Ìsíkíẹ́lì 8:1-18
8 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹfà, ní oṣù kẹfà, ní ọjọ́ karùn-ún oṣù, pé mo jókòó nínú ilé mi, àwọn àgbà ọkùnrin Júdà sì jókòó níwájú mi,+ nígbà tí ọwọ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wá sára mi níbẹ̀.+
2 Mo sì rí i, sì wò ó! ìrí tí ó jọ ìrísí iná;+ iná wà láti ìrísí ìgbáròkó rẹ̀ àní lọ sísàlẹ̀,+ àti láti ìgbáròkó rẹ̀ àní lọ sókè ni ohun kan wà bí ìrísí ìtànyanran, bí ìpọ́nyòò àyọ́lù wúrà-òun-fàdákà.+
3 Ó sì na àwòrán ọwọ́ jáde,+ ó sì mú mi ní ìdìjọ irun orí mi, ẹ̀mí+ sì gbé mi sáàárín ilẹ̀ ayé àti ọ̀run, ó sì gbé mi wá sí Jerúsálẹ́mù nínú àwọn ìran ti Ọlọ́run,+ wá sí ibi àtiwọ ẹnubodè inú lọ́hùn-ún,+ tí ó dojú kọ ìhà àríwá, níbi tí ibùgbé àmì owú tí ń runilọ́kàn sókè sí owú gbé wà.+
4 Sì wò ó! ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀,+ bí ìrísí tí mo rí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì.
5 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, jọ̀wọ́, gbé ojú rẹ sókè sí ìhà àríwá.” Bẹ́ẹ̀ ni mo gbé ojú mi sókè sí ìhà àríwá, sì wò ó! àmì owú+ yìí wà ní àríwá ẹnubodè pẹpẹ ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé.
6 Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ìwọ ha rí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ńláǹlà tí wọ́n ń ṣe,+ ohun tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe níhìn-ín, kí n lè jìnnà réré sí ibùjọsìn mi?+ Síbẹ̀, ìwọ yóò sì tún rí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ńláǹlà.”
7 Nítorí náà, ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá, mo sì rí i, sì wò ó! ihò kan wà lára ògiri.
8 Wàyí o, ó wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, jọ̀wọ́ dá ògiri náà lu.”+ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo dá ògiri náà lu, sì wò ó! ẹnu ọ̀nà wà.
9 Ó sì wí fún mi síwájú sí i pé: “Wọlé, kí ó sì rí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí búburú tí wọ́n ń ṣe níhìn-ín.”+
10 Bẹ́ẹ̀ ni mo wọlé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí i, sì wò ó! gbogbo àwòrán+ ohun tí ń rákò àti àwọn ẹranko tí ń kóni nírìíra tẹ̀gbintẹ̀gin,+ àti gbogbo òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ ilé Ísírẹ́lì,+ tí àwọn ohun gbígbẹ́ náà wà lára gbogbo ògiri yí ká.
11 Àádọ́rin ọkùnrin+ lára àwọn àgbàlagbà ilé Ísírẹ́lì, pẹ̀lú Jaasánáyà ọmọkùnrin Ṣáfánì+ tí ó dúró láàárín wọn, wọ́n dúró níwájú wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú àwo tùràrí rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, òórùn dídùn tí ó wá láti inú ìṣúdùdù èéfín tùràrí náà ń gòkè lọ.+
12 Ó sì tẹ̀ síwájú láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbàlagbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn,+ olúkúlùkù nínú yàrá inú lọ́hùn-ún ti ohun àfihàn rẹ̀? Nítorí wọ́n ń wí pé, ‘Jèhófà kò rí wa.+ Jèhófà ti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’”
13 Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Síbẹ̀, ìwọ yóò tún rí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ńláǹlà tí wọ́n ń ṣe.”+
14 Nítorí náà, ó mú mi wá sí ibi àtiwọ ẹnubodè ilé Jèhófà, èyí tí ó wà níhà àríwá, sì wò ó! ibẹ̀ ni àwọn obìnrin jókòó sí, wọ́n ń sunkún nítorí ọlọ́run Támúsì.
15 Ó sì wí fún mi síwájú sí i pé: “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí èyí? Síbẹ̀, ìwọ yóò tún rí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ tí ó burú ju ìwọ̀nyí.”
16 Nítorí náà, ó mú mi wá sínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún ní ilé Jèhófà,+ sì wò ó! ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà, láàárín gọ̀bì àti pẹpẹ,+ ni nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n+ wà tí wọ́n kọ ẹ̀yìn sí tẹ́ńpìlì Jèhófà,+ wọ́n sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń tẹrí ba síhà ìlà-oòrùn, fún oòrùn.+
17 Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí èyí? Ó ha jẹ́ ohun kan tí ó fúyẹ́ lójú ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí wọ́n ti ṣe níhìn-ín, tí wọ́n fi fi ìwà ipá+ kún ilẹ̀ yìí tí wọ́n sì tún mú mi bínú, kíyè sí i, tí wọ́n na ọ̀mùnú sí imú mi?
18 Èmi alára pẹ̀lú yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nínú ìhónú.+ Ojú mi kì yóò káàánú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ní ìyọ́nú.+ Dájúdájú, wọn yóò sì fi ohùn rara ké ní etí mi, ṣùgbọ́n èmi kì yóò gbọ́ wọn.”+

