Ìsíkíẹ́lì 47:1-23
47 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi padà wá sí ẹnu ọ̀nà Ilé náà,+ sì wò ó! omi+ ń bẹ tí ń jáde láti abẹ́ ibi àbáwọ Ilé náà níhà ìlà-oòrùn,+ nítorí iwájú Ilé náà wà ní ìlà-oòrùn. Omi náà sì ń sọ̀ kalẹ̀ láti abẹ́, láti ìhà ọ̀tún Ilé náà, ní gúúsù pẹpẹ.
2 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi gba ti ẹnubodè àríwá,+ ó sì mú mi yí ká gba ti òde lọ sí ẹnubodè òde tí ó dojú kọ ìlà-oòrùn,+ sì wò ó! omi+ ń sun láti ìhà ọ̀tún.
3 Nígbà tí ọkùnrin náà jáde lọ síhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn ìdiwọ̀n ní ọwọ́ rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi la omi náà kọjá, omi tí ó ga dé ọrùn ẹsẹ̀.
4 Ó sì ń bá a lọ láti wọn ẹgbẹ̀rún kan, ó sì wá mú mi la omi náà kọjá, omi tí ó ga dé eékún.
Ó sì ń bá a lọ láti wọn ẹgbẹ̀rún kan, ó sì mú mi là á kọjá wàyí—omi tí ó gá dé ìgbáròkó.
5 Ó sì ń bá a lọ láti wọn ẹgbẹ̀rún kan. Ọ̀gbàrá tí èmi kò lè là kọjá ni, nítorí omi náà ti ga sókè, omi tí ó ṣeé lúwẹ̀ẹ́, ọ̀gbàrá tí a kò lè là kọjá.
6 Látàrí ìyẹn, ó wí fún mi pé: “Ìwọ ha ti rí èyí, ọmọ ènìyàn?”
Nígbà náà ni ó mú mi rìn, ó sì mú mi padà sí bèbè ọ̀gbàrá náà.
7 Nígbà tí mo padà, họ́wù, wò ó! ní bèbè ọ̀gbàrá náà ni àwọn igi púpọ̀ gan-an wà, ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún.+
8 Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Omi yìí ń jáde lọ sí ẹkùn ilẹ̀ ìlà-oòrùn, yóò sì sọ̀ kalẹ̀ gba Árábà+ kọjá. Yóò sì lọ sínú òkun.+ Nígbà tí a mú un wọnú òkun,+ omi rẹ̀ ni a mú lára dá ní ti gidi pẹ̀lú.
9 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gbogbo alààyè ọkàn tí ń gbá yìn-ìn,+ níbi gbogbo tí ọ̀gbàrá náà tí ó pọ̀ ní ìlọ́po méjì bá dé, yóò rí ìyè. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹja púpọ̀ gan-an yóò wà, nítorí ibẹ̀ ni omi yìí yóò dé dájúdájú, a ó sì mú omi òkun lára dá,+ ohun gbogbo yóò sì wà láàyè níbi tí ọ̀gbàrá náà bá dé.
10 “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, àwọn apẹja yóò dúró ní ti tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti Ẹ́ń-gédì+ àní títí dé Eni-égíláímù. Ilẹ̀ àgbàlá tí a ń sá àwọ̀n ńlá sí yóò wà. Ẹja wọn yóò pọ̀ gan-an ní onírúurú wọn, bí ẹja Òkun Ńlá.+
11 “Àwọn ibi irà rẹ̀ àti àwọn ibi àbàtà rẹ̀ ń bẹ, a kì yóò sì mú wọn lára dá.+ A ó fi wọ́n fún iyọ̀ dájúdájú.+
12 “Gbogbo onírúurú igi tí ó wà fún oúnjẹ+ yóò sì hù lẹ́bàá ọ̀gbàrá náà, lẹ́bàá bèbè rẹ̀ ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò rọ,+ bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò jẹ èso wọn run.+ Ní oṣù wọn, wọn yóò máa so èso tuntun, nítorí omi wọn—ó ń jáde wá láti ibùjọsìn náà gan-an.+ Èso wọn yóò wà fún oúnjẹ, ewé wọn yóò sì wà fún ìmúniláradá.”+
13 Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Èyí ni ìpínlẹ̀ tí ẹ ó yàn fi ṣe ogún fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá, pẹ̀lú pápá méjì fún Jósẹ́fù.+
14 Ẹ ó sì jogún rẹ̀, olúkúlùkù bákan náà bí arákùnrin rẹ̀, ilẹ̀ tí mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ìbúra+ láti fi fún àwọn baba ńlá yín;+ ilẹ̀ yìí yóò sì tipa kèké bọ́ sọ́wọ́ yín fún ogún.+
15 “Èyí sì ni ààlà ilẹ̀ náà sí ìhà àríwá, láti Òkun Ńlá gba ti Hẹ́tílónì,+ bí ènìyàn bá ti ń bọ̀ ní Sédádì,+
16 Hámátì,+ Bérótà,+ Síbúráímù, tí ó wà láàárín ààlà Damásíkù+ àti ààlà Hámátì; Haseri-hátíkónì, tí ó wà níhà ààlà Háúránì.+
17 Ààlà láti òkun yóò sì jẹ́ Hasari-énónì,+ ààlà Damásíkù àti àríwá—síhà àríwá, àti ààlà Hámátì.+ Èyí ni ìhà àríwá.
18 “Ìhà ìlà-oòrùn sì jẹ́ láti àárín Háúránì+ àti Damásíkù+ àti àárín Gílíádì+ àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì; Jọ́dánì,+ láti ààlà dé òkun ìlà-oòrùn ni kí ẹ wọ̀n. Èyí ni ìhà ìlà-oòrùn.
19 “Ìhà gúúsù sì jẹ́ sí gúúsù, láti Támárì+ dé omi Mẹriba-kádéṣì,+ àfonífojì olójú ọ̀gbàrá+ dé Òkun Ńlá. Èyí ni ìhà tí ó dojú kọ gúúsù, níhà Négébù.
20 “Ìhà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ Òkun Ńlá, láti ààlà ní ọ̀kánkán tààrà dé àtiwọ Hámátì.+ Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.”
21 “Kí ẹ sì pín ilẹ̀ yìí fún ara yín, fún ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì.
22 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, kí ẹ pín in fi ṣe ogún fún ara yín+ àti fún àwọn àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín,+ àwọn tí wọ́n ti bí ọmọ ní àárín yín. Kí wọ́n sì dà bí ọmọ ìbílẹ̀ fún yín láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Pẹ̀lú yín ni wọn yóò ní ogún nípa kèké ní àárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+
23 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nínú ẹ̀yà tí àtìpó kan ti ṣe àtìpó, ibẹ̀ ni kí ẹ ti fún un ní ogún rẹ̀,” ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.

