1 Tímótì 2:1-15
2 Nítorí náà, ọ̀rọ̀ ìyànjú mi ni pé, ṣáájú ohun gbogbo, kí a máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà,+ ìbẹ̀bẹ̀fúnni, ọrẹ ẹbọ ọpẹ́, nípa gbogbo onírúurú ènìyàn,+
2 nípa àwọn ọba+ àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga;+ kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.+
3 Èyí dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà+ lójú Olùgbàlà wa, Ọlọ́run,+
4 ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn+ là,+ kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye+ nípa òtítọ́.+
5 Nítorí Ọlọ́run kan+ ni ó wà, àti alárinà kan+ láàárín Ọlọ́run+ àti àwọn ènìyàn,+ ọkùnrin kan, Kristi Jésù,+
6 ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn+—èyí ni ohun tí a óò jẹ́rìí sí ní àwọn àkókò rẹ̀ gan-an.
7 Fún ète ẹ̀rí yìí,+ a yàn mí ṣe oníwàásù àti àpọ́sítélì+—èmi ń sọ òtítọ́,+ èmi kò purọ́—olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè+ nínú ọ̀ràn ìgbàgbọ́+ àti òtítọ́.
8 Nítorí náà, mo ní ìfẹ́-ọkàn pé ní ibi gbogbo, kí àwọn ọkùnrin máa bá a lọ ní gbígbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè,+ láìsí ìrunú+ àti ọ̀rọ̀ fífà.+
9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà+ àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an,+
10 ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run,+ èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.+
11 Kí obìnrin kẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí ìtẹríba kíkún.+
12 Èmi kò gba obìnrin láyè láti kọ́ni,+ tàbí láti lo ọlá àṣẹ lórí ọkùnrin,+ bí kò ṣe láti wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.
13 Nítorí Ádámù ni a kọ́kọ́ ṣẹ̀dá, lẹ́yìn náà Éfà.+
14 Bákan náà, a kò tan Ádámù jẹ,+ ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn jẹ pátápátá,+ ó sì wá wà nínú ìrélànàkọjá.+
15 Bí ó ti wu kí ó rí, a ó pa á mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí,+ bí ó bá ṣe pé wọn ń bá a lọ nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìsọdimímọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.+

