Ẹ́sírà 2:1-70
2 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin àgbègbè+ abẹ́ àṣẹ tí ó gòkè lọ kúrò ní oko òǹdè àwọn ìgbèkùn+ tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn+ ní Bábílónì, tí wọ́n sì padà+ lẹ́yìn náà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà,+ olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀;
2 àwọn tí wọ́n bá Serubábélì+ wá ni, Jéṣúà,+ Nehemáyà, Seráyà,+ Reeláyà, Módékáì, Bílíṣánì, Mísípárì, Bígífáì, Réhúmù, Báánáhì.
Iye àwọn ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì:
3 Àwọn ọmọkùnrin Páróṣì,+ ẹgbọ̀kànlá ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n;
4 àwọn ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà,+ òjì-dín-nírínwó ó lé méjìlá;
5 àwọn ọmọkùnrin Áráhì,+ ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n;
6 àwọn ọmọkùnrin Pahati-móábù,+ ti àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù,+ ẹgbẹ̀rìnlá ó lé méjìlá;
7 àwọn ọmọkùnrin Élámù,+ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́fà;
8 àwọn ọmọkùnrin Sátù,+ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé márùn-ún;
9 àwọn ọmọkùnrin Sákáì,+ òjì-dín-lẹ́gbẹ̀rin;
10 àwọn ọmọkùnrin Bánì,+ òjì-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì;
11 àwọn ọmọkùnrin Bébáì,+ ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógún;
12 àwọn ọmọkùnrin Ásígádì,+ ẹgbẹ̀fà ó lé méjìlélógún;
13 àwọn ọmọkùnrin Ádóníkámù,+ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà;
14 àwọn ọmọkùnrin Bígífáì,+ ẹgbàá ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta;
15 àwọn ọmọkùnrin Ádínì,+ àádọ́ta-lé-nírínwó ó lé mẹ́rin;
16 àwọn ọmọkùnrin Átérì,+ ti Hesekáyà, méjì-dín-lọ́gọ́rùn-ún;
17 àwọn ọmọkùnrin Bísáì,+ ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́tàlélógún;
18 àwọn ọmọkùnrin Jórà, méjì-lé-láàádọ́fà;
19 àwọn ọmọkùnrin Háṣúmù,+ okòó-lérúgba ó lé mẹ́ta;
20 àwọn ọmọkùnrin Gíbárì,+ márùn-dín-lọ́gọ́rùn-ún;
21 àwọn ọmọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ mẹ́tàlélọ́gọ́fà;
22 àwọn ọkùnrin Nétófà,+ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta;
23 àwọn ọkùnrin Ánátótì,+ méjì-dín-láàádóje;
24 àwọn ọmọkùnrin Ásímáfẹ́tì,+ méjìlélógójì;
25 àwọn ọmọkùnrin Kiriati-jéárímù,+ Kéfírà àti Béérótì, òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta;
26 àwọn ọmọkùnrin Rámà+ àti Gébà,+ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún;
27 àwọn ọkùnrin Míkímásì,+ méjìlélọ́gọ́fà;
28 àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì,+ okòó-lérúgba ó lé mẹ́ta;
29 àwọn ọmọkùnrin Nébò,+ méjì-lé-láàádọ́ta;
30 àwọn ọmọkùnrin Mágíbíṣì, mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ;
31 àwọn ọmọkùnrin Élámù+ kejì, ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́fà;
32 àwọn ọmọkùnrin Hárímù,+ okòó-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún;
33 àwọn ọmọkùnrin Lódì,+ Hádídì+ àti Ónò,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé márùndínlọ́gbọ̀n;
34 àwọn ọmọkùnrin Jẹ́ríkò,+ òjì-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún ó lé márùn-ún;
35 àwọn ọmọkùnrin Sénáà,+ egbèjìdínlógún ó lé ọgbọ̀n.
36 Àwọn àlùfáà:+ Àwọn ọmọkùnrin Jedáyà+ ti ilé Jéṣúà,+ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n;
37 àwọn ọmọkùnrin Ímérì,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì;
38 àwọn ọmọkùnrin Páṣúrì,+ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tà-dín-láàádọ́ta;
39 àwọn ọmọkùnrin Hárímù,+ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún.
40 Àwọn ọmọ Léfì:+ Àwọn ọmọkùnrin Jéṣúà+ àti Kádímíélì,+ ti àwọn ọmọkùnrin Hodafáyà,+ mẹ́rìn-lé-láàádọ́rin.
41 Àwọn akọrin, àwọn ọmọkùnrin Ásáfù,+ méjì-dín-láàádóje.
42 Àwọn ọmọkùnrin àwọn aṣọ́bodè, àwọn ọmọkùnrin Ṣálúmù,+ àwọn ọmọkùnrin Átérì,+ àwọn ọmọkùnrin Tálímónì,+ àwọn ọmọkùnrin Ákúbù,+ àwọn ọmọkùnrin Hátítà,+ àwọn ọmọkùnrin Ṣóbáì, gbogbo wọn lápapọ̀, mọ́kàndínlógóje.
43 Àwọn Nétínímù:+ Àwọn ọmọkùnrin Síhà, àwọn ọmọkùnrin Hásúfà, àwọn ọmọkùnrin Tábáótì,+
44 àwọn ọmọkùnrin Kérósì, àwọn ọmọkùnrin Síáhà, àwọn ọmọkùnrin Pádónì,+
45 àwọn ọmọkùnrin Lébánà, àwọn ọmọkùnrin Hágábà, àwọn ọmọkùnrin Ákúbù,
46 àwọn ọmọkùnrin Hágábù, àwọn ọmọkùnrin Sálímáì,+ àwọn ọmọkùnrin Hánánì,
47 àwọn ọmọkùnrin Gídélì, àwọn ọmọkùnrin Gáhárì,+ àwọn ọmọkùnrin Reáyà,
48 àwọn ọmọkùnrin Résínì,+ àwọn ọmọkùnrin Nékódà, àwọn ọmọkùnrin Gásámù,
49 àwọn ọmọkùnrin Úúsà, àwọn ọmọkùnrin Páséà,+ àwọn ọmọkùnrin Bésáì,
50 àwọn ọmọkùnrin Ásínà, àwọn ọmọkùnrin Méúnímù, àwọn ọmọkùnrin Néfúsímù;+
51 àwọn ọmọkùnrin Bákíbúkì, àwọn ọmọkùnrin Hákúfà, àwọn ọmọkùnrin Háhọ́rì,+
52 àwọn ọmọkùnrin Básílútù, àwọn ọmọkùnrin Méhídà, àwọn ọmọkùnrin Háṣà,+
53 àwọn ọmọkùnrin Bákósì, àwọn ọmọkùnrin Sísérà, àwọn ọmọkùnrin Téémà,+
54 àwọn ọmọkùnrin Nesáyà, àwọn ọmọkùnrin Hátífà.+
55 Àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì:+ Àwọn ọmọkùnrin Sótáì, àwọn ọmọkùnrin Sóférétì, àwọn ọmọkùnrin Pérúdà,+
56 àwọn ọmọkùnrin Jálà, àwọn ọmọkùnrin Dákónì, àwọn ọmọkùnrin Gídélì,+
57 àwọn ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà, àwọn ọmọkùnrin Hátílì, àwọn ọmọkùnrin Pokereti-hásébáímù, àwọn ọmọkùnrin Ámì.+
58 Gbogbo Nétínímù+ àti àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì jẹ́ irínwó ó dín mẹ́jọ.+
59 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó gòkè lọ láti Tẹli-mélà, Tẹli-háṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, wọn kò sì lè sọ ilé baba wọn àti orírun wọn,+ yálà wọ́n jẹ́ ara Ísírẹ́lì:
60 àwọn ọmọkùnrin Deláyà, àwọn ọmọkùnrin Tobáyà, àwọn ọmọkùnrin Nékódà,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì.
61 Àti lára àwọn ọmọkùnrin àwọn àlùfáà:+ àwọn ọmọkùnrin Habáyà, àwọn ọmọkùnrin Hákósì,+ àwọn ọmọkùnrin Básíláì,+ tí ó fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Básíláì,+ ọmọ Gílíádì ṣe aya, tí a sì wá ń fi orúkọ wọn pè é.
62 Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó wá àkọsílẹ̀ orúkọ wọn, láti fi ìdí ìtàn ìlà ìdílé wọn múlẹ̀ ní gbangba, wọn kò sì rí tiwọn, a sì dènà wọn láti má ṣe wọ inú iṣẹ́ àlùfáà+ nítorí a kà wọ́n sí eléèérí.
63 Nítorí náà, ẹni tí ó jẹ́ Tíṣátà+ wí fún wọn pé wọn kò lè jẹ+ nínú àwọn ohun mímọ́ jù lọ títí àlùfáà kan yóò fi dìde dúró pẹ̀lú Úrímù+ àti Túmímù.
64 Gbogbo ìjọ náà pátá gẹ́gẹ́ bí àwùjọ+ kan ṣoṣo jẹ́ ẹ̀gbàá mọ́kànlélógún ó lé òjì-dín-nírínwó,+
65 yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin wọn àti àwọn ẹrúbìnrin wọn, àwọn wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà-dín-lógójì ó lé mẹ́tàdínlógójì; wọ́n sì ní igba ọkùnrin akọrin+ àti obìnrin akọrin.
66 Ẹṣin wọn jẹ́ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin, ìbaaka wọn jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún,+
67 ràkúnmí wọn jẹ́ irínwó ó lé márùndínlógójì, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.+
68 Àwọn kan báyìí lára àwọn olórí+ ìdí ilé baba,+ nígbà tí wọ́n wá sínú ilé Jèhófà,+ èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ fún ilé Ọlọ́run tòótọ́, láti mú kí ó dúró ní àyè rẹ̀.+
69 Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n mú wúrà+ wá fún àwọn ìpèsè àfiṣiṣẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rún owó dírákímà, àti fàdákà,+ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n mínà, àti ọgọ́rùn-ún aṣọ+ àwọn àlùfáà.
70 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti àwọn kan lára àwọn ènìyàn náà,+ àti àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè àti àwọn Nétínímù sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú ìlú ńlá wọn, àti gbogbo Ísírẹ́lì nínú ìlú ńlá wọn.+

