1 Jòhánù 5:1-21
5 Olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi ni a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ó ṣokùnfa bíbíni nífẹ̀ẹ́ ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ ẹni yẹn.+
2 Nípa èyí ni a jèrè ìmọ̀ pé àwa ń nífẹ̀ẹ́+ àwọn ọmọ Ọlọ́run,+ nígbà tí a bá ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí a sì ń ṣe ohun tí àwọn àṣẹ rẹ̀ wí.+
3 Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́+ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́;+ síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira,+
4 nítorí ohun gbogbo tí a ti bí+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń ṣẹ́gun ayé.+ Èyí sì ni ìṣẹ́gun+ tí ó ti ṣẹ́gun+ ayé, ìgbàgbọ́+ wa.
5 Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun+ ayé+ bí kò ṣe ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́+ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run?+
6 Èyí ni ẹni tí ó wá nípasẹ̀ omi àti ẹ̀jẹ̀, Jésù Kristi; kì í ṣe pẹ̀lú omi+ nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú omi àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.+ Ẹ̀mí+ sì ni èyíinì tí ń jẹ́rìí, nítorí pé ẹ̀mí ni òtítọ́.
7 Nítorí àwọn mẹ́ta ní ń jẹ́rìí,
8 ẹ̀mí+ àti omi+ àti ẹ̀jẹ̀,+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì fohùn ṣọ̀kan.+
9 Bí àwa bá gba ẹ̀rí tí àwọn ènìyàn ń jẹ́,+ ẹ̀rí tí Ọlọ́run ń jẹ́ ni ó tóbi jù, nítorí èyí ni ẹ̀rí tí Ọlọ́run ń jẹ́, òtítọ́ náà pé ó ti jẹ́rìí+ nípa Ọmọ rẹ̀.
10 Ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọmọ Ọlọ́run ní ẹ̀rí tí a jẹ́+ nínú ọ̀ràn tirẹ̀. Ẹni tí kò bá ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ti sọ ọ́ di òpùrọ́,+ nítorí kò ní ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀rí tí a jẹ́,+ èyí tí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí ti jẹ́+ nípa Ọmọ rẹ̀.
11 Èyí sì ni ẹ̀rí tí a jẹ́, pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ìyè yìí sì wà nínú Ọmọ rẹ̀.+
12 Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè yìí; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọ́run kò ní ìyè yìí.+
13 Mo kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ yín nínú orúkọ Ọmọ Ọlọ́run.+
14 Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i,+ pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.+
15 Síwájú sí i, bí a bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè,+ a mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.+
16 Bí ẹnikẹ́ni bá tajú kán rí arákùnrin rẹ̀ tí ń ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í fa ikú wá báni,+ yóò béèrè, yóò sì fi ìyè fún un,+ bẹ́ẹ̀ ni, fún àwọn tí kì í dẹ́ṣẹ̀ tí yóò fa ikú wá báni.+ Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí ń fa ikú wá báni ní tòótọ́. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ni èmi kò sọ fún un láti ṣe ìbéèrè.+
17 Gbogbo àìṣòdodo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;+ síbẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí kì í fa ikú wá báni.
18 A mọ̀ pé olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, ṣùgbọ́n Ẹni+ tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń ṣọ́ ọ, ẹni burúkú náà kì í sì í rí i dì mú pinpin.+
19 A mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.+
20 Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti wá,+ ó sì ti fún wa ní agbára ìmòye+ kí a lè jèrè ìmọ̀ nípa ẹni tòótọ́ náà.+ A sì wà ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú ẹni tòótọ́ náà,+ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi. Èyí ni Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun.+
21 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.+

