Ọbadáyà 1:1-21

 Ìran Ọbadáyà: Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí nípa Édómù:+ “A ti gbọ́ ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, a sì ti rán aṣojú kan sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé, ‘Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a gbé ìjà ogun dìde sí i.’”+  “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di kékeré láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ A tẹ́ńbẹ́lú rẹ gidigidi.+  Ìkùgbù ọkàn-àyà rẹ ni ó ti tàn ọ́ jẹ,+ ìwọ tí ń gbé àwọn ibi kọ́lọ́fín àpáta gàǹgà,+ ibi gíga tí ó ń gbé, ó ń sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé, ‘Ta ni yóò sọ̀ mí kalẹ̀?’  Bí ìwọ bá tilẹ̀ mú ipò rẹ ga bí ti idì, tàbí bí o bá gbé ìtẹ́ rẹ kalẹ̀ sáàárín àwọn ìràwọ̀, ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Bí ó bá jẹ́ àwọn olè ni ó wọlé wá bá ọ, bí àwọn afiniṣèjẹ bá wá ní òru, títí dé àyè wo ni à bá ti pa ọ́ lẹ́nu mọ́?+ Wọn kì yóò ha jí nǹkan bí wọ́n ti fẹ́? Tàbí bí ó bá jẹ́ àwọn olùkó èso àjàrà jọ ni ó wọlé wá bá ọ, wọn kì yóò ha ṣẹ́ èéṣẹ́ díẹ̀ kù bí?+  Wo ibi tí a wá àwọn ti Ísọ̀ dé!+ Wo bí a ṣe wá àwọn ìṣúra rẹ̀ tí ó fi pa mọ́ jáde!  Títí dé ààlà ni wọ́n rán ọ lọ. Àní gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ ti tàn ọ́ jẹ.+ Àwọn ènìyàn tí ó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ ti borí rẹ.+ Àwọn tí ń bá ọ jẹun yóò fi àwọ̀n sábẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ní ìfòyemọ̀.+  Kì yóò ha ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn bí?” ni àsọjáde Jèhófà. “Dájúdájú, èmi yóò sì pa àwọn ọlọ́gbọ́n run kúrò ní Édómù,+ àti ìfòyemọ̀ kúrò ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Ísọ̀.  Àyà àwọn alágbára ńlá rẹ yóò sì já,+ ìwọ Témánì,+ nítorí ìdí náà pé olúkúlùkù ni a óò ké kúrò+ ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Ísọ̀, nítorí ìpànìyàn.+ 10  Nítorí ìwà ipá sí Jékọ́bù+ arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ́,+ dájúdájú, a ó ké ọ kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 11  Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ní ọjọ́ tí àwọn àjèjì kó ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ lọ sí oko òǹdè+ àti nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè pátápátá wọ ẹnubodè+ rẹ̀, tí wọ́n sì ṣẹ́ kèké+ lórí Jerúsálẹ́mù, ìwọ pẹ̀lú dà bí ọ̀kan nínú wọn. 12  “Kò sì yẹ kí o máa wo ìran náà ní ọjọ́ arákùnrin rẹ,+ ní ọjọ́ àgbákò ibi rẹ̀; kò sì yẹ kí o máa yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣègbé lọ;+ kò sì yẹ kí o máa sọ̀rọ̀ ìfọ́nnu ní ọjọ́ wàhálà wọn. 13  Kò yẹ kí o wọ ẹnubodè àwọn ènìyàn mi ní ọjọ́ àjálù wọn.+ Kò yẹ kí ìwọ, àní ìwọ, tẹjú mọ́ ìyọnu àjálù rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀; kò sì yẹ kí o na ọwọ́ jáde sí ọlà rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù rẹ̀.+ 14  Kò sì yẹ kí o dúró sí ìyànà, kí o bàa lè ké àwọn tirẹ̀ tí ó sá àsálà kúrò;+ kò sì yẹ kí o fi àwọn tirẹ̀ tí ó là á já léni lọ́wọ́ ní ọjọ́ wàhálà.+ 15  Nítorí ọjọ́ Jèhófà lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè sún mọ́lé.+ Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ọ.+ Ọ̀nà-ìgbà-bánilò rẹ yóò padà sórí rẹ.+ 16  Nítorí bí ẹ̀yin ṣe mu lórí òkè ńlá mímọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa mu nígbà gbogbo.+ Dájúdájú, wọn yóò mu, wọn yóò sì gbé mì kàló, wọn yóò sì dà bí ẹni pé wọn kò tíì sí rí. 17  “Òkè Ńlá Síónì sì ni ibi tí àwọn tí ó sá àsálà yóò wà,+ yóò sì di ohun mímọ́;+ ilé Jékọ́bù yóò sì gba àwọn nǹkan tí ó jẹ́ tiwọn láti ní.+ 18  Ilé Jékọ́bù yóò sì di iná,+ ilé Jósẹ́fù yóò sì di ọwọ́ iná, ilé Ísọ̀ yóò sì dà bí àgékù pòròpórò;+ wọn yóò sì ti iná bọ̀ wọ́n, wọn yóò sì jẹ wọ́n run. Kì yóò sì sí olùlàájá ní ilé Ísọ̀;+ nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́. 19  Wọn yóò sì gba Négébù, àní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Ísọ̀,+ àti ti Ṣẹ́fẹ́là, àní ti àwọn Filísínì.+ Wọn yóò sì gba pápá Éfúráímù+ àti pápá Samáríà;+ Bẹ́ńjámínì yóò sì gba Gílíádì.+ 20  Àti ní ti àwọn ìgbèkùn ti ohun àfiṣe-odi yìí,+ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ohun tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Kénáánì+ yóò jẹ́ títí dé Sáréfátì.+ Àwọn ìgbèkùn Jerúsálẹ́mù, àwọn tí ó wà ní Séfárádì, yóò sì gba àwọn ìlú ńlá Négébù.+ 21  “Dájúdájú, àwọn olùgbàlà+ yóò sì gòkè wá sórí Òkè Ńlá Síónì,+ kí wọ́n bàa lè ṣe ìdájọ́ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Ísọ̀;+ ipò ọba yóò sì di ti Jèhófà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé