Òwe 1:1-33
1 Òwe+ Sólómọ́nì+ ọmọkùnrin Dáfídì,+ ọba Ísírẹ́lì,+
2 fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n+ àti ìbáwí,+ láti fi òye mọ àwọn àsọjáde òye,+
3 láti gba ìbáwí+ tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye,+ òdodo+ àti ìdájọ́+ àti ìdúróṣánṣán,+
4 láti fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà,+ láti fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀+ àti agbára láti ronú.+
5 Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni+ púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá,+
6 láti lóye òwe àti ọ̀rọ̀ àdììtú,+ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n+ àti àlọ́ wọn.+
7 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀.+ Ọgbọ́n àti ìbáwí ni àwọn òmùgọ̀ lásán-làsàn ti tẹ́ńbẹ́lú.+
8 Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba+ rẹ, má sì ṣá òfin ìyá+ rẹ tì.
9 Nítorí ọ̀ṣọ́ òdòdó fífanimọ́ra ni wọ́n jẹ́ fún orí+ rẹ àti àtàtà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún ọrùn+ rẹ.
10 Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá gbìyànjú láti sún ọ dẹ́ṣẹ̀, má gbà.+
11 Bí wọ́n bá ń wí pé: “Bá wa lọ. Jẹ́ kí a ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀.+ Jẹ́ kí a ba sí ibi tí ó lùmọ́ de àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ láìnídìí.+
12 Jẹ́ kí a gbé wọn mì láàyè+ bí Ṣìọ́ọ̀lù+ ti ń ṣe, àní lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+
13 Jẹ́ kí a wá onírúurú ohun iyebíye tí ó níye lórí kàn.+ Jẹ́ kí a fi ohun ìfiṣèjẹ kún ilé wa.+
14 Ó yẹ kí o da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ tiwa. Jẹ́ kí gbogbo wa jọ ní ẹyọ àpò kan ṣoṣo”+—
15 ọmọ mi, má ṣe bá wọn rìn pọ̀ ní ọ̀nà.+ Fa ẹsẹ̀ rẹ sẹ́yìn kúrò ní òpópónà wọn.+
16 Nítorí ẹsẹ̀ wọn jẹ́ èyí tí ń sáré sí kìkì ìwà búburú,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+
17 Nítorí lásán ni a tẹ́ àwọ̀n sílẹ̀ lójú ohunkóhun tí ó ní ìyẹ́ apá.+
18 Nítorí náà, àwọn fúnra wọn ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ àwọn wọ̀nyí gan-an;+ wọ́n ba sí ibi tí ó lùmọ́ de ọkàn wọn.+
19 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo ẹni tí ń jẹ èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu rí.+ Ó máa ń gba ọkàn àwọn tí ó ni ín pàápàá lọ.+
20 Ọgbọ́n+ tòótọ́ ń ké sókè ní ojú pópó+ gan-an. Àwọn ojúde ìlú ni ó ti ń fọ ohùn+ rẹ̀ jáde.
21 Ìpẹ̀kun òkè àwọn ojú pópó aláriwo ni ó ti ń ké jáde.+ Ibi àtiwọ àwọn ẹnubodè tí ó wọ ìlú ńlá ni ó ti ń sọ àwọn àsọjáde tirẹ̀+ pé:
22 “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìní ìrírí yóò fi máa nífẹ̀ẹ́ àìní ìrírí,+ yóò sì ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin olùyọṣùtì yóò fi máa fẹ́ ìyọṣùtì+ gbáà fún ara yín, yóò sì ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin arìndìn yóò fi máa kórìíra ìmọ̀?+
23 Yí padà nítorí ìbáwí àfitọ́nisọ́nà+ mi. Nígbà náà, èmi yóò mú kí ẹ̀mí mi tú jáde sórí yín;+ èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi di mímọ̀ fún yín dájúdájú.+
24 Nítorí pé mo ti ké jáde, ṣùgbọ́n ẹ ń bá a nìṣó ní kíkọ̀,+ mo ti na ọwọ́ mi jáde, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ń fetí sílẹ̀,+
25 ẹ sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣàìnáání gbogbo ìmọ̀ràn mi,+ ẹ kò sì gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mi,+
26 èmi pẹ̀lú, ní tèmi, yóò fi àjálù tiyín rẹ́rìn-ín,+ èmi yóò fi yín ṣe ẹlẹ́yà nígbà tí ohun tí ń mú ìbẹ̀rùbojo bá yín bá dé,+
27 nígbà tí ohun tí ń mú ìbẹ̀rùbojo bá yín bá dé gẹ́gẹ́ bí ìjì, tí àjálù tiyín sì dé ìhín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúùfù oníjì,+ nígbà tí wàhálà àti àwọn àkókò ìnira bá dé bá yín.+
28 Ní àkókò yẹn, wọn yóò máa pè mí ṣáá, ṣùgbọ́n èmi kì yóò dá wọn lóhùn;+ wọn yóò máa wá mi ṣáá, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi,+
29 nítorí ìdí náà pé wọ́n kórìíra ìmọ̀,+ ìbẹ̀rù Jèhófà ni wọn kò sì yàn.+
30 Wọn kò gba ìmọ̀ràn mi;+ wọn kò bọ̀wọ̀ fún gbogbo ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mi.+
31 Nítorí náà, wọn yóò jẹ nínú èso ọ̀nà wọn,+ a ó sì fi àwọn ìmọ̀ràn tiwọn rọ wọ́n yó.+
32 Nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀+ àwọn aláìní ìrírí ni ohun tí yóò pa wọ́n,+ ìdẹra dẹngbẹrẹ àwọn arìndìn sì ni ohun tí yóò pa wọ́n run.+
33 Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò,+ yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”+

