Òwe 21:1-31
21 Ọkàn-àyà ọba dà bí ìṣàn omi ní ọwọ́ Jèhófà.+ Ibi gbogbo tí ó bá ní inú dídùn sí, ni ó ń darí rẹ̀ sí.+
2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dúró ṣánṣán lójú ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n Jèhófà ni ó ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà.+
3 Láti máa bá a lọ ní ṣíṣe òdodo àti ìdájọ́ wu Jèhófà ju ẹbọ lọ.+
4 Ojú ìrera àti ọkàn-àyà ìṣefọ́nńté,+ fìtílà àwọn ẹni burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ ni.+
5 Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní,+ ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.+
6 Fífi ahọ́n èké kó ìṣúra jọ, jẹ́ èémí àmíjáde tí a ń fẹ́ lọ,+ nínú ọ̀ràn àwọn tí ń wá ikú.+
7 Àní ìfiṣèjẹ láti ọwọ́ àwọn ẹni burúkú ni yóò wọ́ wọn lọ,+ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe ìdájọ́ òdodo.+
8 Ọkùnrin kan, àní àjèjì, jẹ́ oníwà wíwọ́ ní ọ̀nà rẹ̀;+ ṣùgbọ́n ẹni mímọ́ gaara jẹ́ adúróṣánṣán nínú ìgbòkègbodò rẹ̀.+
9 Ó sàn láti máa gbé lórí igun òrùlé+ ju láti máa gbé pẹ̀lú aya alásọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ilé kan náà.+
10 Àní ọkàn ẹni burúkú ti fà sí ohun tí ó burú;+ kì yóò fi ojú rere hàn sí ọmọnìkejì rẹ̀ ní ojú rẹ̀.+
11 Nípa bíbu ìtanràn lé olùyọṣùtì ni aláìní ìrírí fi ń di ọlọ́gbọ́n;+ nípa fífi tí ènìyàn ń fi ìjìnlẹ̀ òye fún ọlọ́gbọ́n sì ni ó fi ń ní ìmọ̀.+
12 Olódodo Náà ń fún ilé ẹni burúkú ní àfiyèsí,+ ó ń dojú àwọn ẹni burúkú dé sí ìyọnu àjálù wọn.+
13 Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá di etí rẹ̀ sí igbe ìráhùn ẹni rírẹlẹ̀,+ òun alára yóò pè, a kì yóò sì dá a lóhùn.+
14 Ẹ̀bùn tí a fi fúnni ní ìkọ̀kọ̀ ń mú ìbínú rọlẹ̀;+ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní oókan àyà+ sì ń mú ìhónú líle rọlẹ̀.
15 Ó jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀ fún olódodo láti ṣe ìdájọ́ òdodo,+ ṣùgbọ́n ohun jíjáni láyà ń bẹ fún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.+
16 Ní ti ènìyàn tí ń rìn gbéregbère kúrò ní ọ̀nà ìjìnlẹ̀ òye,+ òun yóò sinmi àní ní ìjọ àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú.+
17 Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ àríyá yóò jẹ́ ẹnì kan tí ó wà nínú àìní;+ ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró kì yóò jèrè ọrọ̀.+
18 Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo;+ ẹni tí ń ṣe àdàkàdekè a sì gba ipò àwọn adúróṣánṣán.+
19 Ó sàn láti máa gbé ní ilẹ̀ aginjù ju gbígbé pẹ̀lú aya alásọ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú pákáǹleke.+
20 Ìṣúra fífani-lọ́kàn-mọ́ra àti òróró ń bẹ ní ibùjókòó ọlọ́gbọ́n,+ ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó jẹ́ arìndìn yóò gbé e mì.+
21 Ẹni tí ń lépa òdodo+ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.+
22 Ọlọ́gbọ́n ti gun ìlú ńlá àwọn alágbára ńlá, kí ó lè rẹ okun ìgbọ́kànlé rẹ̀ sílẹ̀.+
23 Ẹni tí ń pa ẹnu rẹ̀ àti ahọ́n rẹ̀ mọ́ ń pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àwọn wàhálà.+
24 Oníkùgbù, afọ́nnu lọ́nà ìjọra-ẹni-lójú ni orúkọ ẹni tí ń fi ìbínú kíkan ti ìkùgbù hùwà.+
25 Àní ìfàsí-ọkàn ọ̀lẹ ni yóò fi ikú pa á, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.+
26 Gbogbo ọjọ́ ni ó ti fi hàn pẹ̀lú ìháragàgà pé òun ní ìfàsí-ọkàn, ṣùgbọ́n olódodo ń fúnni láìfa nǹkan kan sẹ́yìn.+
27 Ẹbọ àwọn ẹni burúkú jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+ Mélòómélòó ni ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá mú un wá tòun ti ìwà àìníjàánu.+
28 Òpùrọ́ ẹlẹ́rìí yóò ṣègbé,+ ṣùgbọ́n ènìyàn tí ń fetí sílẹ̀ yóò máa sọ̀rọ̀ àní títí láé.+
29 Ènìyàn burúkú ti mójú kuku,+ ṣùgbọ́n adúróṣánṣán ni yóò fìdí àwọn ọ̀nà rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+
30 Kò sí ọgbọ́n kankan, tàbí ìfòyemọ̀ èyíkéyìí, tàbí ìmọ̀ràn èyíkéyìí ní ìlòdìsí Jèhófà.+
31 Ẹṣin ni ohun tí a pèsè sílẹ̀ fún ọjọ́ ìjà ogun,+ ṣùgbọ́n ti Jèhófà ni ìgbàlà.+