1 Kọ́ríńtì 16:1-24
16 Wàyí o, ní ti àkójọ+ tí ó wà fún àwọn ẹni mímọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún àwọn ìjọ Gálátíà,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin tìkára yín ṣe pẹ̀lú.
2 Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gédégbé ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí, kí ó lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé, àkójọ kì yóò wáyé nígbà náà.
3 Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá dé, àwọn ọkùnrin yòówù tí ẹ bá tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà,+ àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò rán láti gbé ẹ̀bùn inú rere yín lọ sí Jerúsálẹ́mù.
4 Àmọ́ ṣá o, bí ó bá yẹ fún mi láti lọ sí ibẹ̀ pẹ̀lú, wọn yóò pẹ̀lú mi lọ sí ibẹ̀.
5 Ṣùgbọ́n èmi yóò wá sọ́dọ̀ yín nígbà tí mo bá ti la Makedóníà kọjá, nítorí èmi yóò la Makedóníà+ kọjá;
6 bóyá èmi yóò sì dúró tàbí kí n tilẹ̀ lo ìgbà òtútù pẹ̀lú yín, kí ẹ lè sìn+ mí díẹ̀ lọ́nà ibi tí mo bá ń lọ.
7 Nítorí èmi kò fẹ́ rí yín báyìí-báyìí nígbà kíkọjá lọ mi, nítorí mo ní ìrètí láti wà lọ́dọ̀ yín+ fún ìgbà díẹ̀, bí Jèhófà+ bá yọ̀ǹda.+
8 Ṣùgbọ́n èmi yóò wà ní Éfésù+ títí di ìgbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì;
9 nítorí ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi,+ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ alátakò ní ń bẹ.
10 Bí ó ti wù kí ó rí, bí Tímótì+ bá dé, ẹ rí i pé kò sí ìbẹ̀rù kankan fún un láàárín yín, nítorí ó ń ṣe iṣẹ́ Jèhófà,+ àní gẹ́gẹ́ bí èmi.
11 Nítorí náà, kí ẹnì kankan má ṣe fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀.+ Ẹ sìn ín díẹ̀ dé ọ̀nà ní àlàáfíà, kí ó lè dé ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín, nítorí mo ń dúró dè é pẹ̀lú àwọn ará.
12 Wàyí o, ní ti Àpólò+ arákùnrin wa, mo pàrọwà fún un gidigidi láti wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú àwọn ará, síbẹ̀ kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wá nísinsìnyí; ṣùgbọ́n yóò wá nígbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.
13 Ẹ wà lójúfò,+ ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,+ ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin,+ ẹ di alágbára ńlá.+
14 Kí gbogbo àlámọ̀rí yín máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.+
15 Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará: ẹ mọ̀ pé agbo ilé Sítéfánásì ni àkọ́so+ Ákáyà àti pé wọ́n ṣètò ara wọn láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+
16 Kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa tẹrí ba fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ àti fún gbogbo ẹni tí ó bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí ó sì ń ṣe òpò.+
17 Ṣùgbọ́n mo yọ̀ lórí wíwàníhìn-ín Sítéfánásì+ àti Fọ́túnátù àti Ákáíkọ́sì, nítorí pé wọ́n ti dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín.
18 Nítorí wọ́n ti tu ẹ̀mí+ mi àti tiyín lára. Nítorí náà, ẹ máa mọyì irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.+
19 Àwọn ìjọ Éṣíà kí yín.+ Ákúílà àti Pírísíkà pa pọ̀ pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ní ilé+ wọn kí yín tinútinú nínú Olúwa.
20 Gbogbo àwọn ará kí yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+
21 Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, ní ọwọ́ ara mi.+
22 Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ni fún Olúwa, kí ó di ẹni ègún.+ Ìwọ Olúwa wa, máa bọ̀!+
23 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa wà pẹ̀lú yín.
24 Kí ìfẹ́ mi wà pẹ̀lú gbogbo yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.

