Òwe 14:1-35
14 Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀,+ ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ òmùgọ̀ a fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya á lulẹ̀.+
2 Ẹni tí ń rìn nínú ìdúróṣánṣán rẹ̀ ń bẹ̀rù Jèhófà,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ oníwà wíwọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀.+
3 Ọ̀pá ìrera ń bẹ ní ẹnu òmùgọ̀,+ ṣùgbọ́n ètè àwọn ọlọ́gbọ́n yóò máa ṣọ́ wọn.+
4 Níbi tí àwọn ẹran ọ̀sìn kò sí, ibùjẹ ẹran a mọ́, ṣùgbọ́n irè oko pọ̀ yanturu nítorí agbára akọ màlúù.
5 Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ kì yóò purọ́,+ ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké ń gbé irọ́ pátápátá yọ.+
6 Olùyọṣùtì ti wá ọ̀nà àtirí ọgbọ́n, kò sì sí; ṣùgbọ́n sí olóye, ìmọ̀ jẹ́ ohun rírọrùn.+
7 Kúrò ní iwájú arìndìn,+ nítorí ó dájú pé ìwọ kì yóò ṣàkíyèsí ètè ìmọ̀.+
8 Ọgbọ́n afọgbọ́nhùwà ni láti lóye ọ̀nà ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ àwọn arìndìn ni ẹ̀tàn.+
9 Òmùgọ̀ ni àwọn tí ń fi ẹ̀bi ṣẹ̀sín,+ ṣùgbọ́n ìfohùnṣọ̀kan wà láàárín àwọn adúróṣánṣán.+
10 Ọkàn-àyà mọ ìkorò ọkàn ẹni,+ kò sì sí àjèjì tí yóò tojú bọ ayọ̀ yíyọ̀ rẹ̀.
11 A ó pa ilé àwọn ènìyàn burúkú rẹ́ ráúráú,+ ṣùgbọ́n àgọ́ àwọn adúróṣánṣán yóò gbilẹ̀.+
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn,+ ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.+
13 Nínú ẹ̀rín pàápàá, ọkàn-àyà lè wà nínú ìrora;+ ẹ̀dùn-ọkàn sì ni ayọ̀ yíyọ̀ máa ń parí sí.+
14 Ẹni tí ó jẹ́ aláìṣòtítọ́ ní ọkàn-àyà yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ọ̀nà ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ènìyàn rere nínú àwọn ìyọrísí ìbálò rẹ̀.+
15 Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀,+ ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.+
16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù, ó sì yí padà kúrò nínú ìwà búburú,+ ṣùgbọ́n arìndìn ń bínú kíkankíkan, ó sì ní ìgbọ́kànlé nínú ara rẹ̀.+
17 Ẹni tí ó bá ń yára bínú yóò hu ìwà òmùgọ̀,+ ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní agbára láti ronú ni a kórìíra.+
18 Dájúdájú, aláìní ìrírí yóò fi ìwà òmùgọ̀ ṣe ìní,+ ṣùgbọ́n àwọn afọgbọ́nhùwà yóò gbé ìmọ̀ rù gẹ́gẹ́ bí ìwérí.+
19 Àwọn ènìyàn búburú yóò ní láti tẹrí ba níwájú àwọn ẹni rere,+ àti àwọn ènìyàn burúkú ní àwọn ẹnubodè olódodo.
20 Lójú ọmọnìkejì rẹ̀ pàápàá, ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ jẹ́ ẹni ìkórìíra,+ ṣùgbọ́n púpọ̀ ni ọ̀rẹ́ ọlọ́rọ̀.+
21 Ẹni tí ń tẹ́ńbẹ́lú ọmọnìkejì rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,+ ṣùgbọ́n aláyọ̀ ni ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+
22 Àwọn tí ń hùmọ̀ ibi kì yóò ha máa rìn gbéregbère?+ Ṣùgbọ́n inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ ń bẹ ní ti àwọn tí ń hùmọ̀ ohun rere.+
23 Nípasẹ̀ onírúurú làálàá gbogbo ni àǹfààní fi máa ń wà,+ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè lásán-làsàn máa ń tẹ̀ sí àìní.
24 Adé àwọn ọlọ́gbọ́n ni ọrọ̀ wọn; ìwà òmùgọ̀ àwọn arìndìn jẹ́ ìwà òmùgọ̀.+
25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ ń dá àwọn ọkàn nídè,+ ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ ẹlẹ́tàn ń gbé irọ́ pátápátá yọ.+
26 Inú ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìgbọ́kànlé lílágbára wà,+ ibi ìsádi yóò sì wá wà fún àwọn ọmọ rẹ̀.+
27 Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ kànga ìyè,+ láti yí padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.+
28 Inú ògìdìgbó àwọn ènìyàn ni ọ̀ṣọ́ ọba wà,+ ṣùgbọ́n inú àìsí àwùjọ ènìyàn ni ìparun onípò àṣẹ gíga.+
29 Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.+
30 Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara,+ ṣùgbọ́n owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.+
31 Ẹni tí ń lu ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì ti gan Olùṣẹ̀dá rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn òtòṣì ń yìn Ín lógo.+
32 A ó ti ẹni burúkú lulẹ̀ nítorí ìwà búburú rẹ̀,+ ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ibi ìsádi nínú ìwà títọ́ rẹ̀.+
33 Inú ọkàn-àyà olóye ni ọgbọ́n fìdí kalẹ̀ sí,+ ní àárín àwọn arìndìn sì ni ó ti di mímọ̀.
34 Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè ga,+ ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ohun ìtìjú fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.+
35 Ìdùnnú ọba ń bẹ nínú ìránṣẹ́ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà,+ ṣùgbọ́n ìbínú kíkan rẹ̀ wá wà lórí èyí tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú.+

