1 Kíróníkà 11:1-47
11 Nígbà tí ó ṣe, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì,+ wọ́n wí pé: “Wò ó! Egungun rẹ àti ẹran ara rẹ ni àwa jẹ́.+
2 Àti ní àná àti tẹ́lẹ̀ rí, àní nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba, ìwọ ni ẹni tí ń mú Ísírẹ́lì jáde, tí ó sì ń mú un wọlé;+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, ìwọ sì ni yóò di aṣáájú+ lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.’”
3 Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú ní Hébúrónì níwájú Jèhófà; lẹ́yìn èyí tí wọ́n fòróró yan+ Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀+ Jèhófà nípasẹ̀ Sámúẹ́lì.+
4 Lẹ́yìn náà, Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Jerúsálẹ́mù,+ èyíinì ni, Jébúsì,+ níbi tí àwọn ará Jébúsì+ ti jẹ́ olùgbé ilẹ̀ náà.
5 Àwọn olùgbé Jébúsì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ kì yóò wọ ìhín.”+ Síbẹ̀síbẹ̀, Dáfídì tẹ̀ síwájú láti gba ibi odi agbára Síónì,+ èyíinì ni, Ìlú Ńlá Dáfídì.+
6 Nítorí náà, Dáfídì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kọlu+ àwọn ará Jébúsì, òun ni yóò di olórí àti ọmọ aládé.” Jóábù+ ọmọkùnrin Seruáyà sì ni ó kọ́kọ́ gòkè lọ, ó sì wá di olórí.
7 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ibi tí ó ṣòro láti dé.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pè é ní Ìlú Ńlá Dáfídì.+
8 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ìlú ńlá náà yíká-yíká, láti Òkìtì àní dé àwọn apá tí wọ́n wà yí ká, ṣùgbọ́n Jóábù fúnra rẹ̀ ni ó mú ìyókù ìlú ńlá náà kún fún ìgbòkègbodò.+
9 Dáfídì sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá,+ nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.+
10 Wàyí o, ìwọ̀nyí ni olórí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá+ tí ó jẹ́ ti Dáfídì, tí wọ́n dúró tì í gbágbá nínú ipò ọba rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì, láti fi í jẹ ọba ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà+ nípa Ísírẹ́lì.
11 Èyí sì ni àkójọ orúkọ àwọn ọkùnrin alágbára ńlá tí ó jẹ́ ti Dáfídì: Jáṣóbéámù+ ọmọkùnrin ẹnì kan tí í ṣe ọmọ Hákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà. Ó ń ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ fìrìfìrì lórí ọ̀ọ́dúnrún tí a pa lẹ́ẹ̀kan náà.+
12 Àti lẹ́yìn rẹ̀ ni Élíásárì+ ọmọkùnrin Dódò ọmọ Áhóhì.+ Ó wà lára àwọn alágbára ńlá mẹ́ta náà.+
13 Òun ni ó wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pasi-dámímù,+ níbi tí àwọn Filísínì ti kó ara wọn jọpọ̀ sí fún ogun. Wàyí o, abá pápá kan wà tí ó kún fún ọkà bálì, àwọn ènìyàn náà, ní tiwọn, sì ti sá lọ nítorí àwọn Filísínì.+
14 Ṣùgbọ́n ó mú ìdúró rẹ̀ ní àárín abá náà, ó sì dá a nídè, ó sì ń ṣá àwọn Filísínì balẹ̀ nìṣó, tí ó fi jẹ́ pé Jèhófà fi ìgbàlà ńlá+ gbà wọ́n là.+
15 Mẹ́ta lára àwọn ọgbọ̀n+ olórí sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi àpáta, sọ́dọ̀ Dáfídì ní hòrò Ádúlámù,+ nígbà tí ibùdó àwọn Filísínì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+
16 Nígbà yẹn, Dáfídì sì wà ní ibi tí ó nira láti dé;+ ẹgbẹ́ ogun Filísínì+ sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà yẹn.
17 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Dáfídì fi ìfàsí-ọkàn rẹ̀ hàn, ó sì wí pé: “Ì bá ṣe pé mo lè rí omi mu+ láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ èyí tí ó wà ní ẹnubodè!”
18 Látàrí ìyẹn, àwọn mẹ́ta náà fi ipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n sì fa omi láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, èyí tí ó wà ní ẹnubodè, wọ́n sì ń gbé e bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dáfídì.+ Dáfídì kò sì gbà láti mu ún, ṣùgbọ́n ó dà á jáde fún Jèhófà.+
19 Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ti Ọlọ́run mi, láti ṣe èyí! Ṣé ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni kí n mu ní fífi ọkàn wọn wewu? Nítorí ní fífi ọkàn wọn wewu ni wọ́n fi gbé e wá.” Kò sì gbà láti mu ún.+ Ìwọ̀nyí ni ohun tí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà ṣe.
20 Ní ti Ábíṣáì+ arákùnrin Jóábù,+ òun fúnra rẹ̀ di olórí àwọn mẹ́ta; ó sì ń ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ fìrìfìrì lórí ọ̀ọ́dúnrún tí a pa, ó sì ní ìfùsì bí àwọn mẹ́ta náà.
21 Lára àwọn mẹ́ta náà, ó jẹ́ ẹni sàràkí ju àwọn méjì yòókù, ó sì wá jẹ́ olórí wọn; síbẹ̀síbẹ̀, kò tó+ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.
22 Ní ti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà,+ ọmọ akíkanjú kan, ẹni tí ó ṣe ohun púpọ̀ ní Kábúséélì,+ òun fúnra rẹ̀ ni ó ṣá àwọn ọmọkùnrin méjì ti Áríélì ará Móábù balẹ̀; òun fúnra rẹ̀ sì ni ó sọ̀ kalẹ̀ tí ó sì ṣá kìnnìún+ kan balẹ̀ nínú kòtò omi kan ní ọjọ́ tí ìrì dídì ń sẹ̀.
23 Òun sì ni ó ṣá ọkùnrin ará Íjíbítì náà balẹ̀, ọkùnrin kan tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+ Ọ̀kọ̀+ kan tí ó dà bí ìtì igi àwọn olófì sì wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà; síbẹ̀ ó sọ̀ kalẹ̀ lọ bá a pẹ̀lú ọ̀pá, ó sì já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+
24 Nǹkan wọ̀nyí ni Bẹnáyà ọmọkùnrin Jèhóádà ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà.
25 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ẹni sàràkí ju ọgbọ̀n náà, síbẹ̀ kò wọ+ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, Dáfídì fi í sórí ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.+
26 Ní ti àwọn ọkùnrin alágbára ńlá ti ẹgbẹ́ ológun, àwọn ni Ásáhélì+ arákùnrin Jóábù, Élíhánánì+ ọmọkùnrin Dódò ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,
27 Ṣámótì+ ará Hárórù, Hélésì tí í ṣe Pélónì,+
28 Írà+ ọmọkùnrin Íkéṣì ará Tékóà, Abi-ésérì ọmọ Ánátótì,+
29 Síbékáì+ ọmọ Húṣà, Íláì ọmọ Áhóhì,+
30 Máháráì+ ará Nétófà,+ Hélédì+ ọmọkùnrin Báánáhì ará Nétófà,
31 Ítáì ọmọkùnrin Ríbáì+ ti Gíbíà+ ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ Bẹnáyà ará Pírátónì,+
32 Húráì láti àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Gááṣì,+ Ábíélì tí í ṣe Ábátì,
33 Ásímáfẹ́tì ará Báhúrímù,+ Élíábà tí í ṣe Ṣáálíbónì,
34 àwọn ọmọ Háṣémù tí í ṣe Gísónì, Jónátánì+ ọmọkùnrin Ṣágéè tí í ṣe Hárárì,
35 Áhíámù ọmọkùnrin Sákárì+ tí í ṣe Hárárì, Élífálì+ ọmọkùnrin Úrì,
36 Héfà ọmọ Mékérà, Áhíjà tí í ṣe Pélónì,
37 Hésírò ará Kámẹ́lì,+ Nááráì ọmọkùnrin Ésíbáì,
38 Jóẹ́lì arákùnrin Nátánì,+ Míbúhárì ọmọkùnrin Hágírì,
39 Sélékì ọmọ Ámónì, Náháráì ará Bérótì, arùhámọ́ra Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà,
40 Írà tí í ṣe Ítírì, Gárébù+ tí í ṣe Ítírì,
41 Ùráyà+ ọmọ Hétì,+ Sábádì ọmọkùnrin Áláì,
42 Ádínà ọmọkùnrin Ṣísà ọmọ Rúbẹ́nì, ọ̀kan lára olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, ẹni tí ọgbọ̀n ènìyàn wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀;
43 Hánánì ọmọkùnrin Máákà, àti Jóṣáfátì tí í ṣe Mítínì,
44 Úsíà ará Áṣítárótì, Ṣámà àti Jéélì, àwọn ọmọkùnrin Hótámù ará Áróérì,
45 Jédáélì ọmọkùnrin Ṣímúrì, àti Jóhà arákùnrin rẹ̀ tí í ṣe Tísì,
46 Élíélì tí í ṣe Máháfì, àti Jéríbáì àti Joṣafáyà àwọn ọmọkùnrin Élínáámù, àti Ítímà ọmọ Móábù.
47 Élíélì àti Óbédì àti Jáásíélì ará Sóbà.

