1 Kíróníkà 13:1-14
13 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí fikùnlukùn pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti pẹ̀lú olúkúlùkù aṣáájú;+
2 Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ó bá dára lójú yín tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹ jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wa tí ó ṣẹ́ kù ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì+ àti pẹ̀lú wọn, sí àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì+ ní àwọn ìlú ńlá+ wọn pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ìjẹko, kí wọ́n lè kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ wa.
3 Kí a sì gbé àpótí+ Ọlọ́run wa wá sí ọ̀dọ̀ wa.” Nítorí wọn kò bójú tó o ní àwọn ọjọ́ Sọ́ọ̀lù.+
4 Nítorí náà, gbogbo ìjọ sọ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ohun náà jọ pé ó tọ̀nà ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn náà.+
5 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọpọ̀+ láti odò Íjíbítì+ títí dé àtiwọ Hámátì,+ láti gbé àpótí+ Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù.+
6 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ sí Báálà,+ sí Kiriati-jéárímù, tí í ṣe ti Júdà, láti gbé àpótí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, gòkè wá láti ibẹ̀, ẹni tí ń jókòó lórí àwọn kérúbù,+ ibi tí a ń fi orúkọ rẹ̀ pè.
7 Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun+ láti ilé Ábínádábù, Úsà àti Áhíò+ sì ń ṣamọ̀nà kẹ̀kẹ́ náà.
8 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì sì ń ṣe ayẹyẹ+ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára àti pẹ̀lú orin+ àti pẹ̀lú háàpù+ àti pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti pẹ̀lú ìlù tanboríìnì+ àti pẹ̀lú aro àti pẹ̀lú kàkàkí.+
9 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì ń bọ̀ títí dé ilẹ̀ ìpakà Kídónì,+ Úsà sì na ọwọ́ rẹ̀ wàyí láti gbá Àpótí+ mú, nítorí tí àwọn akọ màlúù náà fẹ́rẹ̀ẹ́ fa ìdojúdé.
10 Látàrí ìyẹn, ìbínú Jèhófà ru sí Úsà, tí ó fi ṣá a balẹ̀ nítorí pé ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sára Àpótí,+ ó sì kú níbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.+
11 Dáfídì sì bínú+ nítorí pé Jèhófà ti ṣe ìyalù nípa gbígbéjàko Úsà; a sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà títí di òní yìí.
12 Dáfídì sì fòyà Ọlọ́run tòótọ́ ní ọjọ́ yẹn,+ ó wí pé: “Èmi ó ha ṣe gbé àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá sọ́dọ̀ mi?”+
13 Dáfídì kò sì gbé Àpótí wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Ìlú Ńlá Dáfídì, ṣùgbọ́n ó gbé e yà sí ilé Obedi-édómù+ ará Gátì.+
14 Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ní agbo ilé Obedi-édómù, ní ilé rẹ̀+ fún oṣù mẹ́ta; Jèhófà sì ń bù kún+ agbo ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀.

