnra rẹ̀ sọ di mímọ́ wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́, fàdákà àti wúrà àti àwọn nǹkan èlò.+
19 Ní ti ogun, kò ṣẹlẹ̀ títí di ọdún karùndínlógójì ìgbà ìjọba Ásà.+

