Ìsíkíẹ́lì 1:1-28

1  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún ọgbọ̀n, ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ karùn-ún oṣù náà, nígbà tí mo wà ní àárín àwọn ìgbèkùn+ lẹ́bàá Odò Kébárì,+ pé ọ̀run ṣí sílẹ̀,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìran ti Ọlọ́run.+  Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù, èyíinì ni, ní ọdún karùn-ún ìgbèkùn Jèhóákínì Ọba,+  ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ+ Ìsíkíẹ́lì+ ọmọkùnrin Búúsì àlùfáà wá ní pàtó ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà+ lẹ́bàá Odò Kébárì, ọwọ́ Jèhófà sì wà lára rẹ̀ ní ibẹ̀.+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wò, sì kíyè sí i! ẹ̀fúùfù oníjì líle+ kan ń bọ̀ láti àríwá, ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ńláǹlà+ àti iná tí ń gbọ̀n wìrìwìrì,+ ó sì ní ìtànyòò yí ká, láti àárín rẹ̀ wá sì ni ohun kan wà tí ó rí bí àyọ́lù wúrà-òun-fàdákà, láti àárín iná náà wá.+  Láti àárín rẹ̀ wá sì ni ìrí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà,+ bí wọ́n sì ti rí nìyí: wọ́n ní ìrí ará ayé.  Ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ní ojú mẹ́rin,+ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ apá mẹ́rin.+  Ẹsẹ̀ wọn gún régé, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn dà bí àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọ màlúù;+ wọ́n sì ń ràn yòò bí ìpọ́nyòò bàbà dídán.+  Ọwọ́ ènìyàn sì wà lábẹ́ ìyẹ́ apá wọn ní ìhà wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin,+ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní àwọn ojú wọn àti àwọn ìyẹ́ apá wọn.+  Àwọn ìyẹ́ apá wọn so pọ̀ mọ́ra wọn. Wọn kì í yí padà nígbà tí wọ́n bá ń lọ; iwájú tààrà ni olúkúlùkù wọn ń lọ.+ 10  Àti ní ti ìrí ojú wọn, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú ènìyàn+ pẹ̀lú ojú kìnnìún+ ní ìhà ọ̀tún,+ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní ojú akọ màlúù+ ní ìhà òsì;+ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tún ní ojú idì.+ 11  Bí àwọn ojú wọn ti rí nìyẹn. Àwọn ìyẹ́ apá+ wọn sì nà sókè. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní méjì tí ó so pọ̀ mọ́ra, méjì sì bo ara wọn.+ 12  Iwájú tààrà+ ni olúkúlùkù wọn sì ń lọ. Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ ni wọn yóò lọ.+ Wọn kì í yí padà bí wọ́n ti ń lọ.+ 13  Àti ní ti ìrí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ìrísí wọn dà bí ẹyín iná tí ń jó.+ Ohun kan tí ó dà bí ìrísí ògùṣọ̀+ ń lọ síwá-sẹ́yìn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè náà, iná náà sì mọ́lẹ̀ yòò, mànàmáná sì ń jáde wá láti inú iná náà.+ 14  Ní tiwọn, àwọn ẹ̀dá alààyè náà ń lọ, wọn sì ń bọ̀ bí ìrísí mànàmáná.+ 15  Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà,+ họ́wù, kíyè sí i! àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà lórí ilẹ̀ ayé lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti ọ̀kọ̀ọ̀kan.+ 16  Ní ti ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà+ àti ìgbékalẹ̀ wọn, ó dà bí ìpọ́nyòò kírísóláítì;+ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìrí kan náà. Ìrísí wọn àti ìgbékalẹ̀ wọn rí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ bá wà ní àárín àgbá kẹ̀kẹ́.+ 17  Nígbà tí wọ́n bá ń lọ, wọ́n a máa fi ìhà wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ.+ Wọn kì í yí padà gba ọ̀nà mìíràn nígbà tí wọ́n bá ń lọ.+ 18  Ní ti àwọn ríìmù wọn, wọ́n ga tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń fa ìbẹ̀rù; àwọn ríìmù wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kún fún ojú yí ká.+ 19  Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náá yóò máa lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, nígbà tí a bá sì gbé àwọn ẹ̀dá alààyè náà sókè kúrò lórí ilẹ̀ ayé, a óò gbé àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà sókè.+ 20  Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ, ni wọn ń lọ, ibẹ̀ ni ẹ̀mí fẹ́ lọ; àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà fúnra wọn a sì gbéra sókè lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn pẹ́kípẹ́kí, nítorí ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè náà ń bẹ nínú àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà. 21  Nígbà tí wọ́n bá lọ, àwọn wọ̀nyí a lọ; nígbà tí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́, àwọn wọ̀nyí a dúró jẹ́ẹ́; nígbà tí a bá sì gbé wọn sókè kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ni a óò gbé sókè lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn pẹ́kípẹ́kí, nítorí ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè náà ń bẹ nínú àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà.+ 22  Lókè orí àwọn ẹ̀dá alààyè náà sì ni ìrí bí òfuurufú+ wà tí ó dà bí ìtànyinrin omi dídì tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, tí ó nà kọjá lórí wọn.+ 23  Ìyẹ́ apá wọn sì gún régé lábẹ́ òfuurufú náà, ọ̀kan mọ́ èkejì. Olúkúlùkù ní ìyẹ́ apá méjì tí ó bo ìhà ìhín, olúkúlùkù sì ní méjì tí ó bo ìhà ọ̀hún ara wọn. 24  Mo sì gbọ́ ìró ìyẹ́ apá wọn, nígbà tí wọ́n lọ, ìró tí ó dà bí alagbalúgbú omi,+ bí ìró Olódùmarè, ìró ìrúkèrúdò,+ bí ìró ìdótini.+ Nígbà tí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́, wọn yóò ká ìyẹ́ apá wọn sílẹ̀. 25  Ohùn kan sì wá láti òkè òfuurufú tí ó wà lókè orí wọn. (Nígbà tí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́, wọn yóò ká ìyẹ́ apá wọn sílẹ̀.) 26  Lókè òfuurufú tí ó wà lókè orí wọn sì ni ohun kan wà tí ó ní ìrísí tí ó dà bí òkúta sàfáyà,+ ó rí bí ìtẹ́.+ Lórí ohun tí ó rí bí ìtẹ́ náà ni ìrí ẹnì kan wà tí ó ní ìrísí tí ó dà bí ti ará ayé,+ lókè. 27  Mo sì rí ohun kan tí ó dà bí ìpọ́nyòò àyọ́lù wúrà-òun-fàdákà,+ bí ìrísí iná yí ká nínú rẹ̀,+ láti ìrísí ìgbáròkó rẹ̀ sókè; àti láti ìrísí ìgbáròkó rẹ̀ sísàlẹ̀, mo rí ohun kan tí ó dà bí ìrísí iná, ó sì ní ìtànyòò yí ká. 28  Ohun kan wà tí ìrísí rẹ̀ dà bí ti òṣùmàrè+ tí ó lé sí ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ní ọjọ́ ọ̀yamùúmùú òjò. Bí ìrísí ìtànyòò náà ti rí nìyẹn yíká-yíká. Ìrísí ti ìrí ògo Jèhófà ni.+ Nígbà tí mo rí i, nígbà náà ni mo dojú bolẹ̀,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn ẹni tí ń sọ̀rọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé