1 Kíróníkà 3:1-24

3  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Dáfídì+ tí a bí fún un ní Hébúrónì:+ Ámínónì+ àkọ́bí, láti ọ̀dọ̀ Áhínóámù+ ọmọbìnrin ará Jésíréélì,+ ìkejì, Dáníẹ́lì, láti ọ̀dọ̀ Ábígẹ́lì+ ọmọbìnrin ará Kámẹ́lì,+  ìkẹta, Ábúsálómù+ ọmọkùnrin Máákà+ ọmọbìnrin Tálímáì+ ọba Géṣúrì,+ ìkẹrin, Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì,+  ìkarùn-ún, Ṣẹfatáyà, láti ọ̀dọ̀ Ábítálì,+ ìkẹfà, Ítíréámù, láti ọ̀dọ̀ Ẹ́gílà+ aya rẹ̀.  Àwọn mẹ́fà ni a bí fún un ní Hébúrónì; ó sì ń bá a lọ láti jọba níbẹ̀ fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà, ó sì jọba ní Jerúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.+  Ìwọ̀nyí sì ni a bí fún un ní Jerúsálẹ́mù:+ Ṣíméà+ àti Ṣóbábù+ àti Nátánì+ àti Sólómọ́nì,+ mẹ́rin láti ọ̀dọ̀ Bátí-ṣébà+ ọmọbìnrin Ámíélì,+  àti Íbárì+ àti Élíṣámà+ àti Élífélétì,+  àti Nógà àti Néfégì àti Jáfíà,+  àti Élíṣámà+ àti Élíádà àti Élífélétì,+ mẹ́sàn-án,  gbogbo ọmọkùnrin Dáfídì yàtọ̀ sí àwọn ọmọkùnrin àwọn wáhàrì, àti Támárì+ arábìnrin wọn. 10  Ọmọkùnrin Sólómọ́nì sì ni Rèhóbóámù,+ Ábíjà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Ásà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jèhóṣáfátì+ ọmọkùnrin rẹ̀, 11  Jèhórámù ọmọkùnrin rẹ̀,+ Ahasáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin rẹ̀, 12  Amasááyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Asaráyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jótámù+ ọmọkùnrin rẹ̀, 13  Áhásì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Hesekáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Mánásè+ ọmọkùnrin rẹ̀, 14  Ámọ́nì+ ọmọkùnrin rẹ̀, Jòsáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀. 15  Àwọn ọmọkùnrin Jòsáyà sì ni Jóhánánì àkọ́bí, ìkejì, Jèhóákímù,+ ìkẹta, Sedekáyà,+ ìkẹrin, Ṣálúmù. 16  Àwọn ọmọkùnrin Jèhóákímù sì ni Jekonáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, Sedekáyà ọmọkùnrin rẹ̀. 17  Àwọn ọmọkùnrin Jekonáyà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n sì ni Ṣéálítíẹ́lì+ ọmọkùnrin rẹ̀ 18  àti Málíkírámù àti Pedáyà àti Ṣẹ́násà, Jekamáyà, Hóṣámà àti Nedabáyà. 19  Àwọn ọmọkùnrin Pedáyà sì ni Serubábélì+ àti Ṣíméì; àwọn ọmọkùnrin Serubábélì sì ni Méṣúlámù àti Hananáyà (Ṣẹ́lómítì sì ni arábìnrin wọn); 20  àti Háṣúbà àti Óhélì àti Berekáyà àti Hasadáyà, Juṣabi-hésédì, márùn-ún. 21  Àwọn ọmọkùnrin Hananáyà sì ni Pẹlatáyà+ àti Jeṣáyà, àwọn ọmọkùnrin Jeṣáyà, Refáyà, àwọn ọmọkùnrin Refáyà, Áánánì, àwọn ọmọkùnrin Áánánì, Ọbadáyà, àwọn ọmọkùnrin Ọbadáyà, Ṣẹkanáyà; 22  àti àwọn ọmọkùnrin Ṣẹkanáyà, Ṣemáyà, àti àwọn ọmọkùnrin Ṣemáyà, Hátúṣì àti Ígálì àti Baráyà àti Nearáyà àti Ṣáfátì, mẹ́fà. 23  Àwọn ọmọkùnrin Nearáyà sì ni Élíóénáì àti Hisikáyà àti Ásíríkámù, mẹ́ta. 24  Àwọn ọmọkùnrin Élíóénáì sì ni Hodafáyà àti Élíáṣíbù àti Pẹláyà àti Ákúbù àti Jóhánánì àti Deláyà àti Ánáánì, méje.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé