Ẹ́sírà 3:1-13
3 Nígbà tí oṣù keje+ dé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú àwọn ìlú ńlá wọn. Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì+ kan ṣoṣo sí Jerúsálẹ́mù.+
2 Jéṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àlùfáà àti Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sì tẹ̀ síwájú láti dìde, wọ́n sì mọ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, láti máa rú àwọn ẹbọ sísun lórí rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ+ sínú òfin Mósè, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́.
3 Nítorí náà, wọ́n fìdí pẹpẹ náà múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní àyè rẹ̀,+ nítorí pé jìnnìjìnnì dé bá wọn nítorí àwọn ènìyàn ilẹ̀ wọnnì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà lórí rẹ̀, àwọn ẹbọ sísun òwúrọ̀ àti ti ìrọ̀lẹ́.+
4 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà+ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé+ rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ẹbọ sísun ọjọ́ dé ọjọ́ ní iye-iye, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àfilélẹ̀ ohun tí ó yẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.+
5 Lẹ́yìn ìgbà náà ni ọrẹ ẹbọ+ sísun ìgbà gbogbo wáyé àti èyí tí ó wà fún àwọn òṣùpá+ tuntun àti fún gbogbo àsìkò àjọyọ̀+ tí a sọ di mímọ́ ti Jèhófà, àti fún olúkúlùkù ẹni tí ó fi tinútinú rú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ sí Jèhófà.
6 Láti ọjọ́ kìíní oṣù+ keje síwájú ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà, àní nígbà tí a kò tíì fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀.
7 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi owó+ fún àwọn agékùúta+ àti fún àwọn oníṣẹ́ ọnà,+ àti àwọn ohun jíjẹ+ àti ohun mímu àti òróró+ fún àwọn ọmọ Sídónì+ àti àwọn ará Tírè,+ láti kó àwọn ẹ̀là gẹdú kédárì wá láti Lẹ́bánónì+ sí òkun tí ó wà ní Jópà,+ ní ìbámu pẹ̀lú ìyọ̀ǹda tí wọ́n gbà láti ọwọ́ Kírúsì+ ọba Páṣíà.
8 Àti ní ọdún kejì tí wọ́n wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù, ní oṣù+ kejì, ni Serubábélì+ ọmọkùnrin Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jéṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì àti ìyókù àwọn arákùnrin wọn, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, àti gbogbo àwọn tí ó jáde wá láti oko òǹdè+ sí Jerúsálẹ́mù bẹ̀rẹ̀; wọ́n sì wá fi àwọn ọmọ Léfì+ sípò, láti ẹni ogún ọdún sókè, láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó lórí iṣẹ́ ilé Jèhófà.+
9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jéṣúà,+ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Kádímíélì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Júdà, dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan ṣoṣo láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó lórí àwọn olùṣe iṣẹ́ ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, àti àwọn ọmọkùnrin Hénádádì,+ àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú.
10 Nígbà tí àwọn akọ́lé fi ìpìlẹ̀+ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀, nígbà náà ni àwọn àlùfáà nínú aṣọ+ iṣẹ́ wọn, ti àwọn ti kàkàkí,+ àti àwọn ọmọ Léfì tí í ṣe àwọn ọmọ Ásáfù,+ ti àwọn ti aro,+ dìde dúró láti yin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìdarí+ tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ṣe.
11 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn padà nípa yíyin+ Jèhófà àti fífi ọpẹ́ fún un, “nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere,+ nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí Ísírẹ́lì wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ Ní ti gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n kígbe rara+ ní yíyin Jèhófà lórí fífi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀.
12 Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì àti àwọn olórí ìdí ilé baba,+ àwọn àgbààgbà tí ó rí ilé àtijọ́,+ sì ń fi ohùn rara sunkún+ nígbà fífi ìpìlẹ̀+ ilé yìí lélẹ̀ ní ìṣojú wọn, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ń gbé ohùn igbe ìdùnnú sókè.+
13 Fún ìdí yìí, àwọn ènìyàn náà kò mọ ìyàtọ̀ láàárín ìró igbe ayọ̀ yíyọ̀+ àti ìró ẹkún sísun àwọn ènìyàn náà, nítorí tí àwọn ènìyàn náà ń kígbe rara, ìró náà ni a sì gbọ́, àní ní ọ̀nà jíjìnréré.

