Ìṣe 13:1-52
13 Wàyí o, ní Áńtíókù, àwọn wòlíì+ àti àwọn olùkọ́ wà nínú ìjọ àdúgbò, Bánábà àti Símíónì tí a ń pè ní Nígérì, àti Lúkíọ́sì+ ará Kírénè, àti Mánáénì ẹni tí ó gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú Hẹ́rọ́dù olùṣàkóso àgbègbè náà, àti Sọ́ọ̀lù.
2 Bí wọ́n ti ń ṣèránṣẹ́+ fún Jèhófà ní gbangba, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ wí pé: “Nínú gbogbo ènìyàn, ẹ ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù+ sọ́tọ̀ gedegbe fún mi fún iṣẹ́ tí mo pè wọ́n sí.”
3 Nígbà náà ni wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́+ lé wọn, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ.
4 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, tí ẹ̀mí mímọ́ rán jáde, sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà, wọ́n sì ṣíkọ̀ láti ibẹ̀ lọ sí Kípírù.
5 Nígbà tí wọ́n sì wà ní Sálámísì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù+ pẹ̀lú wà lọ́dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà.
6 Nígbà tí wọ́n ti la gbogbo erékùṣù náà já títí dé Páfò, wọ́n bá ọkùnrin kan pàdé, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ oṣó, wòlíì èké,+ Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baa-Jésù,
7 ó sì wà pẹ̀lú alákòóso ìbílẹ̀ náà Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, ọkùnrin onílàákàyè. Ní pípe Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́dọ̀ ara rẹ̀, [ọkùnrin] yìí fi taratara wá ọ̀nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
8 Ṣùgbọ́n Élímà oníṣẹ́ oṣó náà (èyíinì, ní ti tòótọ́, ni ọ̀nà tí a gbà túmọ̀ orúkọ rẹ̀) bẹ̀rẹ̀ sí takò wọ́n,+ ó ń wá ọ̀nà láti yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ìgbàgbọ́.
9 Bí Sọ́ọ̀lù, ẹni tí ó tún ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù, ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọn,
10 ó sì wí pé: “Ìwọ ọkùnrin tí ó kún fún gbogbo onírúurú jìbìtì àti gbogbo onírúurú ìwà aṣa, ìwọ ọmọ Èṣù,+ ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo tí ó jẹ́ òdodo, ṣé ìwọ kò ní ṣíwọ́ fífi èrú yí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà po ni?
11 Tóò, nígbà náà, wò ó! ọwọ́ Jèhófà ń bẹ lára rẹ, ìwọ yóò sì fọ́jú, láìrí ìmọ́lẹ̀ oòrùn fún sáà àkókò kan.” Ní ìṣẹ́jú akàn, ìkùukùu ṣíṣúdùdù àti òkùnkùn ṣú bò ó, ó sì lọ yí ká, ó ń wá àwọn ènìyàn láti mú òun lọ́wọ́ lọ.+
12 Nígbà náà ni alákòóso ìbílẹ̀,+ ní rírí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, di onígbàgbọ́, níwọ̀n bí háà ti ṣe é sí ẹ̀kọ́ Jèhófà.
13 Wàyí o, àwọn ènìyàn náà, pa pọ̀ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ṣíkọ̀ sójú òkun láti Páfò, wọ́n sì dé Pẹ́gà ní Panfílíà.+ Ṣùgbọ́n Jòhánù+ fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà+ sí Jerúsálẹ́mù.
14 Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n tẹ̀ síwájú láti Pẹ́gà, wọ́n sì wá sí Áńtíókù ní Písídíà, bí wọ́n sì ti wọ sínágọ́gù+ ní ọjọ́ sábáàtì, wọ́n mú ìjókòó.
15 Lẹ́yìn kíka Òfin+ àti ìwé àwọn Wòlíì ní gbangba, àwọn alága+ sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.”
16 Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù dìde, bí ó sì ti ju+ ọwọ́ rẹ̀, ó wí pé:
“Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ gbọ́.+
17 Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba ńlá wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà ga ní àkókò tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú apá ríròkè.+
18 Fún sáà tí ó tó nǹkan bí ogójì ọdún+ ni ó sì fi fara da ìṣesí wọn ní aginjù.
19 Lẹ́yìn pípa orílẹ̀-èdè méje run ní ilẹ̀ Kénáánì, ó fi kèké pín ilẹ̀ náà fún wọn:+
20 gbogbo èyíinì láàárín nǹkan bí irínwó ó lé àádọ́ta ọdún.
“Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di ìgbà Sámúẹ́lì wòlíì.+
21 Ṣùgbọ́n láti ìgbà náà lọ, wọ́n fi dandan béèrè fún ọba,+ Ọlọ́run sì fún wọn ní Sọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Kíṣì, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ fún ogójì ọdún.
22 Lẹ́yìn tí ó sì mú un kúrò,+ ó gbé Dáfídì dìde fún wọn gẹ́gẹ́ bí ọba,+ ẹni tí ó jẹ́rìí nípa rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Èmi ti rí Dáfídì ọmọkùnrin Jésè,+ ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn,+ ẹni tí yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.’+
23 Láti inú ọmọ+ ọkùnrin yìí, ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, ni Ọlọ́run ti mú olùgbàlà+ kan, Jésù, wá fún Ísírẹ́lì,
24 lẹ́yìn tí Jòhánù,+ ṣáájú ìwọlé dé Ẹni+ yẹn, ti wàásù ní gbangba fún gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì nípa ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà.
25 Ṣùgbọ́n bí Jòhánù ti ń mú ipa ọ̀nà rẹ̀ ṣẹ, òun a sọ pé, ‘Kí ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kọ́ ni ẹni náà. Ṣùgbọ́n, wò ó! ẹnì kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, sálúbàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó láti tú.’+
26 “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin ọmọ ìlà ìran Ábúráhámù àti àwọn yòókù wọnnì láàárín yín tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí ni a ti rán jáde sí wa.+
27 Nítorí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti àwọn olùṣàkóso wọn kò mọ Ẹni+ yìí, ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́, wọ́n mú àwọn ohun tí a sọ láti ẹnu àwọn Wòlíì+ ṣẹ, àwọn ohun tí a ń kà sókè ní gbogbo Sábáàtì,
28 bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìdí kankan fún ikú,+ wọ́n fi dandan béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kí a fi ikú pa á.+
29 Wàyí o, nígbà tí wọ́n ṣàṣeparí ohun gbogbo tí a kọ̀wé nípa rẹ̀,+ wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi,+ wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì ìrántí+ kan.
30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú;+
31 fún ọjọ́ púpọ̀, ó di rírí fún àwọn tí wọ́n ti bá a gòkè láti Gálílì lọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìnyí fún àwọn ènìyàn.+
32 “Nítorí náà, ìhìn rere nípa ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba ńlá+ ni àwa sì ń polongo fún yín,
33 pé Ọlọ́run ti mú un ṣẹ pátápátá fún àwa ọmọ wọn ní ti pé ó jí Jésù dìde;+ àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ nínú sáàmù kejì pé, ‘Ìwọ ni ọmọ mi, mo ti di Baba rẹ lónìí yìí.’+
34 Òtítọ́ yẹn pé ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí a sì yàn án tẹ́lẹ̀ pé kì yóò tún padà sínú ìdíbàjẹ́ mọ́, ni òun ti sọ ní ọ̀nà yìí pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò fún yín ní àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì, àwọn èyí tí ó ṣeé gbíyè lé.’+
35 Nítorí bẹ́ẹ̀, ó tún sọ nínú sáàmù mìíràn pé, ‘Ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’+
36 Nítorí Dáfídì,+ ní ọwọ́ kan, ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tí a fi hàn kedere ní ìran tirẹ̀, ó sì sùn nínú ikú, a sì tẹ́ ẹ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, ó sì rí ìdíbàjẹ́ ní tòótọ́.+
37 Ní ọwọ́ kejì, ẹni tí Ọlọ́run gbé dìde kò rí ìdíbàjẹ́.+
38 “Nítorí náà, kí ó di mímọ̀ fún yín, ẹ̀yin ará, pé nípasẹ̀ Ẹni yìí ni a fi ń kéde ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ fún yín;+
39 àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò ti lè polongo yín ní aláìjẹ̀bi nípasẹ̀ òfin Mósè,+ gbogbo ẹni tí ó bá gbà gbọ́ ni a ń polongo ní aláìjẹ̀bi nípasẹ̀ Ẹni yìí.+
40 Nítorí náà, ẹ rí i pé ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì kò wá sórí yín,
41 ‘Ẹ kíyè sí i, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ó ṣe yín ní kàyéfì, kí ẹ sì pòórá dànù, nítorí pé èmi ń ṣe iṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ yín, iṣẹ́ kan tí ẹ kì yóò gbà gbọ́ lọ́nàkọnà bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ṣèròyìn rẹ̀ fún yín ní kúlẹ̀kúlẹ̀.’”+
42 Wàyí o, nígbà tí wọ́n ń jáde lọ, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà pé kí a sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn ní sábáàtì tí ó tẹ̀ lé e.+
43 Nítorí náà, lẹ́yìn tí wọ́n tú àpéjọ sínágọ́gù ká, ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà,+ àwọn tí ó jẹ́ pé ní bíbá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀+ wọ́n láti máa bá a lọ nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+
44 Ní sábáàtì tí ó tẹ̀ lé e, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú ńlá náà ni ó kóra jọpọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+
45 Nígbà tí àwọn Júù tajú kán rí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n kún fún owú,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtakò lọ́nà ìsọ̀rọ̀ òdì sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.+
46 Nítorí náà, ní fífi àìṣojo sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wí pé: “Ó pọn dandan kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín.+ Níwọ̀n bí ẹ ti ń sọ́gọ rẹ̀ dànù+ kúrò lọ́dọ̀ yín, tí ẹ kò sì ka ara yín yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó! a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+
47 Ní ti tòótọ́, Jèhófà ti pàṣẹ fún wa ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé, ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ fún ọ láti jẹ́ ìgbàlà títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.’”+
48 Nígbà tí àwọn tí í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀, wọ́n sì ń yin ọ̀rọ̀ Jèhófà+ lógo, gbogbo àwọn tí wọ́n sì ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun di onígbàgbọ́.+
49 Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ń mú lọ sí gbogbo ilẹ̀ náà.+
50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù+ ru àwọn obìnrin tí ó ní ìsì rere sókè, àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run àti àwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú ńlá náà, wọ́n sì gbé inúnibíni+ dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn òde ààlà wọn.
51 Àwọn wọ̀nyí gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dànù lòdì sí wọn,+ wọ́n sì lọ sí Íkóníónì.
52 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń bá a lọ ní kíkún fún ìdùnnú+ àti ẹ̀mí mímọ́.

