2 Jòhánù 1:1-13
1 Àgbà ọkùnrin+ sí àyànfẹ́ ìyáàfin+ àti sí àwọn ọmọ rẹ̀, tí mo nífẹ̀ẹ́ ní tòótọ́,+ kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣugbọn àti gbogbo àwọn tí ó ti wá mọ òtítọ́,+
2 nítorí òtítọ́ tí ó dúró nínú wa,+ yóò sì wà pẹ̀lú wa títí láé.+
3 Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ àánú àti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba+ àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi Ọmọ Baba, pẹ̀lú òtítọ́ àti ìfẹ́.+
4 Mo yọ̀ gidigidi nítorí pé mo ti rí àwọn kan lára àwọn ọmọ+ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba.+
5 Nítorí náà, nísinsìnyí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ, ìyáàfin, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń kọ̀wé àṣẹ+ tuntun sí ọ, bí kò ṣe ọ̀kan tí a ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,+ pé kí a nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.+
6 Èyí sì ni ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí,+ pé kí a máa bá a lọ ní rírìn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ+ rẹ̀. Èyí ni àṣẹ náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, pé kí ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú rẹ̀.+
7 Nítorí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé,+ àwọn tí kò jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara.+ Èyí ni ẹlẹ́tàn+ àti aṣòdì sí Kristi.+
8 Ẹ máa ṣọ́ ara yín, kí ẹ má bàa pàdánù àwọn ohun tí a ti ṣiṣẹ́ láti mú jáde, ṣùgbọ́n kí ẹ lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.+
9 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ti ara rẹ̀ síwájú,+ tí kò sì dúró+ nínú ẹ̀kọ́ Kristi kò ní Ọlọ́run.+ Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́ yìí ni ẹni tí ó ní Baba àti Ọmọ.+
10 Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé+ yín láé tàbí kí ẹ kí i.+
11 Nítorí ẹni tí ó bá kí i jẹ́ alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.+
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ohun púpọ̀ láti kọ̀wé rẹ̀ sí yín, èmi kò fẹ́ láti fi pépà àti yíǹkì kọ ọ́,+ ṣùgbọ́n mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,+ kí ìdùnnú+ yín lè wà ní ìwọ̀n kíkún.+
13 Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ, ẹni àyànfẹ́, kí ọ.+

