1 Kíróníkà 25:1-31
25 Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí+ àwọn àwùjọ aṣiṣẹ́ ìsìn+ ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn náà, Hémánì+ àti Jédútúnì+ àwọn tí ń fi háàpù,+ àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti aro+ sọ tẹ́lẹ̀. Láti inú wọn sì ni àwọn òṣìṣẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn wọn ti wá.
2 Lára àwọn ọmọ Ásáfù, Sákúrì àti Jósẹ́fù+ àti Netanáyà àti Áṣárélà,+ àwọn ọmọ Ásáfù lábẹ́ ìdarí Ásáfù+ ẹni tí ń sọ tẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìdarí ọba.
3 Lára Jédútúnì:+ àwọn ọmọkùnrin Jédútúnì, Gẹdaláyà+ àti Séérì+ àti Jeṣáyà,+ àti Ṣíméì, Haṣabáyà àti Matitáyà,+ mẹ́fà, lábẹ́ ìdarí baba wọn Jédútúnì, ẹni tí ń fi háàpù sọ tẹ́lẹ̀ fún dídúpẹ́ àti yíyin Jèhófà.+
4 Lára Hémánì:+ àwọn ọmọkùnrin Hémánì, Bùkáyà,+ Matanáyà,+ Úsíélì,+ Ṣẹ́búẹ́lì àti Jérímótì, Hananáyà,+ Hánáánì, Élíátà,+ Gídálítì+ àti Romamuti-ésérì,+ Joṣibẹ́káṣà,+ Málótì,+ Hótírì,+ Máhásíótì.
5 Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọmọkùnrin Hémánì, olùríran+ fún ọba nínú àwọn ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run tòótọ́ láti gbé ìwo rẹ̀ sókè; nípa báyìí, Ọlọ́run tòótọ́ tẹ̀ síwájú láti fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti ọmọbìnrin mẹ́ta.+
6 Gbogbo àwọn wọ̀nyí wà lábẹ́ ìdarí baba wọn nínú orin ní ilé Jèhófà, pẹ̀lú aro,+ àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti háàpù+ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́.
Abẹ́ ìdarí ọba ni Ásáfù àti Jédútúnì àti Hémánì+ wà.
7 Iye wọn pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn tí a kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà,+ gbogbo àwọn ògbógi,+ wá jẹ́ ọ̀rìn-lérúgba ó lé mẹ́jọ.
8 Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ ní ti àwọn ohun tí a óò bójú tó, ẹni kékeré jẹ́ lọ́nà kan náà gan-an bí ẹni ńlá,+ ògbógi+ pa pọ̀ pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́.
9 Kèké náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá: èkíní jẹ́ ti Ásáfù fún Jósẹ́fù,+ ìkejì fún Gẹdaláyà+ (òun àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ méjìlá);
10 ìkẹta fún Sákúrì,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
11 ìkẹrin fún Ísíráì,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
12 ìkarùn-ún fún Netanáyà,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
13 ìkẹfà fún Bùkáyà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
14 ìkeje fún Jéṣárélà,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
15 ìkẹjọ fún Jeṣáyà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
16 ìkẹsàn-án fún Matanáyà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
17 ìkẹwàá fún Ṣíméì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
18 ìkọkànlá fún Ásárẹ́lì,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
19 ìkejìlá fún Haṣabáyà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
20 fún ìkẹtàlá, Ṣúbáélì,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
21 fún ìkẹrìnlá, Matitáyà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
22 fún ìkẹẹ̀ẹ́dógún, fún Jérémótì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
23 fún ìkẹrìndínlógún, fún Hananáyà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
24 fún ìkẹtàdínlógún, fún Joṣibẹ́káṣà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
25 fún ìkejìdínlógún, fún Hánáánì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
26 fún ìkọkàndínlógún, fún Málótì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
27 fún ogún, fún Élíátà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
28 fún ìkọkànlélógún, fún Hótírì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
29 fún ìkejìlélógún, fún Gídálítì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
30 fún ìkẹtàlélógún, fún Máhásíótì,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá;
31 fún ìkẹrìnlélógún, fún Romamuti-ésérì,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, méjìlá.

