Ìṣe 19:1-41

19  Bí àwọn nǹkan ti ń ṣẹlẹ̀, nígbà tí Àpólò+ wà ní Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ibi tí ilẹ̀ tí jìnnà sí òkun kọjá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ wá sí Éfésù,+ ó sì rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan;  ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ ha gba ẹ̀mí mímọ́+ nígbà tí ẹ di onígbàgbọ́ bí?” Wọ́n wí fún un pé: “Họ́wù, a kò tíì gbọ́ rí bóyá ẹ̀mí mímọ́+ kan wà.”  Ó sì wí pé: “Nínú kí wá ni a batisí yín?” Wọ́n wí pé: “Nínú ìbatisí Jòhánù ni.”+  Pọ́ọ̀lù wí pé: “Jòhánù batisí pẹ̀lú ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà,+ ó ń sọ fún àwọn ènìyàn pé kí wọ́n gbà gbọ́ nínú ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun,+ èyíinì ni, nínú Jésù.”  Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, a batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa.+  Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì gbé ọwọ́+ lé wọn, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń sọ tẹ́lẹ̀.+  Lápapọ̀, wọ́n jẹ́ nǹkan bí ọkùnrin méjìlá.  Ní wíwọ sínágọ́gù,+ ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo fún oṣù mẹ́ta, ó ń sọ àsọyé, ó sì ń lo ìyíniléròpadà nípa ìjọba+ Ọlọ́run.  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn kan ń sọ ara wọn di aláyà líle, tí wọn kò sì gbà gbọ́,+ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lọ́nà ìbàjẹ́ nípa Ọ̀nà Náà+ níwájú ògìdìgbó náà, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ ó sì ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ ó ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ Tíránù. 10  Èyí ṣẹlẹ̀ fún ọdún méjì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé àgbègbè Éṣíà+ fi gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì. 11  Ọlọ́run sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn àrà ọ̀tọ̀ iṣẹ́ agbára láti ọwọ́ Pọ́ọ̀lù,+ 12  tí ó fi jẹ́ pé àwọn aṣọ àti épírọ́ọ̀nù pàápàá ni a mú láti ara rẹ̀ tọ àwọn ènìyàn tí ń ṣòjòjò lọ,+ òkùnrùn wọnnì a sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí burúkú náà a sì jáde.+ 13  Ṣùgbọ́n àwọn kan lára àwọn Júù alárìnkiri tí ń fi lílé àwọn ẹ̀mí èṣù+ jáde ṣiṣẹ́ ṣe pẹ̀lú dáwọ́ lé pípe orúkọ Jésù Olúwa+ sórí àwọn tí ó ní àwọn ẹ̀mí burúkú, wí pé: “Mo pàṣẹ fún yín lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀+ nípasẹ̀ Jésù ẹni tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù.” 14  Wàyí o, àwọn ọmọkùnrin méje wà tí ń ṣe èyí, tí wọ́n jẹ́ ti Síkéfà kan báyìí, tí í ṣe olórí àlùfáà àwọn Júù. 15  Ṣùgbọ́n ní ìdáhùn, ẹ̀mí burúkú náà wí fún wọn pé: “Mo mọ Jésù,+ mo sì mọ Pọ́ọ̀lù;+ ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?” 16  Pẹ̀lú ìyẹn, ọkùnrin tí ẹ̀mí burúkú náà wà nínú rẹ̀ bẹ́ mọ́ wọn,+ ó kápá ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn, ó sì borí wọn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá lọ kúrò ní ilé yẹn ní ìhòòhò àti pẹ̀lú ọgbẹ́ lára. 17  Èyí di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì tí ń gbé ní Éfésù; ẹ̀rù+ sì ba gbogbo wọn, orúkọ Jésù Olúwa sì ń bá a lọ ní dídi èyí tí a gbé ga lọ́lá.+ 18  Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n di onígbàgbọ́ a sì wá, wọn a sì jẹ́wọ́,+ wọn a sì ròyìn àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe ní gbangba. 19  Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán+ pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣe àròpọ̀ iye owó wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹyọ fàdákà. 20  Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí+ lọ́nà tí ó ní agbára ńlá. 21  Wàyí o, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí ti parí, Pọ́ọ̀lù pète nínú ẹ̀mí rẹ̀ pé, lẹ́yìn líla Makedóníà+ àti Ákáyà já, òun yóò rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù,+ ó wí pé: “Lẹ́yìn tí mo bá dé ibẹ̀, mo gbọ́dọ̀ rí Róòmù pẹ̀lú.”+ 22  Nítorí náà, ó rán Tímótì+ àti Érásítù,+ méjì lára àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, lọ sí Makedóníà, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ dúró fún àkókò díẹ̀ ní àgbègbè Éṣíà. 23  Ní àkókò yẹn gan-an, ìyọlẹ́nu+ tí kò kéré dìde nípa Ọ̀nà Náà.+ 24  Nítorí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, ń mú èrè+ tí kò kéré wá fún àwọn oníṣẹ́ ọnà nípa ṣíṣe àwọn ojúbọ fàdákà Átẹ́mísì; 25  ó sì kó wọn jọ àti àwọn tí ń fi irúfẹ́ àwọn ohun bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ ṣe,+ ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ mọ̀ dunjú pé inú iṣẹ́ òwò yìí ni a ti ní aásìkí wa.+ 26  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ rí, ẹ sì gbọ́, kì í ṣe ní Éfésù+ nìkan, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo àgbègbè Éṣíà, bí Pọ́ọ̀lù yìí ti yí ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ lérò padà, tí ó sì ti yí wọn padà sí èrò mìíràn, tí ó ń wí pé àwọn èyí tí a fi ọwọ́+ ṣe kì í ṣe ọlọ́run. 27  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ewu ń bẹ, kì í ṣe kìkì pé iṣẹ́ àjókòótì tiwa yìí yóò wá di aláìníyì nìkan ni, ṣùgbọ́n pé tẹ́ńpìlì ńlá ti abo ọlọ́run Átẹ́mísì+ pẹ̀lú ni a ó kà sí asán àti pé ọlá ńlá rẹ̀ pàápàá, èyí tí gbogbo àgbègbè Éṣíà àti ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ń jọ́sìn ni a máa tó sọ di asán.” 28  Ní gbígbọ́ èyí àti ní kíkún fún ìbínú, àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde, pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù!” 29  Nítorí náà, ìlú ńlá náà kún fún ìdàrúdàpọ̀, pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n rọ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran náà, wọ́n fi tipátipá mú Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì,+ àwọn ará Makedóníà, alájọrin ìrìn àjò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, lọ pẹ̀lú wọn. 30  Ní tirẹ̀, Pọ́ọ̀lù fẹ́ wọlé lọ bá àwọn ènìyàn náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò gbà á láyè. 31  Kódà, àwọn kan lára kọmíṣọ́nnà àwọn àjọyọ̀ àti eré, tí wọ́n lẹ́mìí ọ̀rẹ́ sí i, ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó má fi ara rẹ̀ wewu nínú gbọ̀ngàn ìwòran náà. 32  Òtítọ́ náà ni pé, àwọn kan ń ké ohun kan jáde, àwọn mìíràn sì ń ke ohun mìíràn;+ nítorí àpéjọ náà wà nínú ìdàrúdàpọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn kò sì mọ ìdí tí wọ́n fi kóra jọpọ̀. 33  Nítorí náà, wọ́n jùmọ̀ mú Alẹkisáńdà jáde kúrò nínú ogunlọ́gọ̀ náà, àwọn Júù ń sọ́gọ rẹ̀ síwájú; Alẹkisáńdà sì ju ọwọ́ rẹ̀, ó sì ń fẹ́ láti rojọ́ ní ìgbèjà ara rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn náà. 34  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ dájú pé Júù ni, igbe kan ta láti ọ̀dọ̀ gbogbo wọn bí wọ́n ti kígbe fún nǹkan bí wákàtí méjì pé: “Títóbi+ ni Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù!” 35  Ní ìkẹyìn, nígbà tí akọ̀wé ìlú ńlá náà ti mú ogunlọ́gọ̀ náà dákẹ́,+ ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Éfésù, nínú aráyé, ta ni ó wà tí kò mọ̀ ní ti gidi pé ìlú ńlá àwọn ará Éfésù ni olùpa tẹ́ńpìlì mọ́ fún Átẹ́mísì ńlá àti fún ère tí ó jábọ́ láti ọ̀run? 36  Nítorí náà, níwọ̀n bí nǹkan wọ̀nyí ti jẹ́ aláìṣeé ṣe awuyewuye lé lórí, ó yẹ kí ẹ sinmẹ̀dọ̀, kí ẹ má sì fi ìwàǹwára gbé ìgbésẹ̀.+ 37  Nítorí ẹ ti mú ọkunrin wọ̀nyí wá, tí wọn kì í ṣe ọlọ́ṣà tẹ́ńpìlì tàbí asọ̀rọ̀ òdì sí abo ọlọ́run wa. 38  Nítorí náà, bí Dímẹ́tíríù+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ bá ní ẹjọ́ lòdì sí ẹnì kan, àwọn ọjọ́ kóòtù+ wà, àwọn alákòósò ìbílẹ̀+ sì wà; ẹ jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹ̀sùn wá lòdì sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. 39  Àmọ́ ṣá o, bí ẹ bá ń wá ohunkóhun ré kọjá ìyẹn, àpéjọ tí ó bòfin mu ni a ti gbọ́dọ̀ pinnu rẹ̀. 40  Nítorí ní ti gidi, àwa wà nínú ewu dídi ẹni tí a fi sùn fún ìdìtẹ̀ sí ìjọba lórí àlámọ̀rí òní, kò sí ohun kan ṣoṣo tí ó wà tí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti pèsè ìdí fún àwùjọ onídàrúdàpọ̀ yìí.” 41  Nígbà tí ó sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí,+ ó tú àpéjọ náà ká.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé