1 Sámúẹ́lì 27:1-12
27 Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Wàyí o, a ó ti ọwọ́ Sọ́ọ̀lù gbá mi lọ lọ́jọ́ kan. Kò sí nǹkan tí ó sàn fún mi ju pé kí n sá lọ+ sí ilẹ̀ àwọn Filísínì+ láìkùnà; Sọ́ọ̀lù yóò sì sọ̀rètí nù nípa mi láti tún máa wá mi mọ́ ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,+ dájúdájú, èmi yóò sì sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.”
2 Nítorí náà, Dáfídì dìde, òun àti ẹgbẹ̀ta ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ré kọjá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì+ ọmọkùnrin Máókì, ọba Gátì.
3 Dáfídì sì ń bá a lọ ní gbígbé pẹ̀lú Ákíṣì ní Gátì, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀,+ Dáfídì àti àwọn aya rẹ̀ méjèèjì , Áhínóámù+ ará Jésíréélì àti Ábígẹ́lì,+ aya Nábálì, ará Kámẹ́lì.
4 Nígbà tí ó ṣe, a ròyìn fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì ti fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Gátì, nítorí náà, kò sì tún wá a lọ mọ́ ní ìgbà mìíràn.+
5 Nígbà náà ni Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Wàyí o, bí mo bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí wọ́n fún mi ní ibì kan nínú ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá tí ó wà ní eréko, kí n lè máa gbé níbẹ̀; nítorí èé ṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò fi máa bá ọ gbé nínú ìlú ńlá ti ọba?”
6 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ákíṣì fún un ní Síkílágì+ ní ọjọ́ yẹn. Ìdí nìyẹn tí Síkílágì fi wá di ti àwọn ọba Júdà títí di òní yìí.
7 Iye ọjọ́ tí Dáfídì sì fi gbé ní eréko àwọn Filísínì wá jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin.+
8 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ kí wọ́n lè gbé sùnmọ̀mí lọ bá àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn Gísì àti àwọn ọmọ Ámálékì;+ nítorí wọ́n ń gbé ilẹ̀ tí ó nasẹ̀ láti Télámù+ títí dé Ṣúrì+ àti títí dé ilẹ̀ Íjíbítì.
9 Dáfídì sì kọlu ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kò pa ọkùnrin tàbí obìnrin mọ́ láàyè;+ ó sì kó agbo ẹran àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí àti àwọn ẹ̀wù, lẹ́yìn èyí tí ó padà, ó sì wá sọ́dọ̀ Ákíṣì.
10 Nígbà náà ni Ákíṣì sọ pé: “Ibo ni ẹ gbé sùnmọ̀mí lọ lónìí?” Dáfídì fèsì pé:+ “Sí gúúsù Júdà+ àti sí gúúsù àwọn ọmọ Jéráméélì+ àti sí gúúsù àwọn Kénì.”+
11 Ní ti ọkùnrin àti obìnrin, Dáfídì kò pa ẹnikẹ́ni mọ́ láàyè láti mú wọn wá sí Gátì, ó wí pé: “Kí wọ́n má bàa tú wa fó, pé, ‘Bí Dáfídì ti ṣe nìyí.’”+ (Èyí sì ni ọ̀nà tí ó ń gbà ṣe nǹkan rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí ó fi gbé ní eréko àwọn Filísínì.)
12 Nítorí náà, Ákíṣì gba Dáfídì gbọ́,+ ó sọ fún ara rẹ̀ pé: “Láìsí àní-àní, ó ti di òórùn burúkú láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì;+ yóò sì ní láti di ìránṣẹ́ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

