2 Àwọn Ọba 8:1-29
8 Èlíṣà tìkára rẹ̀ sì ti bá obìnrin náà, ọmọkùnrin ẹni tí ó mú sọ jí,+ sọ̀rọ̀ pé: “Dìde, kí o sì lọ, ìwọ àti agbo ilé rẹ, kí o sì ṣe àtìpó ní ibikíbi tí o bá ti lè ṣe àtìpó;+ nítorí Jèhófà ti pè fún ìyàn,+ àti pé, ní àfikún sí i, yóò dé bá ilẹ̀ yìí fún ọdún méje.”+
2 Nítorí náà, obìnrin náà dìde, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, ó sì lọ,+ òun àti agbo ilé rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àwọn Filísínì+ fún ọdún méje.
3 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin ọdún méje pé obìnrin náà padà wá láti ilẹ̀ àwọn Filísínì, ó sì jáde lọ ké bá ọba+ nítorí ilé rẹ̀ àti nítorí pápá rẹ̀.
4 Wàyí o, ọba ń bá Géhásì+ ẹmẹ̀wà ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀, pé: “Jọ̀wọ́, ṣèròyìn gbogbo àwọn ohun ńlá tí Èlíṣà ti ṣe+ fún mi.”
5 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó ti ń ṣèròyìn fún ọba nípa bí ó ṣe mú ẹni tí ó kú sọ jí,+ họ́wù, obìnrin náà, ọmọkùnrin ẹni tí ó mú sọ jí rèé tí ń ké tọ ọba bọ̀ nítorí ilé rẹ̀ àti nítorí pápá+ rẹ̀. Lójú-ẹsẹ̀, Géhásì sọ pé: “Olúwa+ mi ọba, obìnrin náà nìyí, ọmọkùnrin rẹ̀ tí Èlíṣà mú sọ jí sì nìyí.”
6 Látàrí ìyẹn, ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣèròyìn ìtàn+ náà fún un. Nígbà náà ni ọba fún un ní òṣìṣẹ́ kan láàfin,+ ó wí pé: “Dá gbogbo ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ àti gbogbo àmújáde pápá rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi ilẹ̀ yìí sílẹ̀ títí di ìsinsìnyí padà.”+
7 Èlíṣà sì tẹ̀ síwájú láti wá sí Damásíkù;+ Bẹni-hádádì+ ọba Síríà sì ń ṣàìsàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a ròyìn fún un, pé: “Ènìyàn Ọlọ́run+ tòótọ́ ti dé ìhín.”
8 Látàrí ìyẹn, ọba sọ fún Hásáélì+ pé: “Mú ẹ̀bùn+ dání, kí o sì lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì tipasẹ̀ rẹ̀ wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà, pé, ‘Èmi yóò ha sàn nínú àìsàn yìí bí?’”
9 Nítorí náà, Hásáélì lọ pàdé rẹ̀, ó sì mú ẹ̀bùn dání, àní gbogbo onírúurú ohun rere Damásíkù, ogójì ẹrù ràkúnmí, ó sì wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọmọkùnrin+ rẹ, Bẹni-hádádì, ọba Síríà, rán mi sí ọ, pé, ‘Èmi yóò ha sàn nínú àìsàn yìí bí?’”
10 Nígbà náà ni Èlíṣà sọ fún un pé: “Lọ, sọ fún un pé, ‘Dájúdájú, ìwọ yóò sàn,’ Jèhófà sì ti fi hàn+ mí pé, dájúdájú òun yóò kú.”+
11 Ó sì tẹjú mọ́ ọn, ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọn títí dórí ìmáratini. Nígbà náà ni ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.+
12 Látàrí èyí, Hásáélì sọ pé: “Èé ṣe tí olúwa mi fi ń sunkún?” Ó fèsì pé: “Nítorí pé èmi mọ èṣe+ tí ìwọ yóò ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àmọ̀dunjú. Àwọn ibi olódi wọn ni ìwọ yóò gbé lé iná lọ́wọ́, àwọn ààyò ọkùnrin wọn sì ni ìwọ yóò fi idà pa, àwọn ọmọ wọn sì ni ìwọ yóò fọ́ túútúú,+ àwọn aboyún wọn sì ni ìwọ yóò là ní inú.”+
13 Látàrí ìyẹn, Hásáélì sọ pé: “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jẹ́, ẹni tí í ṣe ajá+ lásán-làsàn, tí yóò fi lè ṣe nǹkan ńlá yìí?” Ṣùgbọ́n Èlíṣà sọ pé: “Jèhófà ti fi ọ́ hàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba lórí Síríà.”+
14 Lẹ́yìn ìyẹn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ Èlíṣà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá, ẹni tí ó wá sọ fún un pé: “Kí ni Èlíṣà sọ fún ọ?” Ó fèsì pé: “Ó sọ fún mi pé, ‘Dájúdájú, ìwọ yóò sàn.’”+
15 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé ó tẹ̀ síwájú láti mú aṣọ ìtẹ́lébùsùn, ó sì tẹ̀ ẹ́ bọ omi, ó sì dà á bo ojú+ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú.+ Hásáélì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.
16 Ní ọdún karùn-ún Jèhórámù+ ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jèhóṣáfátì jẹ́ ọba Júdà, Jèhórámù+ ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ọba Júdà, di ọba.
17 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó jẹ́ nígbà tí ó di ọba, ọdún mẹ́jọ ni ó sì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+
18 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ti ilé Áhábù ti ṣe;+ nítorí ọmọbìnrin Áhábù ni ó di aya+ rẹ̀, ó sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú Jèhófà.
19 Jèhófà kò sì fẹ́ run Júdà+ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́+ rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí láti fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní fìtílà+ nígbà gbogbo.
20 Ní ọjọ́ rẹ̀ ni Édómù+ dìtẹ̀ kúrò lábẹ́ ọwọ́ Júdà, tí wọ́n sì fi ọba+ jẹ lórí ara wọn.
21 Nítorí náà, Jèhórámù kọjá lọ sí Sáírì, gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé òun fúnra rẹ̀ dìde ní òru, ó sì ṣá àwọn ọmọ Édómù tí wọ́n yí òun àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ká balẹ̀; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sínú àgọ́ wọn.
22 Ṣùgbọ́n Édómù ń bá ìdìtẹ̀ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọwọ́ Júdà lọ títí di òní yìí. Ìgbà náà ni Líbínà+ bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ ní àkókò yẹn.
23 Àti ìyókù àlámọ̀rí Jèhórámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà?
24 Níkẹyìn, Jèhórámù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá+ rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì.+ Ahasáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.
25 Ní ọdún kejìlá Jèhórámù ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Ahasáyà ọmọkùnrin Jèhórámù ọba Júdà di ọba.+
26 Ẹni ọdún méjìlélógún ni Ahasáyà nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún kan ni ó sì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ataláyà+ ọmọ-ọmọ Ómírì+ ọba Ísírẹ́lì.
27 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà ilé Áhábù,+ ó sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú Jèhófà,+ gẹ́gẹ́ bí ti ilé Áhábù, nítorí ó jẹ́ àna ilé Áhábù.+
28 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó bá Jèhórámù ọmọkùnrin Áhábù lọ láti bá Hásáélì+ ọba Síríà jagun ní Ramoti-gílíádì,+ ṣùgbọ́n àwọn ará Síríà ṣá Jèhórámù balẹ̀.+
29 Nítorí náà, Jèhórámù+ ọba padà láti gba ìmúláradá ní Jésíréélì+ kúrò nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára ní Rámà nígbà tí ó bá Hásáélì ọba Síríà jà. Ní ti Ahasáyà+ ọmọkùnrin Jèhórámù ọba Júdà, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ wo Jèhórámù ọmọkùnrin Áhábù ní Jésíréélì, nítorí pé ó ń ṣàìsàn.

