Ìsíkíẹ́lì 12:1-28

12  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 2  “Ọmọ ènìyàn, ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ilé+ ni ibi tí ìwọ ń gbé, tí wọ́n ní ojú láti fi ríran ṣùgbọ́n tí wọn kò ríran ní ti gidi,+ tí wọ́n ní etí láti fi gbọ́ràn ṣùgbọ́n tí wọn kò gbọ́ràn ní ti gidi,+ nítorí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé.+ 3  Ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, di ẹrù àdì-lọ-sí ìgbèkùn fún ara rẹ, kí o sì lọ sí ìgbèkùn lójúmọmọ ní ojú wọn, kí o sì lọ sí ìgbèkùn láti ibi tí o wà lọ sí ibòmíràn ní ojú wọn. Bóyá wọn a jẹ́ ríran, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.+ 4  Kí o sì gbé ẹrù àjò rẹ jáde lójú wọn bí ẹrù àdì-lọ-sí ìgbèkùn ní ojúmọmọ, ìwọ alára yóò sì jáde lọ lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí àwọn tí a mú jáde fún ìgbèkùn.+ 5  “Dá ọ̀nà rẹ lu sára ògiri lójú wọn, kí o sì gba inú rẹ̀ kó jáde.+ 6  Ìwọ yóò fi èjìká rù ú lójú wọn. Nígbà òkùnkùn ni ìwọ yóò kó jáde. Ìwọ yóò bo ojú rẹ kí o má bàa rí ilẹ̀, nítorí àmì àgbàyanu+ ni ohun tí mo fi ọ́ ṣe fún ilé Ísírẹ́lì.”+ 7  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún mi.+ Ẹrù àjò mi ni mo gbé jáde, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹrù àdì-lọ-sí ìgbèkùn, ní ojúmọmọ; àti ní ìrọ̀lẹ́ mo fi ọwọ́ dá ọ̀nà mi lu sára ògiri. Nígbà òkùnkùn mo kó jáde. Èjìká mi ni mo fi rù ú, lójú wọn. 8  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá ní òwúrọ̀, pé: 9  “Ọmọ ènìyàn, àwọn ti ilé Ísírẹ́lì, ọlọ̀tẹ̀ ilé,+ kò ha sọ fún ọ pé, ‘Kí ni ìwọ ń ṣe?’ 10  Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ní ti ìjòyè,+ ọ̀rọ̀ ìkéde yìí wà lòdì sí Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí ó wà ní àárín wọn.”’ 11  “Sọ pé, ‘Èmi ni àmì àgbàyanu+ fún yín. Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn. Inú ìgbèkùn, inú oko òǹdè ni wọn yóò lọ.+ 12  Àti ní ti ìjòyè tí ó wà ní àárín wọn, èjìká ni yóò fi rẹrù nínú òkùnkùn, yóò sì jáde lọ; wọn yóò dá ògiri lu, kí wọ́n lè gba inú rẹ̀ kó jáde.+ Òun yóò bo ojú rẹ̀, kí ó má bàa fi ojú ara rẹ̀ rí ilẹ̀.’ 13  Dájúdájú, èmi yóò sì na àwọ̀n mi bò ó, a ó sì mú un nínú àwọ̀n ìṣọdẹ mi;+ èmi yóò sì mú un wá sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ ṣùgbọ́n òun kì yóò rí i; ibẹ̀ ni òun yóò sì kú sí.+ 14  Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká gẹ́gẹ́ bí ìrànlọ́wọ́, àti gbogbo àwùjọ ológun rẹ̀, ni èmi yóò sì tú ká sínú gbogbo ẹ̀fúùfù;+ èmi yóò sí fa idà yọ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.+ 15  Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì tú wọn ká ní ti tòótọ́ sí àwọn ilẹ̀.+ 16  Èmi yóò sì ṣẹ́ àwọn ènìyàn díẹ̀ lára wọn kù kúrò lọ́wọ́ idà,+ kúrò lọ́wọ́ ìyàn, àti kúrò lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn lẹ́sẹẹsẹ nípa gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn yóò wọlé lọ bá;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” 17  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 18  “Ọmọ ènìyàn, pẹ̀lú ìgbọ̀nrìrì ni kí o jẹ oúnjẹ rẹ, pẹ̀lú ṣìbáṣìbo àti àníyàn ṣíṣe sì ni kí o mu omi rẹ.+ 19  Kí o sì wí fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù lórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì:+ “Pẹ̀lú àníyàn ṣíṣe ni wọn yóò fi jẹ oúnjẹ wọn, nínú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni wọn yóò sì mu omi wọn, kí a lè sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀,+ nítorí ìwà ipá gbogbo àwọn tí ń gbé lórí rẹ̀.+ 20  Àwọn ìlú ńlá gbígbé pàápàá ni a ó pa run di ahoro,+ ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro lásán-làsàn;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”+ 21  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ̀ mí wá síwájú sí i, pé: 22  “Ọmọ ènìyàn, ọ̀rọ̀ òwe wo ni ẹ̀yin ní ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ pé, ‘A fa àwọn ọjọ́ gùn,+ gbogbo ìran sì ti ṣègbé’?+ 23  Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Dájúdájú, èmi yóò mú kí ọ̀rọ̀ òwe yìí kásẹ̀ nílẹ̀, wọn kì yóò sì sọ ọ́ bí òwe mọ́ ní Ísírẹ́lì.”’+ Ṣùgbọ́n sọ fún wọn pé, ‘Ọjọ́ sún mọ́lé,+ àti ọ̀ràn gbogbo ìran.’ 24  Nítorí kì yóò sí ìran tí kò ní láárí+ tàbí ìwoṣẹ́ tí ó ní ojú méjì ní àárín ilé Ísírẹ́lì.+ 25  ‘“Nítorí èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò sọ ohun tí èmi yóò sọ, a ó sì ṣe é.+ Kì yóò sí ìsúnsíwájú mọ́ rárá,+ nítorí ní ọjọ́ yín,+ ọlọ̀tẹ̀ ilé, ni èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ kan, tí èmi yóò sì ṣe é dájúdájú,” ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’” 26  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 27  “Ọmọ ènìyàn, wò ó! àwọn ti ilé Ísírẹ́lì ń wí pé, ‘Ìran tí ó ń rí jẹ́ ti ọ̀pọ̀ ọjọ́ níwájú, ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò jíjìnnà réré.’+ 28  Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “‘Kì yóò sí ìsúnsíwájú mọ́ rárá nípa èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ mi.+ Ọ̀rọ tí mo bá sọ, àní òun gan-an ni yóò ṣẹ,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé