1 Àwọn Ọba 14:1-31

14  Ní àkókò yẹn gan-an, Ábíjà ọmọkùnrin Jèróbóámù dùbúlẹ̀ àìsàn.+ 2  Nítorí náà, Jèróbóámù sọ fún aya rẹ̀ pé: “Dìde, jọ̀wọ́, kí o sì para dà+ kí wọ́n má bàa mọ̀ pé aya Jèróbóámù ni ọ́, kí o sì lọ sí Ṣílò. Wò ó! Ibẹ̀ ni Áhíjà+ wòlíì wà. Òun ni ó sọ̀rọ̀ nípa mi ní ti dídi ọba lórí àwọn ènìyàn+ yìí. 3  Kí o sì mú ìṣù búrẹ́dì mẹ́wàá+ àti àkàrà alábùwọ́n àti ṣágo+ oyin dání, kí o sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ.+ Dájúdájú, òun ni yóò sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọdékùnrin+ náà fún ọ.” 4  Aya Jèróbóámù sì tẹ́ síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó dìde, ó sì lọ sí Ṣílò,+ ó sì wá sí ilé Áhíjà. Wàyí o, Áhíjà kò ríran, bí ojú rẹ̀ ti là sílẹ̀ rangandan nítorí ọjọ́ orí+ rẹ̀. 5  Jèhófà sì ti sọ fún Áhíjà pé: “Aya Jèróbóámù rèé tí ń bọ̀ wá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ nípa ọmọkùnrin rẹ̀; nítorí tí ó ń ṣàìsàn. Báyìí-báyìí ni kí o bá a sọ. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ ní ẹni tí kò ṣeé dá mọ̀.”+ 6  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Áhíjà gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ó ti ń bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Wọlé, ìwọ aya Jèróbóámù.+ Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe ara rẹ ní ẹni tí kò ṣeé dá mọ̀ nígbà tí ó jẹ́ pé a fi ìhìn-iṣẹ́ mímúná rán mi sí ọ? 7  Lọ, sọ fún Jèróbóámù pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Nítorí ìdí náà pé mo gbé ọ dìde láti àárín àwọn ènìyàn rẹ, kí n lè sọ ọ́ di aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì,+ 8  mo sì tẹ̀ síwájú láti fa ìjọba ya+ kúrò ní ilé Dáfídì, mó sì fi í fún ọ, ìwọ kò sì dà bí ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ẹni tí ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ó sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ tọ̀ mí lẹ́yìn nípa ṣíṣe kìkì ohun tí ó tọ́ ní ojú mi,+ 9  ṣùgbọ́n ìwọ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ, o sì lọ ṣe ọlọ́run mìíràn+ fún ara rẹ àti àwọn ère dídà+ láti mú mi bínú,+ èmi ni o sì ti gbé jù sí ẹ̀yìn rẹ;+ 10  nítorí ìdí yẹn, kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí ilé Jèróbóámù, dájúdájú, èmi yóò ké ẹnikẹ́ni tí ń tọ̀ sára ògiri+ kúrò lọ́dọ̀ Jèróbóámù, aláìní olùrànlọ́wọ́ àti aláìníláárí ní Ísírẹ́lì;+ ní ti tòótọ́, èmi yóò gbá ilé Jèróbóámù kúrò tefétefé,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn bá gbá ẹlẹ́bọ́tọ kúrò títí yóò fi palẹ̀ rẹ̀ mọ́ kúrò nílẹ̀.+ 11  Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ti Jèróbóámù tí ó bá kú ní ìlú ńlá, ni àwọn ajá yóò jẹ;+ ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kú ní pápá, ni àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run yóò jẹ,+ nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.”’ 12  “Àti ìwọ ní tìrẹ, dìde, máa lọ sí ilé rẹ. Nígbà tí ẹsẹ̀ rẹ bá ti wọ inú ìlú ńlá náà, dájúdájú, ọmọ náà yóò kú. 13  Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì pohùn réré ẹkún fún un+ ní tòótọ́, wọn yóò sì sin ín, nítorí pé ẹni yìí nìkan ṣoṣo, nínú àwọn tí ó jẹ́ ti Jèróbóámù, ni yóò dé inú ibi ìsìnkú; nítorí ìdí náà pé ohun rere kan sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni a ti rí nínú rẹ̀ ní ilé Jèróbóámù.+ 14  Dájúdájú, Jèhófà yóò gbé ọba+ kan dìde fún ara rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, tí yóò ké ilé Jèróbóámù kúrò ní ọjọ́ tí a ń wí yìí, bí ó bá sì jẹ́ nísinsìnyí gan-an ńkọ́?+ 15  Jèhófà yóò sì ṣá Ísírẹ́lì balẹ̀ ní tòótọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí esùsú ti ń mì lòólòó nínú omi;+ dájúdájú, òun yóò sì fa Ísírẹ́lì tu+ kúrò ní ilẹ̀+ dáradára yìí tí ó fi fún àwọn baba ńlá wọn, ní tòótọ́ òun yóò sì tú wọ́n ká+ ré kọjá Odò,+ nítorí ìdí náà pé wọ́n ṣe àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ wọn, ní títipa bẹ́ẹ̀ mú Jèhófà bínú.+ 16  Òun yóò sì pa Ísírẹ́lì tì+ ní tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù, èyí tí ó ṣẹ̀ àti èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.”+ 17  Látàrí ìyẹn, aya Jèróbóámù dìde, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì wá sí Tírísà.+ Bí ó ṣe ń dé ibi àbáwọ ilé náà, ọmọdékùnrin náà kú. 18  Nítorí náà, wọ́n sin ín, gbogbo Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùn réré ẹkún fún un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Áhíjà wòlíì. 19  Àti ìyókù àlámọ̀rí Jèróbóámù, bí ó ṣe jagun+ àti bí ó ṣe jọba, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí, nínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì. 20  Àwọn ọjọ́ tí Jèróbóámù sì fi jọba jẹ́ ọdún méjìlélógún, lẹ́yìn èyí tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá+ rẹ̀; Nádábù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀. 21  Ní ti Rèhóbóámù+ ọmọkùnrin Sólómọ́nì, ó di ọba ní Júdà. Ẹni ọdún mọ́kàn-lé-lógójì ni Rèhóbóámù nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́tàdínlógún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú ńlá+ tí Jèhófà yàn nínú gbogbo ẹ̀yà+ Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà ọmọbìnrin Ámónì.+ 22  Júdà sì ń bá a lọ láti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ tí wọ́n fi ru ú lọ́kàn sókè+ sí owú ju gbogbo èyí tí àwọn baba ńlá wọ́n ṣe nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ṣẹ̀.+ 23  Àwọn pẹ̀lú sì ń bá a nìṣó láti kọ́ àwọn ibi gíga+ àti àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ fún ara wọn lórí gbogbo òkè kéékèèké gíga+ àti lábẹ́ gbogbo igi tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+ 24  Àní kárùwà ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì pàápàá wà ní ilẹ̀+ náà. Wọ́n hùwà ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 25  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún karùn-ún Rèhóbóámù Ọba pé Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì gòkè wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. 26  Ó sì wá kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé ọba;+ ohun gbogbo ni ó sì kó.+ Ó sì ń bá a lọ láti kó gbogbo apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+ 27  Nítorí náà, Rèhóbóámù Ọba ṣe àwọn apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sí ìkáwọ́ àwọn olórí àwọn sárésáré,+ àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba.+ 28  A sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbàkúùgbà tí ọba bá wá sí ilé Jèhófà, àwọn sárésáré a gbé wọn, wọn a sì dá wọn padà sí ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ ti àwọn sárésáré.+ 29  Àti ìyókù àlámọ̀rí Rèhóbóámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí àkókò àwọn ọba Júdà? 30  Ogun sì ń ṣẹlẹ̀ láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù nígbà gbogbo.+ 31  Níkẹyìn, Rèhóbóámù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Náámà ọmọbìnrin Ámónì.+ Ábíjámú+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé