Òwe 5:1-23
5 Ọmọ mi, fetí sí ọgbọ́n mi.+ Dẹ etí rẹ sí ìfòyemọ̀ mi,+
2 kí o bàa lè ṣọ́ agbára láti ronú;+ kí ètè tìrẹ sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ìmọ̀.+
3 Nítorí ètè àjèjì obìnrin ń kán tótó bí afárá oyin,+ òkè ẹnu rẹ̀ sì dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ju òróró lọ.+
4 Ṣùgbọ́n ohun tí ó máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ korò bí iwọ;+ ó mú bí idà olójú méjì.+
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ikú.+ Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ gan-an fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ṣìọ́ọ̀lù.+
6 Ipa ọ̀nà ìyè ni òun kò ṣàgbéyẹ̀wò.+ Àwọn òpó ọ̀nà rẹ̀ ṣe kọ́lọkọ̀lọ, kò mọ ibi tí wọ́n lọ.+
7 Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ,+ ẹ má sì yà kúrò nínú àwọn àsọjáde ẹnu mi.+
8 Jẹ́ kí ọ̀nà rẹ jìnnà réré sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀,+
9 kí ìwọ má bàa fi iyì rẹ fún àwọn ẹlòmíràn,+ tàbí kí o fi àwọn ọdún rẹ fún ohun tí ó níkà;+
10 kí àwọn àjèjì má bàa fi agbára rẹ tẹ́ ara wọn lọ́rùn,+ tàbí kí àwọn nǹkan tí ìwọ fi ìrora rí gbà wà ní ilé ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+
11 tàbí kí o wá máa kérora ní ọjọ́ ọ̀la rẹ+ nígbà tí ẹran ara rẹ àti ẹ̀yà ara rẹ bá wá sí òpin.+
12 Dájúdájú, ìwọ yóò wí pé: “Ẹ wo bí mo ti kórìíra ìbáwí tó,+ ẹ sì wo bí ọkàn-àyà mi ti ṣàìbọ̀wọ̀ àní fún ìbáwí àfitọ́nisọ́nà tó!+
13 Èmi kò sì fetí sí ohùn àwọn olùkọ́ni mi,+ èmi kò sì dẹ etí mi sí àwọn olùkọ́ mi.+
14 Tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn ni mo wá fi wà nínú gbogbo onírúurú ìwà búburú+ ní àárín ìjọ àti àpéjọ.”+
15 Mu omi láti inú ìkùdu tìrẹ, àti omi tí ń sun láti inú kànga tìrẹ.+
16 Ó ha yẹ kí àwọn ìsun rẹ tú ká sí ìta,+ àwọn ìṣàn omi rẹ ní àwọn ojúde ìlú?
17 Jẹ́ kí wọ́n wà fún ìwọ nìkan ṣoṣo, kí ó má sì jẹ́ ti àwọn àjèjì pẹ̀lú rẹ.+
18 Jẹ́ kí orísun omi rẹ jẹ́ èyí tí ó ní ìbùkún,+ kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ,+
19 egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá.+ Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà.+ Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.+
20 Nítorí náà, ọmọ mi, èé ṣe tí ìwọ yóò fi máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú àjèjì obìnrin tàbí tí ìwọ yóò fi gbá oókan àyà obìnrin ilẹ̀ òkèèrè mọ́ra?+
21 Nítorí àwọn ọ̀nà ènìyàn ń bẹ ní iwájú Jèhófà,+ ó sì ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo òpó ọ̀nà rẹ̀.+
22 Àwọn ìṣìnà ẹni burúkú yóò mú òun fúnra rẹ̀,+ inú àwọn ìjàrá ẹ̀ṣẹ̀ òun fúnra rẹ̀ sì ni a ó ti gbá a mú.+
23 Òun ni ẹni tí yóò kú nítorí pé kò sí ìbáwí,+ àti nítorí pé nínú ọ̀pọ̀ yanturu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, ó ṣáko lọ.+

