Òwe 17:1-28
17 Búrẹ́dì gbígbẹ tòun ti ìdákẹ́jẹ́ẹ́+ sàn ju ilé tí ó kún fún àwọn ẹbọ pa pọ̀ pẹ̀lú aáwọ̀.+
2 Ìránṣẹ́ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn yóò ṣàkóso lórí ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú,+ yóò sì ṣe àjọpín ogún láàárín àwọn arákùnrin.+
3 Ìkòkò ìyọ́hunmọ́ wà fún fàdákà àti ìléru fún wúrà,+ ṣùgbọ́n Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.+
4 Aṣebi ń fetí sí ètè ìṣenilọ́ṣẹ́.+ Aṣèké ń fi etí sí ahọ́n tí ń fa àgbákò.+
5 Ẹni tí ó bá ń fi aláìnílọ́wọ́ ṣẹ̀sín ti gan Olùṣẹ̀dá rẹ̀.+ Ẹni tí ó bá kún fún ìdùnnú nítorí àjálù ẹlòmíràn kì yóò bọ́ lọ́wọ́ ìyà.+
6 Adé arúgbó ni àwọn ọmọ-ọmọ,+ ẹwà àwọn ọmọ sì ni baba wọn.+
7 Ètè ìdúróṣánṣán kò yẹ ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ òpònú.+ Áńbọ̀sìbọ́sí ètè èké fún ọ̀tọ̀kùlú!+
8 Ẹ̀bùn jẹ́ òkúta tí ń jèrè ojú rere lójú olúwa rẹ̀ atóbilọ́lá.+ Ibi gbogbo tí òun bá yíjú sí ni yóò ti máa kẹ́sẹ járí.+
9 Ẹni tí ń bo ìrélànàkọjá mọ́lẹ̀ ń wá ìfẹ́,+ ẹni tí ó sì ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ọ̀ràn, ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.+
10 Ìbáwí mímúná ń ṣiṣẹ́ jinlẹ̀ nínú ẹni tí ó ní òye+ ju lílu arìndìn ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.+
11 Kìkì ìṣọ̀tẹ̀ ni ẹni búburú ń wá,+ ìkà sì ni ońṣẹ́ tí a rán sí i.+
12 Ó yá kí ènìyàn pàdé béárì tí ó ṣòfò ọmọ+ rẹ̀ ju kí ó pàdé ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ arìndìn nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.+
13 Ní ti ẹnikẹ́ni tí ń fi búburú san ire,+ ohun búburú kì yóò ṣí kúrò ní ilé rẹ̀.+
14 Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde;+ nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.+
15 Ẹnikẹ́ni tí ń pe ẹni burúkú ní olódodo+ àti ẹnikẹ́ni tí ń pe olódodo ní ẹni burúkú+—àní àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.+
16 Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé iye owó láti fi ra ọgbọ́n ń bẹ ní ọwọ́ arìndìn,+ nígbà tí kò ní ọkàn-àyà?+
17 Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà,+ ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.+
18 Ènìyàn tí ọkàn-àyà kù fún a máa bọ ọwọ́,+ ní ṣíṣe onídùúró pátápátá níwájú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.+
19 Ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìrélànàkọjá nífẹ̀ẹ́ ìjàkadì.+ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀ ní gíga ń wá ìfọ́yángá.+
20 Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́kàn-àyà wíwọ́ kì yóò rí ire,+ ẹni tí ó bá sì ti yí po ní ahọ́n rẹ̀ yóò já sínú ìyọnu àjálù.+
21 Ẹnikẹ́ni tí ó bí arìndìn ọmọ—ẹ̀dùn-ọkàn ni ó jẹ́ fún un;+ baba òpònú ọmọ kì í sì í yọ̀.+
22 Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn,+ ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.+
23 Ènìyàn burúkú yóò mú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ pàápàá ní oókan àyà+ láti yí ipa ọ̀nà ìdájọ́ po.+
24 Ọgbọ́n wà níwájú olóye,+ ṣùgbọ́n ojú arìndìn wà ní ìkángun ilẹ̀ ayé.+
25 Arìndìn ọmọ jẹ́ ìbìnújẹ́ fún baba rẹ̀+ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i.+
26 Pẹ̀lúpẹ̀lù, bíbu ìtanràn lé olódodo kò dára.+ Láti kọlu àwọn ọ̀tọ̀kùlú lòdì sí ohun dídúró ṣánṣán.+
27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀,+ ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.+
28 Ẹni tí ó tilẹ̀ ya òmùgọ̀, nígbà tí ó bá dákẹ́, ni a ó kà sí ọlọ́gbọ́n;+ ẹni tí ó pa ètè ara rẹ̀ dé, ni a ó kà sí ẹni tí ó ní òye.

