2 Àwọn Ọba 5:1-27
5 Wàyí o, Náámánì+ kan báyìí, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọba Síríà, ti di ènìyàn ńlá níwájú olúwa rẹ̀, a sì gbé e ga, nítorí pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni Jèhófà fi fún Síríà+ ní ìgbàlà; ọkùnrin náà alára sì wá jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé adẹ́tẹ̀ ni.
2 Àwọn ará Síríà, ní tiwọn, jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí,+ wọ́n sì mú ọmọdébìnrin kékeré+ kan láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ní òǹdè, ó sì wá wà níwájú aya Náámánì.
3 Nígbà tí ó ṣe, ó sọ+ fún olúwa rẹ̀ obìnrin pé: “Ká ní olúwa mi wà níwájú wòlíì+ tí ó wà ní Samáríà ni! Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá wò ó sàn nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”+
4 Lẹ́yìn náà, ẹnì kan wá, ó sì ròyìn fún olúwa ọkùnrin náà, pé: “Báyìí-báyìí ni ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì wá sọ.”+
5 Nígbà náà ni ọba Síríà wí pé: “Gbéra! Wá, sì jẹ́ kí n fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì.” Nítorí náà, ó tẹ̀ síwájú láti lọ, ó sì mú tálẹ́ńtì fàdákà mẹ́wàá àti ẹgbàáta ẹyọ wúrà+ àti ìpààrọ̀ ẹ̀wù mẹ́wàá+ ní ọwọ́+ rẹ̀.
6 Ó sì mú lẹ́tà náà wá fún ọba Ísírẹ́lì, ó wí pé: “Wàyí o, bí lẹ́tà+ yìí bá ṣe ń dé ọ̀dọ̀ rẹ, kíyè sí i, mo rán Náámánì ìránṣẹ́ mi sí ọ, kí o lè wò ó sàn nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
7 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba Ísírẹ́lì ka lẹ́tà náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya,+ ó sì sọ pé: “Ọlọ́run+ ha ni mí, láti fi ikú pa àti láti pa mọ́ láàyè?+ Nítorí ẹni yìí ń ránṣẹ́ sí mi pé kí n wo ọkùnrin kan sàn nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀; ẹ jọ̀wọ́, ẹ sáà ṣàkíyèsí, kí ẹ sì wo bí ó ṣe ń wá ọ̀nà láti bá mi ṣe aáwọ̀.”+
8 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Èlíṣà, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya,+ kíákíá, ó ránṣẹ́ sí ọba, pé: “Èé ṣe tí o fi gbọn ẹ̀wù rẹ ya? Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó wá sọ́dọ̀ mi, kí ó lè mọ̀ pé wòlíì kan ń bẹ ní Ísírẹ́lì.”+
9 Nítorí náà, Náámánì wá, ti òun ti àwọn ẹṣin rẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Èlíṣà.
10 Bí ó ti wù kí ó rí, Èlíṣà rán ońṣẹ́ kan sí i, pé: “Ní lílọ sí ọ̀hún, kí o wẹ̀+ ní ìgbà méje+ nínú Jọ́dánì kí ẹran ara rẹ lè padà sára rẹ;+ kí o sì mọ́.”
11 Látàrí èyí, ìkannú Náámánì ru,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, ó sì sọ pé: “Kíyè sí i, èmi wí fún ara mi+ pé, ‘Yóò jáde wá sọ́dọ̀ mi tààrà, dájúdájú, yóò sì dúró, yóò sì ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lọ síwá-sẹ́yìn lórí ibẹ̀, yóò sì wo adẹ́tẹ̀ náà sàn ní ti tòótọ́.’
12 Ábánà àti Fápárì, àwọn odò Damásíkù,+ kò ha sàn ju gbogbo omi+ Ísírẹ́lì? Ṣé n kò lè wẹ̀ nínú wọn ni kí n sì mọ́+ dájúdájú?” Pẹ̀lú ìyẹn, ó yí padà, ó sì lọ tìhónú-tìhónú.+
13 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sún mọ́ ọn wàyí, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀, wọ́n sì wí pé: “Baba+ mi, ká ní ohun ńlá kan ni wòlíì náà bá ọ sọ, ìwọ kí yóò ha ṣe é bí? Mélòómélòó wá ni, níwọ̀n bí ó ti wí fún ọ pé, ‘Wẹ̀, kí o sì mọ́’?”
14 Látàrí ìyẹn, ó sọ̀ kalẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ri ara rẹ̀ bọ Jọ́dánì ní ìgbà méje ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́;+ lẹ́yìn èyí tí ẹran ara rẹ̀ padà wá gẹ́gẹ́ bí ẹran ara ọmọdékùnrin kékeré,+ ó sì mọ́.+
15 Nígbà náà ni ó padà lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run+ tòótọ́, òun pẹ̀lú gbogbo ibùdó rẹ̀, ó sì wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kíyè sí i, dájúdájú, mo wá mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé, bí kò ṣe ní Ísírẹ́lì.+ Wàyí o, jọ̀wọ́, gba ẹ̀bùn+ ìbùkún lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”
16 Bí ó ti wù kí o rí, ó sọ pé: “Bí Jèhófà, níwájú ẹni tí mo dúró sí, ti ń bẹ,+ èmi kì yóò gbà á.”+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó gbà á, ṣùgbọ́n ó ń kọ̀.
17 Níkẹyìn, Náámánì sọ pé: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí a fún ìránṣẹ́ rẹ ní ilẹ̀+ díẹ̀, ẹrù ìbaaka méjì; nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ẹbọ sí ọlọ́run mìíràn mọ́, bí kò ṣe sí Jèhófà.+
18 Nínú nǹkan yìí, kí Jèhófà dárí ji ìránṣẹ́ rẹ: Nígbà tí olúwa mi bá wá sí ilé Rímónì+ láti tẹrí ba níbẹ̀, tí ó sì fara ti+ ọwọ́ mi, tí mo sì ní láti tẹrí ba+ ní ilé Rímónì, nígbà tí mo bá tẹrí ba ní ilé Rímónì, kí Jèhófà, jọ̀wọ́, dárí ji ìránṣẹ́ rẹ nínú ọ̀ràn yìí.”+
19 Látàrí èyí, ó sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ibi jíjìnnaréré nínú ilẹ̀ náà.
20 Lẹ́yìn náà ni Géhásì,+ ẹmẹ̀wà Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́+ sọ pé: “Kíyè sí i, ọ̀gá mi ti dá Náámánì+ ará Síríà yìí sí, ní ṣíṣàìgba ohun tí ó mú wá ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ dájúdájú, èmi yóò sáré tẹ̀ lé e, èmi yóò sì gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.”+
21 Géhásì sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré tẹ̀ lé Náámánì. Nígbà tí Náámánì rí i tí ẹnì kan ń sáré tẹ̀ lé òun, lójú ẹsẹ̀, ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, láti pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni?”+
22 Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Ọ̀gá+ mi fúnra rẹ̀ ni ó rán mi,+ ó wí pé, ‘Wò ó! Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí ni ọ̀dọ́kùnrin méjì láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, láti ara àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ dé ọ̀dọ̀ mi. Jọ̀wọ́, fún wọn ní tálẹ́ńtì fàdákà kan àti ìpààrọ̀ ẹ̀wù méjì.’”+
23 Látàrí ìyẹn, Náámánì sọ pé: “Ó yá, kó tálẹ́ńtì méjì.” Ó sì ń rọ̀ ọ́+ ṣáá, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó di tálẹ́ńtì fàdákà méjì sínú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ ẹ̀wù méjì, ó sì kó wọn fún méjì lára ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí wọ́n máa rù ú nìṣó níwájú rẹ̀.
24 Nígbà tí ó dé Ófélì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbà á lọ́wọ́ wọn, ó sì kó wọn sínú ilé,+ ó sì rán àwọn ọkùnrin náà lọ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ.
25 Òun alára sì wọlé wá, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀.+ Èlíṣà sọ fún un wàyí, pé: “Ibo ni o ti ń bọ̀, Géhásì?” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibikíbi rárá.”+
26 Látàrí ìyẹn, ó sọ fún un pé: “Ọkàn-àyà mi kò ha bá ọ lọ ní gbàrà tí ọkùnrin náà yí padà láti sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò nìyí láti gba fàdákà tàbí láti gba àwọn ẹ̀wù tàbí àwọn oko ólífì tàbí àwọn ọgbà àjàrà tàbí àgùntàn tàbí màlúù tàbí àwọn ìránṣẹ́kùnrin tàbí àwọn ìránṣẹ́bìnrin?+
27 Nítorí náà, ẹ̀tẹ̀+ Náámánì yóò lẹ̀ mọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀ ní adẹ́tẹ̀ tí ó funfun bí ìrì dídì.+

