1 Kọ́ríńtì 1:1-31
1 Pọ́ọ̀lù, tí a pè láti jẹ́ àpọ́sítélì+ Jésù Kristi nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run,+ àti Sótínésì+ arákùnrin wa,
2 sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríńtì,+ sí ẹ̀yin tí a ti sọ di mímọ́+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́,+ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ń ké pe orúkọ+ Olúwa wa, Jésù Kristi níbi gbogbo, Olúwa wọn àti tiwa:+
3 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti àlàáfíà+ láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.+
4 Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo fún yín nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Ọlọ́run tí a fi fún yín nínú Kristi Jésù;+
5 pé nínú ohun gbogbo a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀+ nínú rẹ̀, nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára láti sọ̀rọ̀ àti nínú ìmọ̀ kíkún,+
6 àní gẹ́gẹ́ bí a ṣe fìdí ẹ̀rí nípa Kristi+ múlẹ̀ gbọn-in láàárín yín,
7 tí ó fi jẹ́ pé ẹ kò kùnà rárá láti dé ojú ìwọ̀n nínú ẹ̀bùn+ èyíkéyìí, bí ẹ ti ń fi ìháragàgà dúró de ìṣípayá+ Olúwa wa Jésù Kristi.
8 Òun yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in+ pẹ̀lú títí dé òpin, kí ẹ má bàa fi àyè sílẹ̀ fún ẹ̀sùn+ kankan ní ọjọ́+ Olúwa wa Jésù Kristi.+
9 Olùṣòtítọ́ ni Ọlọ́run,+ ẹni tí ó pè yín sínú àjọpín+ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.
10 Wàyí o, mo gbà yín níyànjú,+ ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ+ Olúwa wa Jésù Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan,+ àti pé kí ìpínyà+ má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú+ kan náà.
11 Nítorí àwọn tí wọ́n jẹ́ ará ilé Kílóè sọ ọ́ di mímọ̀+ fún mi nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé ìyapa wà láàárín yín.
12 Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí, pé olúkúlùkù yín ń wí pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” “Ṣùgbọ́n èmi ti Àpólò,”+ “Ṣùgbọ́n èmi ti Kéfà,” “Ṣùgbọ́n èmi ti Kristi.”
13 Kristi wà ní pípín yẹ́lẹyẹ̀lẹ.+ A kò kan Pọ́ọ̀lù mọ́gi fún yín, àbí a kàn án? Tàbí a ha batisí+ yín ní orúkọ Pọ́ọ̀lù bí?
14 Mo kún fún ọpẹ́ pé kò sí ọ̀kan nínú yín tí mo batisí àyàfi Kírípọ́sì+ àti Gáyọ́sì,+
15 kí ẹnì kankan má bàa lè sọ pé a batisí yín ní orúkọ mi.
16 Bẹ́ẹ̀ ni, mo batisí agbo ilé Sítéfánásì+ pẹ̀lú. Ní ti àwọn yòókù, èmi kò mọ̀ bóyá mo batisí ẹnikẹ́ni mìíràn.
17 Nítorí pé Kristi kò rán mi+ wá láti lọ máa batisí, bí kò ṣe láti lọ máa polongo ìhìn rere, kì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀rọ̀ sísọ,+ kí a má bàa sọ òpó igi oró Kristi di aláìwúlò.
18 Nítorí ọ̀rọ̀ nípa òpó igi oró jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀+ lójú àwọn tí ń ṣègbé,+ ṣùgbọ́n lójú àwa tí a ń gbà là,+ ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.+
19 Nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ṣe ni èmi yóò mú kí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ṣègbé,+ làákàyè àwọn amòye+ ni èmi yóò sì rọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”+
20 Ibo ni ọlọ́gbọ́n ènìyàn náà wà? Ibo ni akọ̀wé òfin náà wà?+ Ibo ni olùjiyàn ọ̀rọ̀+ ètò àwọn nǹkan yìí wà?+ Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀?+
21 Nítorí níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé nípasẹ̀ ọgbọ́n+ tirẹ̀ kò mọ Ọlọ́run,+ Ọlọ́run rí i pé ó dára nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀+ ohun tí a wàásù láti gba àwọn tí ń gbà gbọ́ là.
22 Nítorí àwọn Júù ń béèrè àmì,+ àwọn Gíríìkì sì ń wá ọgbọ́n;+
23 ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi tí a kàn mọ́gi,+ lójú àwọn Júù okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀+ ṣùgbọ́n lójú àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀rọ̀ òmùgọ̀;+
24 àmọ́ ṣá o, lójú àwọn tí í ṣe àwọn tí a pè, àti Júù àti Gíríìkì, Kristi agbára+ Ọlọ́run àti ọgbọ́n+ Ọlọ́run.
25 Nítorí ohun òmùgọ̀ ti Ọlọ́run gbọ́n ju àwọn ènìyàn lọ, ohun aláìlera ti Ọlọ́run sì lágbára ju àwọn ènìyàn lọ.+
26 Nítorí ẹ̀yin rí pípè tí òun pè yín, ẹ̀yin ará, pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ ọlọ́gbọ́n+ nípa ti ara ni a pè,+ kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára,+ kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn tí a bí ní ilé ọlá;
27 ṣùgbọ́n Ọlọ́run yan àwọn ohun òmùgọ̀ ayé,+ kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn; Ọlọ́run sì yan àwọn ohun aláìlera ayé, kí ó bàa lè kó ìtìjú bá àwọn ohun tí ó lágbára;+
28 Ọlọ́run sì yan àwọn ohun tí kò gbayì nínú ayé àti àwọn ohun tí a fojú tẹ́ńbẹ́lú, àwọn ohun tí kò sí,+ kí ó lè sọ àwọn ohun tí ó wà di asán,+
29 kí ẹlẹ́ran ara kankan má bàa ṣògo+ níwájú Ọlọ́run.
30 Ṣùgbọ́n òun ni ó mú kí ẹ wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹni tí ó ti di ọgbọ́n+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún wa, pẹ̀lúpẹ̀lù òdodo+ àti ìsọdimímọ́+ àti ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà;+
31 kí ó bàa lè rí gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.”+

