Òwe 19:1-29
19 Ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ tí ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀ sàn+ ju ẹni tí ó jẹ́ oníwà wíwọ́ ní ètè rẹ̀, àti ẹni tí ó jẹ́ arìndìn.+
2 Pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí ọkàn wà láìsí ìmọ̀ kò dára,+ ẹni tí ó bá sì ń ṣe kánkán ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀.+
3 Ìwà òmùgọ̀ ará ayé ni ó lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po,+ ọkàn-àyà rẹ̀ sì wá di èyí tí ó kún fún ìhónú sí Jèhófà.+
4 Ọlà ń jẹ́ kí alábàákẹ́gbẹ́ di púpọ̀ sí i,+ ṣùgbọ́n ẹni rírẹlẹ̀ ń di ẹni tí a pín níyà sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pàápàá.+
5 Ẹlẹ́rìí èké kì yóò bọ́ lọ́wọ́ ìyà,+ ẹni tí ń gbé irọ́ yọ kì yóò sì yè bọ́.+
6 Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ń tu ọ̀tọ̀kùlú lójú,+ gbogbo ènìyàn sì ni alábàákẹ́gbẹ́ ènìyàn tí ń bunni ní ẹ̀bùn.+
7 Gbogbo àwọn arákùnrin ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ kórìíra rẹ̀.+ Ẹ wo bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ti jìnnà pátápátá sí i tó!+ Ó ń lépa wọn pẹ̀lú ohun tí yóò sọ; wọn kò sí.+
8 Ẹni tí ń jèrè ọkàn-àyà+ nífẹ̀ẹ́ ọkàn ara rẹ̀. Ẹni tí ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ìfòyemọ̀ yóò rí ire.+
9 Ẹlẹ́rìí èké kì yóò bọ́ lọ́wọ́ ìyà,+ ẹni tí ń gbé irọ́ yọ yóò sì ṣègbé.+
10 Fàájì kò yẹ ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ arìndìn.+ Áńbọ̀sìbọ́sí kí ìránṣẹ́ máa wá ṣàkóso lé àwọn ọmọ aládé lórí!+
11 Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú,+ ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.+
12 Ìhónú ọba jẹ́ kíkùn hùn-ùn bí ti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀,+ ṣùgbọ́n ìfẹ́ rere rẹ̀ dà bí ìrì lára ewéko.+
13 Arìndìn ọmọ jẹ́ àgbákò fún baba rẹ̀,+ asọ̀ aya sì dà bí òrùlé jíjò tí ń léni lọ.+
14 Ogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ni ilé àti ọlà,+ ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti wá.+
15 Ìwà ọ̀lẹ máa ń mú kí oorun àsùnwọra gbéni lọ,+ ebi sì máa ń pa ọkàn tí ó wà dẹngbẹrẹ.+
16 Ẹni tí ń pa àṣẹ mọ́ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́;+ ẹni tí ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀nà ara rẹ̀ ni a ó fi ikú pa.+
17 Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín,+ Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.+
18 Na ọmọ rẹ nígbà tí ìrètí ṣì wà;+ má sì gbé ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn rẹ sókè sí fífi ikú pa á.+
19 Ẹni tí ó bá ní ìhónú ńlá ni a óò máa bu ìtanràn lé;+ nítorí pé bí o bá dá a nídè, ìwọ yóò tún máa ṣe é léraléra.+
20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí,+ kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.+
21 Ọ̀pọ̀ ni ìwéwèé tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ènìyàn,+ ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn Jèhófà ni yóò dúró.+
22 Ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra nínú ará ayé ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́;+ ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ sì sàn ju òpùrọ́ ènìyàn.+
23 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa ń tẹ̀ sí ìhà ìyè,+ ènìyàn yóò sì sùn tẹ́rùn ní òru;+ ohun tí ó burú kì yóò bẹni wò.+
24 Ọ̀lẹ fi ọwọ́ ara rẹ̀ pa mọ́ sínú àwokòtò àsè;+ kò lè mú un padà àní sí ẹnu òun fúnra rẹ̀.+
25 Gbá olùyọṣùtì,+ kí aláìní ìrírí lè di afọgbọ́nhùwà;+ sì fi ìbáwí tọ́ olóye sọ́nà, kí ó lè fi òye mọ ìmọ̀.+
26 Ẹni tí ń ṣe baba níkà tí ó sì lé ìyá lọ,+ jẹ́ ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú àti lọ́nà tí ń dójú tini.+
27 Ọmọ mi, ṣíwọ́ fífetísí ìbáwí, yóò sì túmọ̀ sí ṣíṣáko lọ kúrò nínú àwọn àsọjáde ìmọ̀.+
28 Ẹlẹ́rìí tí kò dára fún ohunkóhun ń fi ìdájọ́ òdodo ṣẹ̀sín,+ àní ẹnu àwọn ènìyàn burúkú sì ń gbé ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ mì.+
29 A ti fìdí àwọn ìdájọ́ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àwọn olùyọṣùtì,+ àti ẹgba fún ẹ̀yìn àwọn arìndìn.+

