1 Tímótì 1:1-20

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì+ Kristi Jésù lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run+ Olùgbàlà+ wa àti ti Kristi Jésù, ìrètí wa,+  sí Tímótì,+ ojúlówó ọmọ+ nínú ìgbàgbọ́: Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú, àlàáfíà wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Kristi Jésù Olúwa wa.+  Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fún ọ ní ìṣírí láti dúró ní Éfésù nígbà tí mo fẹ́ máa bá ọ̀nà mi lọ sí Makedóníà,+ bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe nísinsìnyí, kí ìwọ lè pàṣẹ+ fún àwọn kan láti má ṣe fi ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀ kọ́ni,+  tàbí fi àfiyèsí sí àwọn ìtàn èké+ àti sí àwọn ìtàn ìlà ìdílé, èyí tí kì í yọrí sí nǹkan kan,+ ṣùgbọ́n tí ń mú àwọn ìbéèrè fún ìwádìí jinlẹ̀ wá dípò pípín ohunkóhun fúnni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.  Ní ti gidi, ète àṣẹ pàtàkì yìí ni ìfẹ́+ láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́+ àti láti inú ẹ̀rí-ọkàn rere+ àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.+  Nípa yíyapa kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, àwọn kan ni a ti mú yà+ sínú ọ̀rọ̀ olóòrayè,+  wọn ń fẹ́ láti jẹ́ olùkọ́+ òfin,+ ṣùgbọ́n wọn kò róye yálà àwọn ohun tí wọn ń sọ tàbí àwọn ohun tí wọn ń tẹnu mọ kíkankíkan.  Wàyí o, a mọ̀ pé Òfin dára lọ́pọ̀lọpọ̀+ bí ó bá ṣe pé ẹnì kan mú un lò lọ́nà tí ó bófin mu+  nínú ìmọ̀ òtítọ́ yìí, pé a kò gbé òfin kalẹ̀ fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ aláìlófin+ àti ewèlè,+ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀, aláìní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,+ àti aláìbọ̀wọ̀ fún ohun mímọ́, àwọn olùṣìkàpa baba àti àwọn olùṣìkàpa ìyá, àwọn apànìyàn, 10  àwọn àgbèrè,+ àwọn ọkùnrin tí ń bá akọ dàpọ̀, àwọn ajínigbé, àwọn òpùrọ́, àwọn abúra èké,+ àti ohun èyíkéyìí mìíràn tí ó tako+ ẹ̀kọ́ afúnni-nílera+ 11  ní ìbámu pẹ̀lú ìhìnrere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀,+ tí a fi sí ìkáwọ́ mi.+ 12  Mo kún fún ìmoore sí Kristi Jésù Olúwa wa, ẹni tí ó fi agbára fún mi, nítorí tí ó kà mí sí olùṣòtítọ́+ nípa yíyan iṣẹ́ òjíṣẹ́+ kan lé mi lọ́wọ́, 13  bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni+ àti aláfojúdi.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fi àánú hàn sí mi,+ nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan,+ tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́. 14  Ṣùgbọ́n inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa pọ̀ lọ́nà tí ó peléke+ pa pọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.+ 15  Ṣíṣeégbíyèlé àti yíyẹ fún ìtẹ́wọ́gbà kíkún ni àsọjáde+ náà pé Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.+ Nínú àwọn wọ̀nyí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.+ 16  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí tí a fi fi àánú+ hàn sí mi ni pé nípasẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àkọ́kọ́, kí Kristi Jésù lè fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan lára àwọn tí yóò gbé ìgbàgbọ́+ wọn lé e fún ìyè àìnípẹ̀kun.+ 17  Wàyí o, Ọba ayérayé,+ tí kò lè díbàjẹ́,+ tí a kò lè rí,+ Ọlọ́run kan ṣoṣo+ náà, ni kí ọlá àti ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé.+ Àmín. 18  Àṣẹ pàtàkì+ yìí ni mo fi lé ọ lọ́wọ́, Tímótì, ọmọ, ní ìbámu pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀+ tí ó ṣamọ̀nà sọ́dọ̀ rẹ ní tààràtà, pé nípasẹ̀ èyí, kí ìwọ lè máa bá a lọ ní jíja ogun àtàtà;+ 19  ní dídi ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere+ mú, èyí tí àwọn kan ti sọ́gọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,+ tí wọn sì ti ní ìrírí rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn.+ 20  Híméníọ́sì+ àti Alẹkisáńdà+ wà nínú àwọn wọ̀nyí, mo sì ti fi wọ́n lé Sátánì lọ́wọ́,+ kí a lè kọ́ wọn nípasẹ̀ ìbáwí láti má ṣe sọ̀rọ̀ òdì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé