Ìṣe 28:1-31
28 Nígbà tí a sì ti gúnlẹ̀ ní àlàáfíà, nígbà náà ni a gbọ́ pé Málítà+ ni a ń pe erékùṣù náà.
2 Àwọn ènìyàn elédè ilẹ̀ òkèèrè náà sì fi àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn+ hàn sí wa, nítorí wọ́n dá iná, wọ́n sì gba gbogbo wa pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ nítorí òjò tí ń rọ̀ àti nítorí òtútù.+
3 Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù kó ìdì igi jọ, tí ó sì kó o sórí iná, paramọ́lẹ̀ kan jáde wá nítorí ooru, ó sì wé ara rẹ̀ mọ́ ọn lọ́wọ́.
4 Nígbà tí àwọn ènìyàn elédè ilẹ̀ òkèèrè náà tajú kán rí ẹ̀dá olóró tí ó rọ̀ dìrọ̀dìrọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Dájúdájú, òṣìkàpànìyàn ni ọkùnrin yìí, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ó gúnlẹ̀ ní àlàáfíà láti inú òkun, ìdájọ́ ẹ̀san kò gbà á láyè láti máa wà láàyè nìṣó.”
5 Àmọ́ ṣá o, ó gbọn ẹ̀dá olóró náà dànù sínú iná, kò sì ní ìpalára kankan.+
6 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fojú sọ́nà pé wíwú ni ara rẹ̀ yóò wú bèǹbè tàbí kí ó ṣubú lulẹ̀ kú lójijì. Lẹ́yìn tí wọ́n dúró fún àkókò gígùn, tí wọ́n sì rí i pé ọṣẹ́ kankan kò ṣe é, wọ́n yí èrò inú wọn padà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọlọ́run kan ni.+
7 Wàyí o, ní àdúgbò ibẹ̀, ọkùnrin sàràkí erékùṣù náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Púbílọ́sì, ní àwọn ilẹ̀; ó sì gbà wá pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, ó sì ṣe wá lálejò pẹ̀lú ẹ̀mí ìṣoore fún ọjọ́ mẹ́ta.
8 Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ pé baba Púbílọ́sì dùbúlẹ̀, tí ibà àti ìgbẹ́ ọ̀rìn ń yọ ọ́ lẹ́nu, Pọ́ọ̀lù sì wọlé lọ bá a, ó sì gbàdúrà, ó gbé ọwọ́+ lé e, ó sì mú un lára dá.+
9 Lẹ́yìn tí èyí ṣẹlẹ̀, ìyókù àwọn ènìyàn erékùṣù náà tí wọ́n ní àwọn àìsàn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wò wọ́n sàn.+
10 Wọ́n sì fi ẹ̀bùn púpọ̀ bọlá fún wa pẹ̀lú àti pé, nígbà tí a ń ṣíkọ̀, wọ́n di ẹrù àwọn nǹkan fún wa fún àìní wa.
11 Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, a ṣíkọ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi kan tí ó wá láti Alẹkisáńdíríà,+ tí ó ti lo ìgbà òtútù ní erékùṣù náà, tí ó sì ní ère orí ọkọ̀ “Àwọn Ọmọkùnrin Súúsì.”
12 Àti pé ní gígúnlẹ̀ sí èbúté ọkọ̀ ní Sírákúsì, a dúró fún ọjọ́ mẹ́ta,
13 láti ibi tí a ti lọ yí po, tí a sì dé Régíómù. Ọjọ́ kan lẹ́yìn náà, ẹ̀fúùfù gúúsù kan bẹ̀rẹ̀, a sì dé Pútéólì ní ọjọ́ kejì.
14 Níhìn-ín ni a ti rí àwọn ará, wọ́n sì pàrọwà fún wa láti wà pẹ̀lú wọn fún ọjọ́ méje; báyìí sì ni a ṣe wá síhà Róòmù.
15 Nígbà tí àwọn ará sì gbọ́ ìròyìn nípa wa, wọ́n wá láti ibẹ̀ láti wá pàdé wa ní ibi tí ó jìnnà dé Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta, bí Pọ́ọ̀lù sì ti tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.+
16 Nígbà tí a wọ Róòmù nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a gba Pọ́ọ̀lù láyè+ láti wà ní òun nìkan pẹ̀lú ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ́.
17 Bí ó ti wù kí ó rí, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó pe àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù. Nígbà tí wọ́n ti péjọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ṣe nǹkan kan tí ó lòdì sí àwọn ènìyàn tàbí àwọn àṣà àwọn baba ńlá wa,+ a fà mí lé àwọn ará Róòmù+ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n láti Jerúsálẹ́mù.
18 Lẹ́yìn tí àwọn wọ̀nyí sì ṣe àyẹ̀wò,+ wọ́n fẹ́ láti tú mi sílẹ̀,+ níwọ̀n bí kò ti sí ìdí kankan fún ikú+ nínú mi.
19 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i ṣáá, ó di ọ̀ranyàn fún mi láti ké gbàjarè+ sí Késárì, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ẹni pé mo ní ohunkóhun láti fẹ̀sùn kan orílẹ̀-èdè mi lé lórí.
20 Ní ti gidi, ní tìtorí èyí ni mo ṣe pàrọwà láti rí àti láti bá yín sọ̀rọ̀, nítorí pé tìtorí ìrètí+ Ísírẹ́lì ni ẹ̀wọ̀n yìí ṣe wà yí mi ká.”+
21 Wọ́n wí fún un pé: “Àwa kò gba àwọn lẹ́tà nípa rẹ láti Jùdíà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni lára àwọn ará tí ó ti dé kò ròyìn tàbí kí wọ́n sọ ohun burúkú kankan nípa rẹ.
22 Ṣùgbọ́n àwa ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti gbọ́ láti ẹnu rẹ ohun tí àwọn ìrònú rẹ jẹ́, nítorí pé lóòótọ́, ní ti ẹ̀ya ìsìn+ yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”+
23 Wàyí o, wọ́n ṣètò ọjọ́ kan pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní iye púpọ̀ ní ibùwọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn nípa jíjẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run+ àti nípa lílo ìyíniléròpadà pẹ̀lú wọn nípa Jésù láti inú òfin Mósè+ àti àwọn Wòlíì,+ láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.
24 Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ohun tí ó sọ gbọ́;+ àwọn mìíràn kò sì gbà gbọ́.+
25 Nítorí náà, nítorí pé wọ́n wà ní àìfohùnṣọ̀kan pẹ̀lú ara wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ, bí Pọ́ọ̀lù ti sọ ọ̀rọ̀ àkíyèsí kan yìí pé:
“Ẹ̀mí mímọ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì fún àwọn baba ńlá yín,
26 pé, ‘Lọ bá àwọn ènìyàn yìí, kí o sì wí pé: “Ní gbígbọ́, ẹ óò gbọ́ ṣùgbọ́n ẹ kì yóò lóye lọ́nàkọnà; àti pé, ní wíwò, ẹ ó wò ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí lọ́nàkọnà.+
27 Nítorí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí láé, kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́, kí wọ́n sì fi ọkàn-àyà wọn lóye, kí wọ́n sì yí padà, kí n sì mú wọn lára dá.”’+
28 Nítorí náà, kí ó di mímọ̀ fún yín pé èyí, ohun àmúlò tí Ọlọ́run fi ń gbani là, ni a ti rán jáde sí àwọn orílẹ̀-èdè;+ wọn yóò fetí sí i dájúdájú.”+
29 ——
30 Nítorí náà, ó dúró fún ọdún méjì gbáko nínú ilé tí òun fúnra rẹ̀ háyà,+ òun a sì fi inú rere gba gbogbo àwọn tí wọ́n wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀,
31 ní wíwàásù ìjọba Ọlọ́run fún wọn àti kíkọ́ni ní àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ+ ńláǹlà, láìsí ìdílọ́wọ́.

