Ìsíkíẹ́lì 39:1-29
39 “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Gọ́ọ̀gù,+ kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ ọ́, Gọ́ọ̀gù, ìwọ olórí ìjòyè Méṣékì+ àti Túbálì.+
2 Dájúdájú, èmi yóò sì yíjú rẹ padà, èmi yóò sì darí rẹ lọ,+ èmi yóò sì mú kí o wá láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá,+ èmi yóò sì mú ọ wá sórí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì.
3 Ṣe ni èmi yóò gbá ọrun rẹ dànù ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ já bọ́ kúrò ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
4 Orí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì ni ìwọ yóò ṣubú sí,+ ìwọ àti gbogbo àwùjọ ọmọ ogun rẹ àti àwọn ènìyàn tí yóò wà pẹlú rẹ. Dájúdájú, àwọn ẹyẹ aṣọdẹ, àwọn ẹyẹ tí ó ní onírúurú ìyẹ́ apá, àti àwọn ẹranko inú pápá ni èmi yóò fi ọ́ ṣe oúnjẹ fún.”’+
5 “‘Orí pápá ni ìwọ yóò ṣubú sí,+ nítorí èmi tìkára mi ti sọ ọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.
6 “‘Ṣe ni èmi yóò rán iná sí Mágọ́gù+ àti sí àwọn tí ń gbé àwọn erékùṣù ní ààbò;+ àwọn ènìyàn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.
7 Èmi yóò sì sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ ní àárín àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, èmi kì yóò sì jẹ́ kí a sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ mọ́;+ àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ Ẹni Mímọ́ ní Ísírẹ́lì.’+
8 “‘Wò ó! Yóò dé, a ó sì mú kí ó ṣẹlẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. ‘Èyí ni ọjọ́ tí mo ti sọ nípa rẹ̀.+
9 Àwọn olùgbé àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì yóò sì jáde lọ dájúdájú, wọn yóò sì fi iná sun, wọn yóò sì fi ohun ìhámọ́ra àti àwọn asà àti àwọn apata ńlá dá iná,—pẹ̀lú àwọn ọrun àti àwọn ọfà àti àwọn òlùgbóńgbó àti àwọn aṣóró; wọn yóò sì fi wọ́n dá iná+ fún ọdún méje.
10 Wọn kì yóò sì ru igi láti inú pápá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kó igi ìdáná jọ láti inú igbó, nítorí pé àwọn ohun ìhámọ́ra ni wọn yóò máa fi dáná.’
“‘Dájúdájú, wọn yóò sì fi àwọn tí ń fi wọ́n ṣe ìjẹ ṣe ohun ìfiṣèjẹ,+ wọn yóò sì piyẹ́ àwọn tí ń piyẹ́ wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.
11 “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi yóò fi ibì kan níbẹ̀ fún Gọ́ọ̀gù,+ ibi ìsìnkú ní Ísírẹ́lì, àfonífojì àwọn tí ń la ìlà-oòrùn òkun kọjá, yóò sì máa dá àwọn tí ń là á kọjá dúró. Dájúdájú, ibẹ̀ ni wọn yóò sì sin Gọ́ọ̀gù àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ sí, tí ó sì dájú pé wọn yóò pè é ní Àfonífojì Ogunlọ́gọ̀ Gọ́ọ̀gù.+
12 Ṣe ni àwọn ara ilé Ísírẹ́lì yóò sì sin wọ́n fún ète fífọ ilẹ̀ náà mọ́, fún oṣù méje.+
13 Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà yóò sì sin wọ́n, dájúdájú, yóò sì di ọ̀ràn òkìkí fún wọn ní ọjọ́ tí èmi yóò ṣe ara mi lógo,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.
14 “‘Àwọn ènìyàn yóò wà tí a fi sẹ́nu iṣẹ́ nígbà gbogbo, àwọn tí a yà sọ́tọ̀, tí wọn yóò rìn la ilẹ̀ náà já, tí wọn yóò máa sìnkú, pẹ̀lú àwọn tí ń là á kọjá, àwọn tí ó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀, kí a lè fọ̀ ọ́ mọ́. Títí di òpin oṣù méje ni wọn yóò máa ṣe ìwákiri.
15 Àwọn tí ń là á kọjá yóò rìn la ilẹ̀ náà já, bí ẹnì kan bá sì rí egungun ènìyàn ní tòótọ́, òun yóò gbé ohun ìsàmì ró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, títí àwọn tí ń sìnkú yóò fi sin ín sí Àfonífojì Ogunlọ́gọ̀ Gọ́ọ̀gù.+
16 Orúkọ ìlú ńlá náà pẹ̀lú yóò sì jẹ́ Hámónà. Ó dájú pé wọn yóò sì fọ ilẹ̀ náà mọ́.’+
17 “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Sọ fún àwọn ẹyẹ tí ó ní onírúurú ìyẹ́ apá àti fún gbogbo ẹranko inú pápá+ pé: “Ẹ kó ara yín jọpọ̀, kí ẹ sì wá. Ẹ kó ara yín jọpọ̀ yí ẹbọ mi ká, èyí tí èmi yóò ṣe fún yín, ẹbọ ńlá lórí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì.+ Ẹ ó sì jẹ ẹran, ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀+ dájúdájú.
18 Ẹran ara àwọn alágbára ńlá ni ẹ ó jẹ,+ ẹ̀jẹ̀ àwọn ìjòyè ilẹ̀ ayé ni ẹ ó sì mu, àwọn àgbò, àwọn ẹgbọrọ akọ àgùntàn,+ àti àwọn òbúkọ, ẹgbọrọ akọ màlúù,+ ẹran àbọ́pa Báṣánì, gbogbo wọn pátá.+
19 Ó dájú pé ẹ ó jẹ ọ̀rá ní àjẹtẹ́rùn,+ ẹ ó sì mu ẹ̀jẹ̀ ní àmuyó, láti inú ẹbọ mi tí èmi yóò ṣe fún yín.”’
20 “‘A ó sì fi àwọn ẹṣin àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn alágbára ńlá, àti gbogbo onírúurú jagunjagun bọ́ yín yó ní tábìlì mi,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+
21 “‘Dájúdájú, èmi yóò sì gbé ògo mi kalẹ̀ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè; ṣe ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì rí ìdájọ́ mi tí mo ti mú ṣẹ ní kíkún+ àti ọwọ́ mi tí mo ti fi sí àárín wọn.+
22 Àwọn ará ilé Ísírẹ́lì yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn láti ọjọ́ yẹn lọ.+
23 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé nítorí ìṣìnà wọn ni àwọn, ilé Ísírẹ́lì, fi lọ sí ìgbèkùn,+ ní tìtorí òtítọ́ náà pé wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi, tí mo fi fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ tí mo sì fi wọ́n lé àwọn elénìní wọn lọ́wọ́, wọ́n sì ń ṣubú, gbogbo wọn pátá, nípa idà.+
24 Gẹ́gẹ́ bí ìwà àìmọ́ wọn àti gẹ́gẹ́ bí ìrélànàkọjá wọn ni mo ṣe sí wọn,+ mo sì ń pa ojú mi mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.’
25 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ìsinsìnyí ni èmi yóò mú àwọn òǹdè Jékọ́bù padà bọ̀,+ tí èmi yóò sì ṣàánú ní ti tòótọ́ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì;+ ṣe ni èmi yóò fi ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe hàn fún orúkọ mímọ́ mi.+
26 Wọn yóò sì ti ru ìtẹ́lógo wọn+ àti gbogbo àìṣòótọ́ wọn tí wọ́n ṣe sí mi,+ nígbà tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ wọn ní ààbò,+ tí ẹnikẹ́ni kò ní mú wọn wárìrì.+
27 Nígbà tí mo bá mú wọn padà bọ̀ láti inú àwọn ènìyàn, tí èmi sì kó wọn jọpọ̀ ní tòótọ́ láti ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn,+ ṣe ni èmi yóò sọ ara mi di mímọ́ láàárín wọn níwájú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.’+
28 “‘Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, nígbà tí mo bá rán wọn lọ ní ìgbèkùn sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì kó wọn jọpọ̀ ní tòótọ́ sórí ilẹ̀ wọn,+ tí èmi kì yóò sì fi ìkankan nínú wọn sílẹ̀ láti ṣẹ́ kù níbẹ̀.+
29 Èmi kì yóò sì fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ́,+ nítorí èmi yóò da ẹ̀mí mi sórí ilé Ísírẹ́lì+ dájúdájú,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

