1 Jòhánù 1:1-10

1  Èyíinì tí ó wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,+ tí a ti gbọ́,+ tí a ti fi ojú wa rí,+ tí a ti wò pẹ̀lú ìfiyèsí,+ tí a sì ti fọwọ́ bà,+ ní ti ọ̀rọ̀ ìyè,+  (bẹ́ẹ̀ ni, ìyè náà ni a fi hàn kedere,+ a sì ti rí, a sì ń jẹ́rìí,+ a sì ń ròyìn fún yín nípa ìyè àìnípẹ̀kun+ tí ó ti wà pẹ̀lú Baba, tí a sì fi hàn kedere fún wa,)  èyíinì tí a ti rí, tí a sì ti gbọ́ ni a ń ròyìn fún yín pẹ̀lú,+ kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè máa ní àjọpín pẹ̀lú wa.+ Síwájú sí i, àjọpín+ tiwa yìí jẹ́ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi.+  Àti nítorí náà, a ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí kí ìdùnnú wa lè wà ní ìwọ̀n kíkún.+  Èyí sì ni ìhìn iṣẹ́ tí a ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, tí a sì ń kéde fún yín,+ pé Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+ kò sì sí òkùnkùn kankan rárá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+  Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: “Àwa ń ní àjọpín pẹ̀lú rẹ̀,” síbẹ̀ tí a ń bá a lọ ní rírìn nínú òkùnkùn,+ irọ́ ni a ń pa, a kò sì fi òtítọ́ ṣe ìwà hù.+  Àmọ́ ṣá o, bí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ti wà nínú ìmọ́lẹ̀,+ àwa ní àjọpín pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,+ ẹ̀jẹ̀+ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́+ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.+  Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: “Àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan,”+ a ń ṣi ara wa lọ́nà ni,+ òtítọ́ kò sì sí nínú wa.  Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo.+ 10  Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: “Àwa kò dẹ́ṣẹ̀,” a ń sọ ọ́ di òpùrọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé