Ìdárò 5:1-22
5 Rántí, Jèhófà, ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa.+ Wò, kí o sì rí ẹ̀gàn wa.+
2 Ohun ìní àjogúnbá wa ni a ti fi lé àwọn àjèjì lọ́wọ́, àwọn ilé wa ni a ti fi fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.+
3 A ti di ọmọ òrukàn gbáà láìní baba.+ Àwọn ìyá wa dà bí opó.+
4 Owó ni a ń san kí a tó lè rí omi mu.+ Ó níye tí a ń san kí igi tó wọlé fún wa.
5 A ti lépa wa fẹ́rẹ̀ẹ́ kan ọrùn.+ Agara ti dá wa. Ìsinmi kò sí fún wa rárá.+
6 A ti nawọ́+ sí Íjíbítì;+ sí Ásíríà,+ kí a lè jẹ oúnjẹ ní àjẹyó.
7 Àwọn baba ńlá wa ni ó dẹ́ṣẹ̀.+ Wọn kò sí mọ́. Ní tiwa, ìṣìnà wọn ni ó di dandan fún wa láti rù.+
8 Àwọn ìránṣẹ́ lásán-làsàn ti ṣàkóso lé wa lórí.+ Kò sí ẹni tí ń já wa gbà kúrò ní ọwọ́ wọn.+
9 Ní fífi ọkàn wa wewu ni a ń mú oúnjẹ wa wọlé,+ nítorí idà aginjù.
10 Awọ ara wa pàápàá ti gbóná bí ìléru, nítorí ìroragógó ebi.+
11 Àwọn aya tí ń bẹ ní Síónì ni wọ́n ti rẹ̀ sílẹ̀,+ àwọn wúńdíá tí ń bẹ ní ìlú ńlá Júdà.
12 Àwọn ọmọ aládé pàápàá ni a ti so rọ̀ nípasẹ̀ kìkì ọwọ́ wọn.+ Àní ojú àwọn arúgbó ni a kò bọlá fún.+
13 Àní àwọn ọ̀dọ́kùnrin ti gbé ọlọ ọlọ́wọ́ pàápàá sókè,+ àwọn ọmọdékùnrin pàápàá sì ti kọsẹ̀ lábẹ́ igi.+
14 Àwọn àgbààgbà alára ti kásẹ̀ nílẹ̀ àní ní ẹnubodè,+ àwọn ọ̀dọ́kùnrin ti ṣíwọ́ lẹ́nu orin tí a fi ohun èlò orin kọ.+
15 Ayọ̀ ńláǹlà ọkàn-àyà wa ti kásẹ̀ nílẹ̀. Ijó wa ni a ti sọ di kìkìdá ọ̀fọ̀.+
16 Adé orí wa ti já bọ́.+ A gbé wàyí, nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀!+
17 Ní tìtorí èyí, ọkàn-àyà wa ń ṣàmódi.+ Ní tìtorí nǹkan wọ̀nyí, ojú wa ti di bàìbàì,+
18 Ní tìtorí òkè ńlá Síónì tí ó di ahoro;+ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pàápàá ti rìn lórí rẹ̀.+
19 Ní tìrẹ, Jèhófà, fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ìwọ yóò jókòó.+ Ìtẹ́ rẹ jẹ́ láti ìran dé ìran.+
20 Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé títí láé ni o gbàgbé wa,+ tí o sì fi wa sílẹ̀ fún ọjọ́ gígùn?+
21 Mú wa padà,+ Jèhófà, sọ́dọ̀ ara rẹ, wéréwéré ni àwa yóò sì padà wá. Mú ọjọ́ tuntun wá fún wa bí ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.+
22 Bí ó ti wù kí ó rí, ṣe ni o kọ̀ wá sílẹ̀.+ Ìkannú rẹ ti ru sí wa gidigidi.+