1 Kíróníkà 23:1-32

23  Dáfídì alára sì ti darúgbó,+ ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́, nítorí náà, ó fi Sólómọ́nì+ ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì. 2  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ọmọ aládé+ Ísírẹ́lì jọ àti àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì.+ 3  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a ka iye àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè;+ iye wọn, orí kọ̀ọ̀kan wọn, abarapá ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, wá jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún. 4  Lára àwọn wọ̀nyí, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì ń bẹ tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà; àti ẹgbàáta gẹ́gẹ́ bí onípò àṣẹ+ àti onídàájọ́;+ 5  àti ẹgbàajì aṣọ́bodè+ àti ẹgbàajì olùfi ìyìn+ fún Jèhófà lórí àwọn ohun èlò+ tí Dáfídì sọ pé “mo ṣe fún bíbu ìyìn.” 6  Nígbà náà ni Dáfídì pín wọn sí ìpín+ fún àwọn ọmọkùnrin Léfì,+ fún Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì. 7  Fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì, Ládánì àti Ṣíméì. 8  Àwọn ọmọkùnrin Ládánì ni Jéhíélì+ tí í ṣe onípò orí àti Sétámù àti Jóẹ́lì,+ mẹ́ta. 9  Àwọn ọmọkùnrin Ṣíméì ni Ṣẹ́lómótì àti Hásíélì àti Háránì, mẹ́ta. Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn baba fún Ládánì. 10  Àwọn ọmọkùnrin Ṣíméì sì ni Jáhátì, Sínà àti Jéúṣì àti Bẹráyà. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí ni ọmọkùnrin Ṣíméì. 11  Jáhátì sì wá jẹ́ olórí, Sísáhì sì ni ìkejì. Ní ti Jéúṣì àti Bẹráyà, wọn kò ní ọmọkùnrin púpọ̀; nítorí náà, wọ́n di ìdí ilé baba+ fún ẹgbẹ́ agbo onípò àṣẹ kan. 12  Àwọn ọmọkùnrin Kóhátì+ ni Ámúrámù, Ísárì,+ Hébúrónì+ àti Úsíélì,+ mẹ́rin. 13  Àwọn ọmọkùnrin Ámúrámù ni Áárónì+ àti Mósè.+ Ṣùgbọ́n a ya Áárónì sọ́tọ̀+ kí ó lè sọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ di mímọ́, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, láti máa rú èéfín ẹbọ+ níwájú Jèhófà, láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un+ àti láti máa fi orúkọ rẹ̀ súre+ fún àkókò tí ó lọ kánrin. 14  Ní ti Mósè ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ a ń bá a lọ láti ka àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì.+ 15  Àwọn ọmọkùnrin Mósè ni Gẹ́ṣómù+ àti Élíésérì.+ 16  Àwọn ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù ni Ṣẹ́búẹ́lì+ olórí. 17  Àwọn ọmọkùnrin Élíésérì sì wá jẹ́ Rehabáyà+ olórí; Élíésérì kò sì wá ní àwọn ọmọkùnrin mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọkùnrin Rehabáyà sì wá di púpọ̀ lọ́nà tí ó peléke. 18  Àwọn ọmọkùnrin Ísárì+ ni Ṣẹ́lómítì+ tí í ṣe onípò orí. 19  Àwọn ọmọkùnrin Hébúrónì ni Jeráyà olórí, Amaráyà ìkejì, Jahasíẹ́lì ìkẹta àti Jekaméámì+ ìkẹrin. 20  Àwọn ọmọkùnrin Úsíélì+ ni Míkà olórí àti Isiṣáyà ìkejì. 21  Àwọn ọmọkùnrin Mérárì+ ni Máhílì àti Múṣì.+ Àwọn ọmọkùnrin Máhílì ni Élíásárì+ àti Kíṣì. 22  Ṣùgbọ́n Élíásárì kú; kò sì wá ní àwọn ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin. Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin Kíṣì arákùnrin wọ́n fi wọ́n ṣe aya.+ 23  Àwọn ọmọkùnrin Múṣì ni Máhílì àti Édérì àti Jérémótì,+ mẹ́ta. 24  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọ Léfì ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn,+ àwọn olórí àwọn baba, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn tí a fàṣẹ yàn nínú wọn, ní iye orúkọ, orí kọ̀ọ̀kan wọn, àwọn olùṣe iṣẹ́ náà fún iṣẹ́ ìsìn+ ilé Jèhófà, láti ẹni ogún ọdún sókè.+ 25  Nítorí Dáfídì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìsinmi,+ òun yóò sì máa gbé ní Jerúsálẹ́mù fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 26  Pẹ̀lúpẹ̀lù, kì yóò di dandan fún àwọn ọmọ Léfì láti máa ru àgọ́ ìjọsìn tàbí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan èlò rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.”+ 27  Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn+ Dáfídì, ìwọ̀nyí ni iye àwọn ọmọ Léfì láti ẹni ogún ọdún sókè. 28  Nítorí iṣẹ́ wọ́n wà ní ìkáwọ́ àwọn ọmọ Áárónì+ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà lórí àwọn àgbàlá+ àti lórí àwọn yàrá ìjẹun+ àti lórí ìwẹ̀mọ́gaara gbogbo ohun mímọ́+ àti iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́, 29  àní fún búrẹ́dì onípele+ àti fún ìyẹ̀fun kíkúnná+ fún ọrẹ ẹbọ ọkà àti fún àwọn àdíngbẹ àkàrà pẹlẹbẹ+ ti búrẹ́dì aláìwú+ àti fún àwọn àkàrà tí a fi agbada+ dín àti fún àpòrọ́+ àti fún gbogbo àwọn ìdíwọ̀n bí nǹkan ṣe pọ̀ tó àti ìtóbi nǹkan;+ 30  àti fún dídúró+ ní òròòwúrọ̀+ láti máa dúpẹ́+ àti láti máa yin+ Jèhófà, àti bákan náà ní alẹ́; 31  àti fún gbogbo rírú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà ní àwọn sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀,+ ní iye ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àfilélẹ̀ tí a fi fún wọn, nígbà gbogbo níwájú Jèhófà. 32  Wọ́n sì bójú tó ṣíṣọ́ ẹ̀ṣọ́+ lórí àgọ́ ìpàdé àti ṣíṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ibi mímọ́+ àti ṣíṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí àwọn ọmọ Áárónì arákùnrin wọn fún iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé