Òwe 31:1-31
31 Àwọn ọ̀rọ̀ Lémúẹ́lì Ọba, ìhìn iṣẹ́ wíwúwo+ tí ìyá rẹ̀ fi fún un bí ìtọ́sọ́nà:+
2 Kí ni mo ń sọ, ìwọ ọmọ mi, kí sì ni, ìwọ ọmọ ikùn mi,+ kí sì ni, ìwọ ọmọ àwọn ẹ̀jẹ́ mi?+
3 Má fi ìmí rẹ fún àwọn obìnrin,+ tàbí àwọn ọ̀nà rẹ fún ohun tí ń ṣokùnfà nínu àwọn ọba nù.+
4 Kì í ṣe fún àwọn ọba, Lémúẹ́lì, kì í ṣe fún àwọn ọba láti máa mu wáìnì tàbí fún àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga láti máa sọ pé: “Ọtí tí ń pani dà?”+
5 kí ènìyàn má bàa mu, kí ó sì gbàgbé ohun tí a fàṣẹ gbé kalẹ̀, kí ó sì ṣe ìyípo ọ̀ràn ẹjọ́ èyíkéyìí lára àwọn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́.+
6 Ẹ fi ọtí tí ń pani fún ẹni tí ń sún mọ́ àtiṣègbé+ àti wáìnì fún àwọn ọlọ́kàn kíkorò.+
7 Kí ènìyàn mu kí ó sì gbàgbé ipò òṣì rẹ̀, kí ènìyàn má sì rántí ìdààmú tirẹ̀ mọ́.
8 La ẹnu rẹ fún ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀,+ nínú ọ̀ràn ẹjọ́ gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ.+
9 La ẹnu rẹ, ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo, kí o sì gba ọ̀ràn ẹjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì rò.+
א [Áléfì]
10 Ta ni ó lè rí aya tí ó dáńgájíá?+ Ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn.
ב [Bétì]
11 Ọkàn-àyà olúwa rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, kò sì ṣaláìní èrè.+
ג [Gímélì]
12 Obìnrin náà fi ohun rere san án lẹ́san, láìjẹ́ ohun búburú, ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.+
ד [Dálétì]
13 Obìnrin náà wá irun àgùntàn àti aṣọ ọ̀gbọ̀, ó sì ń ṣe ohun yòówù tí ọwọ́ ara rẹ̀ ní inú dídùn sí.+
ה [Híì]
14 Ó dà bí àwọn ọkọ̀ òkun tí í ṣe ti olówò kan.+ Ibi jíjìnnàréré ni ó ti ń mú oúnjẹ rẹ̀ wá.
ו [Wọ́ọ̀]
15 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó máa ń dìde nígbà tí ó ṣì jẹ́ òru,+ a sì fi oúnjẹ fún agbo ilé rẹ̀ àti ìpín tí a lànà sílẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀.+
ז [Sáyínì]
16 Ó gbé pápá kan yẹ̀ wò, ó sì tẹ̀ síwájú láti rí i gbà;+ nínú èso ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi gbin ọgbà àjàrà.+
ח [Kétì]
17 Ó fi okun di ìgbáròkó rẹ̀ lámùrè, ó sì mú apá rẹ̀ le.+
ט [Tétì]
18 Ó róye pé òwò òun dára; fìtílà rẹ̀ kì í kú ní òru.+
י [Yódì]
19 Ó na ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀pá ìrànwú, ọwọ́ tirẹ̀ sì di ìrànwú mú.+
כ [Káfì]
20 Ó na àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òtòṣì.+
ל [Lámédì]
21 Ẹ̀rù kò bà á fún agbo ilé rẹ̀ nítorí ìrì dídì, nítorí pé ẹ̀wù oníṣẹ̀ẹ́po méjì ni gbogbo agbo ilé rẹ̀ wọ̀.+
מ [Mémì]
22 Ó ṣe àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn+ fún ara rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró.+
נ [Núnì]
23 Ẹni mímọ̀ ni olúwa obìnrin+ náà jẹ́ ní àwọn ẹnubodè,+ nígbà tí ó bá jókòó pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà.
ס [Sámékì]
24 Ó ṣe àwọn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ pàápàá,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tà wọ́n, ó sì fi àwọn ìgbànú fún àwọn ọkùnrin oníṣòwò.
ע [Áyínì]
25 Okun àti ọlá ńlá ni aṣọ rẹ̀,+ ó sì ń rẹ́rìn-ín nípa ọjọ́ tí ń bọ̀ níwájú.+
פ [Péè]
26 Ó fi ọgbọ́n la ẹnu rẹ̀,+ òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀.+
צ [Sádì]
27 Ó ń ṣọ́ àwọn ohun tí ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀, kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.+
ק [Kófì]
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní aláyọ̀;+ olúwa rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.+
ר [Réṣì]
29 Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin ní ń bẹ tí ó fi ìdáńgájíá hàn,+ ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ lékè gbogbo wọn.+
ש [Ṣínì]
30 Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké,+ ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán;+ ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.+
ת [Tọ́ọ̀]
31 Ẹ fún un lára èso ọwọ́ rẹ̀,+ kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè pàápàá.+

