1 Sámúẹ́lì 23:1-29

23  Nígbà tí ó ṣe, wọ́n wá ròyìn fún Dáfídì pé: “Kíyè sí i, àwọn Filísínì ń bá Kéílà+ jagun, wọ́n sì ń kó àwọn ilẹ̀ ìpakà ní ìkógun.”+ 2  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ṣé kí n lọ, ṣé kí n sì ṣá àwọn Filísínì wọ̀nyí balẹ̀?” Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà wí fún Dáfídì pé: “Lọ, kí o sì ṣá àwọn Filísínì balẹ̀, kí o sì gba Kéílà là.” 3  Látàrí èyí, àwọn ọkùnrin Dáfídì wí fún un pé: “Wò ó! Àwa ń fòyà nígbà tí a wà níhìn-ín ní Júdà,+ mélòómélòó ni yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé a lọ sí Kéílà láti dojú kọ ojú ìlà ogun àwọn Filísínì!”+ 4  Nítorí náà, Dáfídì tún wádìí síbẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Jèhófà dá a lóhùn wàyí, ó sì wí pé: “Dìde, sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kéílà, nítorí èmi yóò fi àwọn Filísínì lé ọ lọ́wọ́.”+ 5  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí Kéílà, ó sì bá àwọn Filísínì jà, ó sì kó ohun ọ̀sìn wọn lọ, ṣùgbọ́n ó fi ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣá wọn balẹ̀; Dáfídì sì wá di olùgbàlà àwọn olùgbé Kéílà.+ 6  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Ábíátárì+ ọmọkùnrin Áhímélékì fẹsẹ̀ fẹ lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Kéílà, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ pẹ̀lú éfódì+ kan ní ọwọ́ rẹ̀. 7  Nígbà tí ó ṣe, a ròyìn fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dáfídì ti wá sí Kéílà.”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ọlọ́run ti tà á sí ọwọ́ mi,+ nítorí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ nípa wíwá sínú ìlú ńlá tí ó ní àwọn ilẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.” 8  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù fi ọlá àṣẹ pe gbogbo àwọn ènìyàn náà sí ogun, láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti sàga ti Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. 9  Dáfídì sì wá mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù ń fẹ̀tàn hùmọ ibi+ sí òun. Nítorí náà, ó wí fún Ábíátárì àlùfáà pé: “Mú éfódì sún mọ́ tòsí.”+ 10  Dáfídì sì ń bá a lọ láti wí pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ dájúdájú pé Sọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà láti run ìlú ńlá náà ní tìtorí mi.+ 11  Àwọn onílẹ̀ Kéílà yóò ha fi mi lé e lọ́wọ́? Sọ́ọ̀lù yóò ha sọ̀ kalẹ̀ wá gan-an gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́? Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́, sọ fún ìránṣẹ́ rẹ.” Jèhófà fèsì pé: “Yóò sọ̀ kalẹ̀ wá.”+ 12  Dáfídì sì ń bá a lọ láti wí pé: “Àwọn onílẹ̀ Kéílà yóò ha fi èmi àti àwọn ọkùnrin mi lé Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́?” Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà wí pé: “Wọn yóò ṣe ìfilénilọ́wọ́ náà.”+ 13  Ní kíá, Dáfídì dìde pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọkùnrin,+ wọ́n sì jáde kúrò ní Kéílà, wọ́n sì ń bá a lọ ní rírìn káàkiri ní ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rìn káàkiri. A sì ròyìn fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà, nítorí náà, ó jáwọ́ nínú jíjáde lọ. 14  Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní aginjù ní àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé, ó sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ní aginjù Sífù.+ Sọ́ọ̀lù sì ń bá a nìṣó ní wíwá a nígbà gbogbo,+ Ọlọ́run kò sì fi í lé e lọ́wọ́.+ 15  Dáfídì sì wà nínú ìbẹ̀rù nítorí pé Sọ́ọ̀lù ti jáde lọ láti wá ọkàn rẹ̀ nígbà tí Dáfídì wà ní aginjù Sífù ní Hóréṣi.+ 16  Jónátánì ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù dìde wàyí, ó sì lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, kí ó bàa lè fún ọwọ́ rẹ̀ lókun+ nípa ti Ọlọ́run.+ 17  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Má fòyà;+ nítorí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́, ìwọ ni yóò sì jẹ ọba+ lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù baba mi sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”+ 18  Nígbà náà ni àwọn méjèèjì jọ dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà; Dáfídì sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ní Hóréṣì, Jónátánì alára sì lọ sí ilé rẹ̀. 19  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Sífù+ gòkè lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n wí pé: “Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pa mọ́+ nítòsí wa ní àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé ní Hóréṣì,+ lórí òkè kékeré Hákílà,+ èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún Jéṣímónì?+ 20  Nísinsìnyí, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìfàsí ọkàn rẹ,+ ìwọ ọba, láti sọ̀ kalẹ̀, sọ̀ kalẹ̀ wá, ipa tiwa yóò sì jẹ́ láti fi í lé ọba lọ́wọ́.”+ 21  Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù wí pé: “Alábùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni yín,+ nítorí ẹ ní ìyọ́nú sí mi. 22  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lọ, ẹ ní ìforítì púpọ̀ sí i, kí ẹ sì wádìí dájú, kí ẹ sì rí ibi tí ó wà, níbi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà—ẹnì yòówù tí ó bá rí i níbẹ̀—nítorí a ti sọ fún mi pé alálùmọ̀kọ́rọ́yí+ gbáà ni òun fuńra rẹ̀ jẹ́. 23  Kí ẹ sì wò, kí ẹ sì wádìí dájú nípa gbogbo ibi ìfarapamọ́ tí ó ń fi ara rẹ̀ pa mọ́ sí; kí ẹ sì padà wá sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀rí, èmi yóò sì bá yín lọ; dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó bá wà ní ilẹ̀ náà, èmi pẹ̀lú yóò fẹ̀sọ̀ wá a kiri dájúdájú láàárín gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ Júdà.” 24  Nítorí náà, wọ́n dìde, wọ́n sì ṣáájú Sọ́ọ̀lù lọ sí Sífù,+ nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì wà ní aginjù Máónì+ ní Arábà+ sí apá gúúsù Jéṣímónì. 25  Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti wá a.+ Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì, ní kíá, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibi àpáta gàǹgà,+ ó sì ń bá a lọ ní gbígbé ní aginjù Máónì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù wá gbọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa+ Dáfídì lọ sínú aginjù Máónì. 26  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Sọ́ọ̀lù wá sí ẹ̀gbẹ́ ìhín òkè ńlá náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀hún òkè ńlá náà. Nítorí náà, Dáfídì ṣe wéré láti lọ+ nítorí Sọ́ọ̀lù; ní gbogbo àkókò náà, Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ká Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ mọ́ láti gbá wọn mú.+ 27  Ṣùgbọ́n ońṣẹ́ kan wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó wí pé: “Ṣe kánkán, kí o sì lọ, nítorí àwọn Filísínì ti gbé sùnmọ̀mí wá sí ilẹ̀ náà!” 28  Látàrí ìyẹn, Sọ́ọ̀lù yí padà ní lílépa Dáfídì,+ ó sì lọ pàdé àwọn Filísínì. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Àpáta Gàǹgà Àwọn Ìpínyà. 29  Nígbà náà ni Dáfídì bá ọ̀nà rẹ̀ gòkè lọ láti ibẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé ní Ẹ́ń-gédì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé