1 Àwọn Ọba 20:1-43
20 Ní ti Bẹni-hádádì+ ọba Síríà, ó kó gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ jọpọ̀, bákan náà, ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì wà pẹ̀lú rẹ̀+ àti àwọn ẹṣin+ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ, ó sì sàga+ ti Samáríà,+ ó sì bá a jà.
2 Nígbà náà ni ó rán àwọn ońṣẹ́+ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ní ìlú ńlá náà. Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Bẹni-hádádì wí,
3 ‘Fàdákà rẹ àti wúrà rẹ jẹ́ tèmi, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, tí ó dára jù lọ ní ìrísí, jẹ́ tèmi.’”+
4 Ọba Ísírẹ́lì fèsì, ó sì wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, olúwa mi ọba, tìrẹ ni èmi pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó jẹ́ tèmi.”+
5 Nígbà tí ó yá, àwọn ońṣẹ́ náà padà wá, wọ́n sì wí pé: “Èyí ni ohun tí Bẹni-hádádì wí, ‘Mo ránṣẹ́ sí ọ pé: “Fàdákà rẹ àti wúrà rẹ àti àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni kí o fi fún mi.
6 Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ, wọn yóò sì fẹ̀sọ̀ wá ilé rẹ àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ohun tí ó fani mọ́ra+ lójú rẹ ni wọn yóò kó sí ọwọ́ wọn, wọn yóò sì kó o lọ.”’”
7 Látàrí ìyẹn, ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà,+ ó sì wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣàkíyèsí, kí ẹ sì rí i pé ìyọnu àjálù ni ẹni yìí ń wá;+ nítorí tí ó ránṣẹ́ sí mi fún àwọn aya mi àti àwọn ọmọ mi àti fàdákà mi àti wúrà mi, èmi kò sì fawọ́ wọn sẹ́yìn fún un.”
8 Nígbà náà ni gbogbo àgbà ọkùnrin àti gbogbo ènìyàn náà sọ fún un pé: “Má ṣègbọràn, má sì gbà.”
9 Nítorí náà, ó sọ fún àwọn ońṣẹ́ Bẹni-hádádì pé: “Sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Gbogbo iṣẹ́ tí o kọ́kọ́ rán sí ìránṣẹ́ rẹ ni èmi yóò ṣe; ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò lè ṣe.’” Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ońṣẹ́ náà lọ, wọ́n sì mú ọ̀rọ̀ padà wá fún un.
10 Wàyí o, Bẹni-hádádì ránṣẹ́ sí i, ó sì wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́run+ ṣe sí mi, bẹ́ẹ̀ sì ni kí wọ́n fi kún un,+ bí ekuru Samáríà yóò bá tó ẹ̀kúnwọ́ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀ lé mi!”+
11 Ẹ̀wẹ̀, ọba Ísírẹ́lì dáhùn, ó sì wí pé: “Ẹ sọ fún un pé, ‘Kí ẹni tí ń di àmùrè+ má ṣògo nípa ara rẹ̀ bí ẹni tí ń tú+ u kúrò.’”
12 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, bí òun fúnra rẹ̀ àti àwọn ọba ti ń mutí+ nínú àwọn àtíbàbà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbára dì!” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbára dì láti gbéjà ko ìlú ńlá náà.
13 Sì wò ó! wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá,+ ó sì wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí,+ ‘Ṣé o rí gbogbo ogunlọ́gọ̀ ńláǹlà yìí? Kíyè sí i, èmi yóò fi í lé ọ lọ́wọ́ lónìí, ìwọ yóò sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.’”+
14 Nígbà náà ni Áhábù sọ pé: “Nípasẹ̀ ta ni?” ó dáhùn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nípasẹ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ ni.’” Níkẹyìn, ó wí pé: “Ta ni yóò kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìjà ogun náà?” ó dáhùn pé: “Ìwọ ni!”
15 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ka iye àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ, wọ́n sì wá jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n;+ lẹ́yìn wọn, ó ka iye gbogbo ènìyàn náà, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin.
16 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ ní ọ̀sán gangan nígbà tí Bẹni-hádádì ń fi ọtí rọ ara rẹ̀ yó+ nínú àwọn àtíbàbà, òun àti àwọn ọba, àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n tí ń ràn án lọ́wọ́.
17 Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin+ àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ́kọ́ jáde wá, ní kíá, Bẹni-hádádì ránṣẹ́ jáde; wọ́n sì wá sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin kan wà tí wọ́n jáde wá láti Samáríà.”
18 Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ì báà jẹ́ nítorí àlàáfíà ni wọ́n fi jáde wá, ẹ gbá wọn mú láàyè; ì báà sì jẹ́ nítorí ìjà ogun ni wọ́n fi jáde wá, ààyè ni kí ẹ gbá wọn mú.”+
19 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìlú ńlá náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin àwọn ọmọ aládé ti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ àti àwọn ẹgbẹ́ ológun tí ó wà lẹ́yìn wọn.
20 Olúkúlùkù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá ọkùnrin tirẹ̀ balẹ̀; àwọn ará Síríà+ sì fẹsẹ̀ fẹ,+ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn, ṣùgbọ́n Bẹni-hádádì ọba Síríà sá lọ lórí ẹṣin pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin.
21 Ṣùgbọ́n ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣá àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ balẹ̀, ó sì fi ìpakúpa rẹpẹtẹ ṣá àwọn ará Síríà balẹ̀.
22 Nígbà tí ó yá, wòlíì+ náà tọ ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì sọ fún un pé: “Lọ, fún ara rẹ lókun+ kí o sì fiyè sí i, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe;+ nítorí nígbà ìyípo ọdún, ọba Síríà yóò gòkè wá gbéjà kò ọ́.”+
23 Ní ti àwọn ìránṣẹ́ ọba Síríà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọlọ́run wọ́n jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè ńlá.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lágbára jù wá lọ. Nítorí náà, ní ọwọ́ kejì, jẹ́ kí a bá wọn jà lórí ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ kí a sì wò ó bóyá a kì yóò lágbára jù wọ́n lọ.
24 Sì ṣe nǹkan yìí: Mú àwọn ọba kúrò,+ olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi àwọn gómìnà dípò wọn.+
25 Ní tìrẹ, kí o ka iye ẹgbẹ́ ológun fún ara rẹ, èyí tí ó jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun tí ó ṣubú níhà ọ̀dọ̀ tìrẹ, pẹ̀lú ẹṣin fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin; sì jẹ́ kí a bá wọn jà lórí ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ kí a sì wò ó bóyá a kì yóò lágbára jù wọ́n lọ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó fetí sí ohùn wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
26 Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo ọdún pé Bẹni-hádádì bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn ará Síríà+ jọ, ó sì gòkè lọ sí Áfékì+ láti bá Ísírẹ́lì ja ìjà ogun.
27 Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a pè wọ́n jọ, a sì pèsè fún wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ láti pàdé wọn; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó sí iwájú wọn bí agbo ewúrẹ́ táṣẹ́rẹ́ méjì, nígbà tí àwọn ará Síríà, ní tiwọn, kún ilẹ̀.+
28 Nígbà náà ni ènìyàn Ọlọ́run+ tòótọ́ sún mọ́ tòsí, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni, ó ń bá a lọ láti sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nítorí ìdí náà pé àwọn ará Síríà sọ pé: “Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè ńlá, kì í sì í ṣe Ọlọ́run pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀,” dájúdájú, èmi yóò fi gbogbo ogunlọ́gọ̀ ńláǹlà yìí lé ọ lọ́wọ́,+ ẹ ó sì mọ̀ dájúdájú pé èmi ni Jèhófà.’”+
29 Wọ́n sì ń bá a lọ láti wà ní ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn wọ̀nyí ní iwájú àwọn wọ̀nyẹn.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé ìjà ogun bẹ̀rẹ̀; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ará Síríà balẹ̀, ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn tí ń fẹsẹ̀ rìn, ní ọjọ́ kan.
30 Àwọn tí ó sì ṣẹ́ kù bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí Áfékì,+ sínú ìlú ńlá náà; ògiri sì wó lu ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáàrin ọkùnrin tí ó ṣẹ́ kù.+ Ní ti Bẹni-hádádì, ó sá lọ,+ níkẹyìn, ó sì wá sínú ìlú ńlá sínú ìyẹ̀wù inú pátápátá.+
31 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé: “Wàyí o, kíyè sí i, àwa ti gbọ́ pé àwọn ọba ilé Ísírẹ́lì jẹ́ ọba tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+ Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a sán aṣọ àpò ìdọ̀họ+ mọ́ abẹ́nú+ wa, kí a sì fi ìjàrá sí orí wa, sí jẹ́ kí a jáde tọ ọba Ísírẹ́lì lọ. Bóyá yóò pa ọkàn rẹ mọ́ láàyè.”+
32 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ abẹ́nú wọn, pẹ̀lú ìjàrá ní orí wọn, wọ́n sì wọlé tọ ọba Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì wí pé: “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ọkàn mi yè.’” Ó fèsì pé: “Ṣé ó ṣì wà láàyè ni? Arákùnrin mi ni.”
33 Nítorí náà, àwọn ọkùnrin náà+ kà á sí àmì ìṣẹ̀lẹ̀ kan, wọ́n sì yára gbà á gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí ó wá láti inú ìdánúṣe tirẹ̀, wọ́n sì ǹ bá a lọ láti sọ pé: “Arákùnrin rẹ ni Bẹni-hádádì.” Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ẹ wá, ẹ lọ mú un wá.” Nígbà náà ni Bẹni-hádádì jáde tọ̀ ọ́ lọ; lójú ẹsẹ̀, ó sì mú kí ó gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin.+
34 Bẹni-hádádì wá sọ fún un pé: “Àwọn ìlú ńlá+ tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ ni èmi yóò dá padà; ìwọ yóò sì fún ara rẹ ní ojú pópó ní Damásíkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní Samáríà.”
“Ní tèmi, lábẹ́ májẹ̀mú+ ni èmi ó sì fi rán ọ lọ.”
Pẹ̀lú ìyẹn, ó bá a dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.
35 Ọkùnrin kan lára àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀+ Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kọ̀ láti lù ú.
36 Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Nítorí ìdí náà pé o kò fetí sí ohùn Jèhófà, kíyè sí i, ìwọ ń lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, kìnnìún yóò sì ṣá ọ balẹ̀ dájúdájú.” Lẹ́yìn ìyẹn, ó lọ kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, kìnnìún+ sì wá rí i, ó sì ṣá a balẹ̀.+
37 Ó sì wá rí ọkùnrin mìíràn, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Nítorí náà, ọkùnrin náà lù ú, ní lílù àti gbígbọgbẹ́.
38 Wòlíì náà wá lọ dúró jẹ́ẹ́ de ọba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà, ó sì para dà+ ní fífi ọ̀já tí a fi ń di ọgbẹ́ bo ojú.
39 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ọba ti ń kọjá lọ, ó ké sí ọba, ó sì tẹ̀ síwájú láti wí pé:+ “Ìránṣẹ́ rẹ jáde lọ sí ibi tí ìjà ogun ti kira; sì wò ó! ọkùnrin kan ń fi ojú ìlà ogun sílẹ̀, ó mú ọkùnrin kan tọ̀ mí wá, ó sì wá sọ pé, ‘Máa ṣọ́ ọkùnrin yìí. Bí ó bá di àwátì lọ́nàkọnà, ọkàn+ rẹ yóò ní láti dípò ọkàn+ tirẹ̀ pẹ̀lú, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tálẹ́ńtì fàdákà kan ni ìwọ yóò wọ̀n wá.’+
40 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ìránṣẹ́ rẹ ti ń ṣe aápọn níhìn-ín àti lọ́hùn-ún, họ́wù, ó ti lọ.” Látàrí èyí, ọba Ísírẹ́lì wí fún un pé: “Bí ìdájọ́ rẹ ṣe jẹ́ nìyẹn. Ìwọ fúnra rẹ ti pinnu rẹ̀.”+
41 Látàrí ìyẹn, ó mú ọ̀já tí a fi ń di ọgbẹ́ kúrò lójú ara rẹ̀ wéréwéré, ọba Ísírẹ́lì wá dá a mọ̀, pé ó wá láti inú àwọn wòlíì.+
42 Wàyí o, ó sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Nítorí ìdí náà pé o jẹ́ kí ọkùnrin tí a yà sọ́tọ̀ fún mi fún ìparun+ kí ó lọ kúrò lọ́wọ́ rẹ, ọkàn rẹ gbọ́dọ̀ dípò ọkàn+ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn rẹ dípò àwọn ènìyàn rẹ̀.’”+
43 Látàrí ìyẹn, ọba Ísírẹ́lì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ síhà ilé rẹ̀, ó wúgbọ, ó sì dorí kodò,+ ó sì wá sí Samáríà.+

