Ìṣe 2:1-47
2 Wàyí o, bí ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì+ ti ń lọ lọ́wọ́, gbogbo wọ́n wà pa pọ̀ ní ibì kan náà,
2 lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí.+
3 Àwọn ahọ́n bí ti iná+ sì di rírí fún wọn, ó sì pín káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn,
4 gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.
5 Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, àwọn Júù wà tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù,+ àwọn ènìyàn tí ó ní ìfọkànsìn,+ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.
6 Nítorí náà, nígbà tí ìró yìí dún, ògìdìgbó náà kóra jọpọ̀, ìdàrúdàpọ̀-ọkàn sì bá wọn, nítorí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè tòun.
7 Ní tòótọ́, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì, wọ́n sì wí pé: “Ẹ wò ó, gbogbo àwọn wọ̀nyí tí ń sọ̀rọ̀ jẹ́ ará Gálílì,+ àbí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Síbẹ̀, báwo ni ó ṣe jẹ́ tí olúkúlùkù wa ń gbọ́ èdè tirẹ̀ nínú èyí tí a bí wa sí?
9 Àwọn ará Pátíà àti àwọn ará Mídíà+ àti àwọn ọmọ Élámù,+ àti àwọn olùgbé Mesopotámíà, àti Jùdíà+ àti Kapadókíà,+ àti Pọ́ńtù+ àti àgbègbè Éṣíà,+
10 àti Fíríjíà+ àti Panfílíà,+ Íjíbítì àti àwọn apá Líbíà, èyí tí ń bẹ níhà Kírénè, àti àwọn olùṣàtìpó láti Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe,+
11 àwọn ará Kírétè+ àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà,+ àwa gbọ́ wọn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n wa nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.”
12 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnu ya gbogbo wọn, ọkàn wọ́n sì dàrú, wọ́n ń sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Kí ni ìtúmọ̀ tí èyí gbé yọ?”
13 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹlòmíràn fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Wọ́n ti mu wáìnì dídùn yó.”+
14 Ṣùgbọ́n Pétérù dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá náà,+ ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde fún wọn pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Jùdíà àti gbogbo ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù,+ kí èyí di mímọ̀ fún yín, kí ẹ sì fi etí sí àwọn àsọjáde mi.
15 Ní ti tòótọ́, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò mutí para,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rò, nítorí pé wákàtí kẹta ọjọ́ ni.
16 Kàkà bẹ́ẹ̀, èyí ni ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì pé,
17 ‘“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Ọlọ́run wí, “èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí+ mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò sì máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá;+
18 ṣe ni èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní ọjọ́ wọnnì, wọn yóò sì sọ tẹ́lẹ̀.+
19 Ṣe ni èmi yóò fúnni ní àwọn àmì àgbàyanu ní ọ̀run lókè àti àwọn iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti iná àti ìkùukùu èéfín;+
20 a óò yí oòrùn+ padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí ti Jèhófà tó dé.+
21 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”’+
22 “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Jésù ará Násárétì,+ ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn ní gbangba fún yín nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára+ àti àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀,
23 ọkùnrin yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fà léni lọ́wọ́ nípasẹ̀ ète tí a ti pa àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run,+ ni ẹ ti ọwọ́ àwọn ènìyàn aláìlófin kàn gbọn-in gbọn-in mọ́ òpó igi, tí ẹ sì pa.+
24 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde+ nípa títú àwọn ìroragógó ikú,+ nítorí kò ṣeé ṣe pé kí ó máa bá a lọ láti dì í mú ṣinṣin.+
25 Nítorí Dáfídì sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo ní Jèhófà níwájú mi nígbà gbogbo; nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, kí a má bàa mì mí láé.+
26 Ní tìtorí èyí, ọkàn-àyà mi yá gágá, ahọ́n mi sì yọ̀ gidigidi. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹran ara mi pàápàá yóò máa gbé ní ìrètí;+
27 nítorí ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.+
28 Ìwọ ti sọ àwọn ọ̀nà ìyè di mímọ̀ fún mi, ìwọ yóò fi ìmóríyá gágá kún inú mi ní ojú rẹ.’+
29 “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, a yọ̀ǹda fúnni láti bá yín sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ nípa olórí ìdílé náà Dáfídì, pé ó di olóògbé,+ a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì wà láàárín wa títí di òní.
30 Nítorí náà, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì, tí ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run ti fi ìbúra kan búra fún un pé òun yóò mú ẹnì kan láti inú èso abẹ́nú rẹ̀ jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+
31 ó ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò ṣá a tì sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.+
32 Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde, òtítọ́ tí gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún.+
33 Nítorí náà, nítorí pé a gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ tí ó sì gba ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Baba,+ ó tú èyí tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ jáde.
34 Ní ti gidi, Dáfídì kò gòkè lọ sí ọ̀run,+ ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,+
35 títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.”’+
36 Nítorí náà, kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi+ ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa+ àti Kristi.”
37 Wàyí o, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ó gún wọn dé ọkàn-àyà,+ wọ́n sì wí fún Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, kí ni kí àwa ṣe?”+
38 Pétérù wí fún wọn pé: “Ẹ ronú pìwà dà,+ kí a sì batisí+ olúkúlùkù yín ní orúkọ+ Jésù Kristi fún ìdáríjì+ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ ẹ̀mí mímọ́.
39 Nítorí ìlérí+ náà jẹ́ fún ẹ̀yin àti fún àwọn ọmọ yín àti fún gbogbo àwọn tí ń bẹ lókèèrè réré,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá pè wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ti lè pọ̀ tó.”+
40 Ó sì fi ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn jẹ́rìí kúnnákúnná, ó sì ń gbà wọ́n níyànjú ṣáá, pé: “Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí.”+
41 Nítorí náà, àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a batisí,+ ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn ni a sì fi kún wọn.+
42 Wọ́n sì ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì àti ṣíṣe àjọpín pẹ̀lú ara wọn,+ nínú jíjẹ oúnjẹ+ àti nínú àdúrà.+
43 Ní tòótọ́, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba olúkúlùkù ọkàn, ọ̀pọ̀ àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+
44 Gbogbo àwọn tí wọ́n di onígbàgbọ́ wà pa pọ̀ ní níní ohun gbogbo ní àpapọ̀,+
45 wọ́n sì ń ta àwọn ohun ìní+ àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó ohun tí a tà fún gbogbo wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní olúkúlùkù bá ṣe rí.+
46 Láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n sì ń pésẹ̀ nígbà gbogbo sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan,+ wọ́n sì ń jẹ oúnjẹ wọn nínú àwọn ilé àdáni, wọ́n sì ń ṣalábàápín oúnjẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà+ àti òtítọ́ ọkàn-àyà,
47 wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn.+ Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí a ń gbà là+ dara pọ̀+ mọ́ wọn lójoojúmọ́.

