1 Kíróníkà 19:1-19
19 Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé Náháṣì+ ọba àwọn ọmọ Ámónì wá kú, ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.+
2 Látàrí ìyẹn, Dáfídì sọ pé: “Èmi yóò ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ sí Hánúnì ọmọkùnrin Náháṣì, nítorí pé baba rẹ̀ ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí mi.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ láti tù ú nínú nítorí baba rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì wá sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ sí ọ̀dọ̀ Hánúnì, láti tù ú nínú.
3 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ aládé àwọn ọmọ Ámónì sọ fún Hánúnì pé: “Dáfídì ha ń bọlá fún baba rẹ ní ojú rẹ ní ti pé ó rán àwọn olùtùnú sí ọ? Kì í ha ṣe nítorí àtiṣe àyẹ̀wò fínnífínní àti láti fa ìbìṣubú àti láti ṣe amí+ ilẹ̀ náà ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi wọlé tọ̀ ọ́ wá?”+
4 Nítorí náà, Hánúnì mú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì,+ ó sì fá irùngbọ̀n wọn,+ ó sì gé ẹ̀wù wọn ní ààbọ̀ dé ekiti ìdí wọn,+ ó sì rán wọn lọ.+
5 Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn lọ sọ fún Dáfídì nípa àwọn ọkùnrin náà; kíákíá, ó ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí pé wọ́n ti di àwọn ọkùnrin tí a tẹ́ lógo gidigidi; ọba sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Ẹ máa gbé ní Jẹ́ríkò+ títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù lọ́pọ̀ yanturu. Lẹ́yìn náà ni kí ẹ padà.”
6 Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọmọ Ámónì rí i pé wọ́n ti di òórùn burúkú+ sí Dáfídì, Hánúnì+ àti àwọn ọmọ Ámónì sì tẹ̀ síwájú láti fi ẹgbẹ̀rún tálẹ́ńtì fàdákà+ ránṣẹ́ láti háyà àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti ẹlẹ́ṣin láti Mesopotámíà àti láti Aramu-máákà+ àti láti Sóbà+ fún ara wọn.
7 Báyìí ni wọ́n háyà ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàáfà àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti ọba Máákà àti àwọn ènìyàn rẹ̀+ fún ara wọn. Nígbà náà ni wọ́n wọlé wá, wọ́n sì dó síwájú Médébà;+ ní ti àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n kóra jọpọ̀ láti àwọn ìlú ńlá wọn, wọ́n sì wọlé wá wàyí fún ogun.
8 Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán Jóábù+ àti gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá.+
9 Àwọn ọmọ Ámónì sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ, wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun ní ẹnu ọ̀nà ìlú ńlá náà, àwọn ọba+ tí ó wá sì dá wà nínú pápá gbalasa.
10 Nígbà tí Jóábù rí i pé ìgbóguntini nínú ìjà ogun wá dojú kọ òun láti iwájú àti láti ẹ̀yìn, ní kíá, ó yan àwọn kan lára gbogbo àwọn ààyò ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn ará Síríà.+
11 Ìyókù àwọn ènìyàn náà sì ni ó fi sí ọwọ́ Ábíṣáì+ arákùnrin rẹ̀, kí wọ́n lè tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn ọmọ Ámónì.+
12 Ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Bí àwọn ará Síríà+ bá le jù fún mi, kí ìwọ pẹ̀lú ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà fún mi;+ ṣùgbọ́n bí àwọn ọmọ Ámónì fúnra wọn bá le jù fún ọ, kí èmi pẹ̀lú gbà ọ́ là.+
13 Jẹ́ alágbára,+ kí a lè fi ara wa hàn ní onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa àti nítorí àwọn ìlú ńlá Ọlọ́run wa;+ ní ti Jèhófà, ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀ ni yóò ṣe.”+
14 Nígbà náà ni Jóábù àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ síwájú àwọn ará Síríà síbi ìjà ogun náà,+ wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ+ kúrò níwájú rẹ̀.
15 Ní ti àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n rí i pé àwọn ará Síríà ti sá lọ, àwọn alára pẹ̀lú sì fẹsẹ̀ fẹ+ kúrò níwájú Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀, nígbà náà ni wọ́n wọ ìlú ńlá náà.+ Lẹ́yìn náà, Jóábù wá sí Jerúsálẹ́mù.
16 Nígbà tí àwọn ará Síríà rí i pé a ti ṣẹ́gun+ wọn níwájú Ísírẹ́lì, wọ́n tẹ̀ síwájú láti rán àwọn ońṣẹ́, wọ́n sì mú àwọn ará Síríà tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Odò+ jáde wá, pẹ̀lú Ṣófákì olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hadadésà níwájú wọn.
17 Nígbà tí a ròyìn fún Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó gbogbo Ísírẹ́lì jọpọ̀, ó sì sọdá Jọ́dánì, ó sì dé bá wọn, ó sì tẹ́ ìtẹ́gun láti dojú kọ wọ́n.+ Nígbà tí Dáfídì tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn ará Síríà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá a jà.
18 Ṣùgbọ́n àwọn ará Síríà fẹsẹ̀ fẹ+ nítorí Ísírẹ́lì; Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ méjì àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn lára àwọn ará Síríà, Ṣófákì alára tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ó sì fi ikú pa.+
19 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà rí i pé a ti ṣẹ́gun wọn níwájú Ísírẹ́lì,+ kíákíá ni wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn ín;+ Síríà kò sì fẹ́ gbìyànjú láti tún gba àwọn ọmọ Ámónì là.+

