2 Àwọn Ọba 3:1-27

3  Ní ti Jèhórámù+ ọmọkùnrin Áhábù, ó di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún kejìdínlógún Jèhóṣáfátì ọba Júdà, ó sì ń bá a lọ láti jọba fún ọdún méjìlá.  Ó sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú Jèhófà,+ kìkì pé kò ṣe gẹ́gẹ́ bí baba+ rẹ̀ tàbí gẹ́gẹ́ bí ìyá rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mú ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ ti Báálì tí baba rẹ̀ ṣe+ kúrò.  Kìkì pé ó rọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Kò kúrò nínú wọn.  Ní ti Méṣà+ ọba Móábù, ó jẹ́ olùsin àgùntàn, ó sì san ọ̀kẹ́ márùn-ún ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀kẹ́ márùn-ún akọ àgùntàn tí a kò rẹ́ irun wọn, fún ọba Ísírẹ́lì.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Áhábù kú,+ ọba Móábù bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀+ sí ọba Ísírẹ́lì.  Nítorí náà, Jèhórámù Ọba jáde lọ ní ọjọ́ náà láti Samáríà, ó sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ.+  Ó lọ síwájú sí i, ó sì wá ránṣẹ́ sí Jèhóṣáfátì ọba Júdà, pé: “Ọba Móábù alára ti dìtẹ̀ sí mi. Ìwọ yóò ha bá mi lọ láti bá Móábù jagun?” Ó fèsì pé: “Èmi yóò lọ.+ Èmi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti jẹ́; àwọn ènìyàn mi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ;+ àwọn ẹṣin mi jẹ́ bákan náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹṣin rẹ.”  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ọ̀nà wo ní pàtó ni àwa yóò gbà gòkè lọ?” Nítorí náà, ó sọ pé: “Ọ̀nà aginjù Édómù+ ni.”  Ọba Ísírẹ́lì àti ọba Júdà àti ọba Édómù+ sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, wọ́n sì ń bá ọ̀nà wọn lọ yí ká fún ọjọ́ méje, kò sì sí omi fún ibùdó náà àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ tí ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ wọn. 10  Nígbà tí ó ṣe, ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Ó mà kúkú ṣe o, pé Jèhófà pe ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí láti fi wọ́n lé ọwọ́ Móábù!”+ 11  Látàrí ìyẹn, Jèhóṣáfátì sọ pé:+ “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà+ níhìn-ín ni? Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a tipasẹ̀ rẹ̀+ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.” Nítorí náà, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn, ó sì sọ pé: “Èlíṣà+ ọmọkùnrin Ṣáfátì, ẹni tí ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà,+ wà níhìn-ín.” 12  Nígbà náà ni Jèhóṣáfátì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì àti ọba Édómù sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ. 13  Èlíṣà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀?+ Lọ bá àwọn wòlíì+ baba rẹ àti àwọn wòlíì ìyá rẹ.” Ṣùgbọ́n ọba Ísírẹ́lì sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí Jèhófà ti pe àwọn ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí láti fi wọ́n lé ọwọ́ Móábù.”+ 14  Èlíṣà fèsì pé: “Bí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, níwájú ẹni tí mo dúró sí, ti ń bẹ,+ bí kì í bá ṣe ti ojú Jèhóṣáfátì ọba Júdà tí mo rò,+ èmi kì bá wò ọ́ tàbí kí n rí ọ.+ 15  Wàyí o, ẹ bá mi wá olùta+ ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín wá.” Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí olùta ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín ta á, ọwọ́ Jèhófà+ wá wà lára rẹ̀. 16  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kí sísọ àfonífojì olójú ọ̀gbàrá yìí di èyí tí ó kún fún kòtò+ wáyé; 17  nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ̀yin kì yóò rí ẹ̀fúùfù, ẹ̀yin kì yóò sì rí eji wọwọ; síbẹ̀, àfonífojì olójú ọ̀gbàrá yẹn yóò kún fún omi,+ dájúdájú, ẹ̀yin yóò sì mu láti inú rẹ̀,+ ẹ̀yin àti àwọn ohun ọ̀sìn yín àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ yín.”’ 18  Ní tòótọ́, èyí yóò sì jẹ́ ohun tí kò tó nǹkan ní ojú Jèhófà,+ dájúdájú, òun yóò sì fi Móábù lé yín lọ́wọ́.+ 19  Kí ẹ sì ṣá gbogbo ìlú ńlá olódi+ balẹ̀ àti gbogbo ìlú ńlá tí ó jẹ́ ààyò, gbogbo igi dáradára+ sì ni kí ẹ gé lulẹ̀,+ gbogbo ìsun omi sì ni kí ẹ dí pa, gbogbo abá ilẹ̀ tí ó dára sì ni kí ẹ fi òkúta sọ di págunpàgun.” 20  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀,+ nígbà ìgòkè lọ ọrẹ ẹbọ ọkà,+ pé, wò ó! omi ń ti ìhà Édómù bọ̀, ilẹ̀ náà sì wá kún fún omi. 21  Ní ti gbogbo àwọn ọmọ Móábù, wọ́n gbọ́ pé àwọn ọba náà ti gòkè wá láti bá àwọn jà. Nítorí náà, wọ́n pe àwọn ènìyàn jọ, bẹ̀rẹ̀ láti orí gbogbo àwọn tí ń de+ ìgbànú mọ́ra sókè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dúró ní ojú ààlà. 22  Nígbà tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, oòrùn ta sórí omi náà, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọmọ Móábù láti ìhà kejì rí omi náà pé ó pupa bí ẹ̀jẹ̀. 23  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ ni èyí! Láìsí àní-àní, àwọn ọba náà ni a ti fi idà pa, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá ara wọn balẹ̀ lẹ́nì kìíní-kejì. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, Móábù, díde sí ohun ìfiṣèjẹ!”+ 24  Nígbà tí wọ́n wá sínú ibùdó Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ọmọ Móábù balẹ̀, tí wọ́n fi fẹsẹ̀ fẹ kúrò níwájú wọn.+ Nítorí náà, wọ́n wọnú Moabu, wọ́n sì ń ṣá àwọn ọmọ Móábù balẹ̀ bí wọ́n ti ń bọ̀. 25  Àwọn ìlú ńlá ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wó palẹ̀,+ àti pé, ní ti gbogbo abá ilẹ̀ tí ó dára, olúkúlùkù wọn ju òkúta tirẹ̀, wọn sì fi kún un ní ti gidi; gbogbo ìsun omi ni wọ́n sì dí pa,+ gbogbo igi dáradára ni wọ́n sì gé lulẹ̀,+ títí wọ́n fi ṣẹ́ kìkì àwọn òkúta Kiri-hárésétì+ kù sílẹ̀ nínú rẹ̀; àwọn oníkànnàkànnà sì bẹ̀rẹ̀ sí yí i ká, wọ́n sì ń ṣá a balẹ̀. 26  Nígbà tí ọba Móábù rí i pé ìjà ogun náà ti le jù fún òun, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọkùnrin tí ń fa idà yọ pẹ̀lú ara rẹ̀, láti la ogun já lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Édómù;+ ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. 27  Níkẹyìn, ó mú ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí tí yóò jọba ní ipò rẹ̀, ó sì fi í rú+ ẹbọ sísun lórí ògiri. Ìkannú ńláǹlà sì wá wà sí Ísírẹ́lì, tí wọ́n fi kúrò lẹ́nu gbígbéjàkò ó, wọ́n sì padà sí ilẹ̀ wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé