Òwe 6:1-35
6 Ọmọ mi, bí ìwọ bá ti lọ ṣe onídùúró fún ọmọnìkejì rẹ,+ bí ìwọ bá ti bá àjèjì pàápàá bọ ọwọ́,+
2 bí àwọn àsọjáde ẹnu rẹ bá ti dẹkùn mú ọ,+ bí àwọn àsọjáde ẹnu rẹ bá ti mú ọ,
3 nígbà náà, gbé ìgbésẹ̀ yìí, ọmọ mi, kí o sì dá ara rẹ nídè, nítorí pé o ti bọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ ọmọnìkejì rẹ:+ Lọ, rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì bẹ ọmọnìkejì rẹ ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀.+
4 Má fi oorun kankan fún ojú rẹ, tàbí ìtòògbé kankan fún ojú rẹ títàn yanran.+
5 Dá ara rẹ nídè bí àgbàlàǹgbó kúrò ní ọwọ́ náà àti bí ẹyẹ kúrò ní ọwọ́ pẹyẹpẹyẹ.+
6 Tọ eèrà lọ,+ ìwọ ọ̀lẹ;+ wo àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì di ọlọ́gbọ́n.
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, tàbí onípò àṣẹ tàbí olùṣàkóso,
8 ó ń pèsè oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ àní ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn;+ ó ti kó àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè.
9 Yóò ti pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ, tí ìwọ yóò fi wà ní ìdùbúlẹ̀?+ Ìgbà wo ni ìwọ yóò dìde kúrò lójú oorun rẹ?+
10 Oorun díẹ̀ sí i, ìtòògbé díẹ̀ sí i, kíká ọwọ́ pọ̀ díẹ̀ sí i ní ìdùbúlẹ̀,+
11 ipò òṣì rẹ yóò sì dé dájúdájú gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri kan,+ àti àìní rẹ bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra.+
12 Ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun,+ ènìyàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ń rìn tòun ti ọ̀rọ̀ wíwọ́,+
13 ó ń ṣẹ́jú,+ ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣe àmì, ó ń fi àwọn ìka rẹ̀ ṣe ìtọ́ka.+
14 Àyídáyidà ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ Ó ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ohun búburú ní gbogbo ìgbà.+ Ó ń rán kìkìdá asọ̀ jáde ṣáá.+
15 Ìdí nìyẹn tí àjálù rẹ̀ yóò fi dé lójijì;+ ìṣẹ́jú akàn ni òun yóò ṣẹ́, kì yóò sì sí ìmúláradá.+
16 Ohun mẹ́fà ni ń bẹ tí Jèhófà kórìíra ní tòótọ́;+ bẹ́ẹ̀ ni, méje ni ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ọkàn rẹ̀:+
17 ojú gíga fíofío,+ ahọ́n èké,+ àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀,+
18 ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,+ ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú,+
19 ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ,+ àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.+
20 Ìwọ ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́,+ má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.+
21 So wọ́n mọ́ ọkàn-àyà rẹ nígbà gbogbo;+ dè wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.+
22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn káàkiri, yóò máa ṣamọ̀nà rẹ;+ nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, yóò máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí rẹ;+ nígbà tí o bá sì jí, yóò máa fi ọ́ ṣe ìdàníyàn rẹ̀.
23 Nítorí pé àṣẹ jẹ́ fìtílà,+ òfin sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+ àwọn ìtọ́sọ́nà inú ìbáwí sì ni ọ̀nà ìyè,+
24 láti máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ obìnrin búburú,+ lọ́wọ́ dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ahọ́n obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.+
25 Má ṣe fẹ́ ẹwà ojú rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ,+ ǹjẹ́ kí ó má sì fi ojú rẹ̀ dídán gbinrin mú ọ,+
26 nítorí pé, ní tìtorí kárùwà obìnrin, ènìyàn a di ẹni tí kò ní ju ìṣù búrẹ́dì ribiti kan ṣoṣo;+ ṣùgbọ́n ní ti aya ọkùnrin mìíràn, ó ń ṣọdẹ ọkàn tí ó ṣe iyebíye pàápàá.+
27 Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná?+
28 Tàbí kẹ̀, ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyín iná, kí ẹsẹ̀ rẹ̀ pàápàá má sì jó?
29 Bákan náà ni pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀,+ kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí kò ní yẹ fún ìyà.+
30 Àwọn ènìyàn kì í tẹ́ńbẹ́lú olè kìkì nítorí pé ó jalè láti fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn nígbà tí ebi ń pa á.
31 Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá rí i, òun yóò san án padà ní ìlọ́po méje; gbogbo àwọn ohun tí ó níye lórí nínú ilé rẹ̀ ni yóò fi lélẹ̀.+
32 Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá obìnrin ṣe panṣágà jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún;+ ẹni tí ó bá ṣe é ń run ọkàn ara rẹ̀.+
33 Yóò rí ìyọnu àti àbùkù,+ a kì yóò sì nu ẹ̀gàn rẹ̀ nù.+
34 Nítorí owú ni ìhónú abarapá ọkùnrin,+ kì yóò sì fi ìyọ́nú hàn ní ọjọ́ ẹ̀san.+
35 Kì yóò fi ìgbatẹnirò kankan hàn fún ìràpadà èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ẹ̀mí ìmúratán hàn, láìka bí o ti mú kí ẹ̀bùn náà pọ̀ tó.