1 Kíróníkà 26:1-32
26 Ní ti ìpín ti àwọn aṣọ́bodè:+ Lára àwọn ọmọ Kórà,+ Meṣelemáyà+ ọmọkùnrin Kórè lára àwọn ọmọ Ásáfù.
2 Meṣelemáyà sì ní àwọn ọmọkùnrin: Sekaráyà àkọ́bí, Jédáélì ìkejì, Sebadáyà ìkẹta, Játíníélì ìkẹrin,
3 Élámù ìkarùn-ún, Jèhóhánánì ìkẹfà, Elieho-énáì ìkeje.
4 Obedi-édómù+ sì ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣemáyà àkọ́bí, Jèhósábádì ìkejì, Jóà ìkẹta àti Sákà ìkẹrin àti Nétánélì ìkarùn-ún,
5 Ámíélì ìkẹfà, Ísákárì ìkeje, Péúlétáì ìkẹjọ; nítorí pé Ọlọ́run bù kún un.+
6 Fún Ṣemáyà ọmọkùnrin rẹ̀, a sì bí àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olùṣàkóso ilé baba wọn, nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ọkùnrin dídáńgájíá, alágbára ńlá.
7 Àwọn ọmọkùnrin Ṣemáyà, Ótínì àti Réfáélì àti Óbédì, Élísábádì, tí àwọn arákùnrin wọn dáńgájíá, Élíhù àti Semakáyà.
8 Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ lára àwọn ọmọkùnrin Obedi-édómù, àwọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá tí wọ́n ní agbára fún iṣẹ́ ìsìn náà, méjìlélọ́gọ́ta jẹ́ ti Obedi-édómù.
9 Meṣelemáyà+ sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá, méjìdínlógún.
10 Hósà lára àwọn ọmọ Mérárì sì ní àwọn ọmọkùnrin. Ṣímúrì ni olórí, nítorí pé òun kọ́ ni àkọ́bí+ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ yàn án ṣe olórí;+
11 Hilikáyà ìkejì, Tebaláyà ìkẹta, Sekaráyà ìkẹrin. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin Hósà jẹ́ mẹ́tàlá.
12 Lára ìpín wọ̀nyí tí í ṣe ti àwọn aṣọ́bodè, àwọn onípò orí ní àwọn iṣẹ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn ti ní,+ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ní ilé Jèhófà.
13 Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ fún ẹni kékeré lọ́nà kan náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún ẹni ńlá nípa ìdí ilé baba wọn,+ fún onírúurú ẹnubodè.
14 Nígbà náà ni ìpín síhà ìlà-oòrùn bọ́ sọ́wọ́ Ṣelemáyà.+ Wọ́n ṣẹ́ kèké fún Sekaráyà+ ọmọkùnrin rẹ̀, agbani-nímọ̀ràn+ pẹ̀lú ọgbọ́n inú, ìpín tirẹ̀ sì jáde wá síhà àríwá.+
15 Ti Obedi-édómù wá síhà gúúsù, àwọn ọmọkùnrin+ rẹ̀ ni ó sì ni àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí.+
16 Ti Ṣúpímù àti Hósà+ wá síhà ìwọ̀-oòrùn nítòsí Ẹnubodè Ṣálékétì lẹ́bàá òpópó tí ó lọ sókè, tí àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́+ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́;+
17 síhà ìlà-oòrùn àwọn ọmọ Léfì mẹ́fà ni ó wà; síhà àríwá fún ọjọ́ kan,+ mẹ́rin; síhà gúúsù fún ọjọ́ kan, mẹ́rin; àti fún àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí,+ méjì-méjì;
18 fún ìloro olórùlé síhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin ní òpópó,+ méjì ní ìloro olórùlé.
19 Ìwọ̀nyí ni ìpín àwọn aṣọ́bodè láti inú àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Kórà+ àti lára àwọn ọmọ Mérárì.+
20 Ní ti àwọn ọmọ Léfì, Áhíjà ni ó ń bójú tó àwọn ìṣúra+ ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn ìṣúra àwọn ohun tí a sọ di mímọ́.+
21 Àwọn ọmọ Ládánì,+ àwọn ọmọkùnrin lára àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì tí wọ́n jẹ́ ti Ládánì; àwọn olórí ìdí ilé baba tí wọ́n jẹ́ ti Ládánì ọmọ Gẹ́ṣónì, Jẹ́híélì.+
22 Àwọn ọmọkùnrin Jẹ́híélì, Sétámù àti Jóẹ́lì+ arákùnrin rẹ̀, ni wọ́n ń bójú tó àwọn ìṣúra+ ilé Jèhófà.
23 Fún àwọn ọmọ Ámúrámù, fún àwọn ọmọ Ísárì, fún àwọn ọmọ Hébúrónì, fún àwọn ọmọ Úsíélì,+
24 àní Ṣẹ́búẹ́lì+ ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù ọmọkùnrin Mósè ni aṣáájú lórí àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí.
25 Ní ti àwọn arákùnrin rẹ̀, ti Élíésérì,+ Rehabáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ ń bẹ àti Jeṣáyà ọmọkùnrin rẹ̀ àti Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ àti Síkírì ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ṣẹ́lómótì ọmọkùnrin rẹ̀.
26 Ṣẹ́lómótì yìí àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ni wọ́n ń bójú tó gbogbo àwọn ìṣúra àwọn ohun tí a sọ di mímọ́,+ tí Dáfídì+ Ọba àti àwọn olórí ìdí ilé baba,+ àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ di mímọ́.
27 Láti inú ogun+ àti láti inú ohun ìfiṣèjẹ+ ni wọ́n ti sọ àwọn nǹkan di mímọ́ láti máa fi tọ́jú ilé Jèhófà.
28 Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo ohun tí Sámúẹ́lì aríran+ àti Sọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Kíṣì àti Ábínérì+ ọmọkùnrin Nérì àti Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà+ ti sọ di mímọ́. Ohun tí ẹnikẹ́ni sọ di mímọ́ wà lábẹ́ àkóso Ṣẹ́lómítì àti àwọn arákùnrin rẹ̀.
29 Lára àwọn ọmọ Ísárì,+ Kenanáyà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà fún iṣẹ́ àmójútó ti òde+ gẹ́gẹ́ bí àwọn onípò àṣẹ àti gẹ́gẹ́ bí àwọn onídàájọ́+ lórí Ísírẹ́lì.
30 Lára àwọn ọmọ Hébúrónì,+ Haṣabáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ni wọ́n wà lórí iṣẹ́ àbójútó Ísírẹ́lì ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì níhà ìwọ̀-oòrùn fún gbogbo iṣẹ́ Jèhófà àti fún iṣẹ́ ìsìn ọba.
31 Lára àwọn ọmọ Hébúrónì, Jéríjà+ ni olórí àwọn ọmọ Hébúrónì nípa ìran-ìran rẹ̀ nípa àwọn baba ńlá. Ọdún ogójì+ àkóso Dáfídì ni a wá wọn jáde, a sì wá rí àwọn akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin lára wọn ní Jásérì+ ní Gílíádì.+
32 Àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá,+ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá, àwọn olórí ìdí ilé baba.+ Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì Ọba yàn wọ́n lórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè,+ fún gbogbo ọ̀ràn Ọlọ́run tòótọ́ àti ọ̀ràn+ ọba.

