Ẹ́sírà 1:1-11
1 Àti ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Jèhófà láti ẹnu Jeremáyà+ ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí,+ tí ó fi mú kí igbe+ kan la gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀ kọjá, a sì kọ̀wé+ rẹ̀ pẹ̀lú, pé:
2 “Èyí ni ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà wí,+ ‘Gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé ni Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run+ ti fi fún mi,+ òun fúnra rẹ̀ sì ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tí ó wà ní Júdà.
3 Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀, kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.+ Nítorí náà, kí ó gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́—òun ni Ọlọ́run+ tòótọ́—èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.+
4 Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ́ kù ní gbogbo ibi tí ó ti ń ṣe àtìpó,+ kí àwọn ènìyàn ibi tí ó ń gbé fi fàdákà àti wúrà àti àwọn ẹrù àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ+ àfínnúfíndọ̀ṣe ṣèrànwọ́ fún un fún ilé Ọlọ́run tòótọ́, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.’”
5 Nígbà náà ni àwọn olórí+ àwọn baba ti Júdà àti ti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì dìde, àní olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ ta ẹ̀mí+ rẹ̀ jí, láti gòkè lọ tún ilé Jèhófà+ kọ́, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.
6 Ní ti gbogbo àwọn tí ó wà yí wọn ká, wọ́n fi àwọn nǹkan èlò fàdákà fún ọwọ́ wọn lókun,+ pẹ̀lú wúrà, pẹ̀lú àwọn ẹrù àti pẹ̀lú àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ohun ààyò, yàtọ̀ sí gbogbo èyí tí a fínnú-fíndọ̀ fi fúnni.+
7 Pẹ̀lúpẹ̀lù, Kírúsì Ọba alára kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà+ jáde wá, èyí tí Nebukadinésárì kó jáde láti Jerúsálẹ́mù,+ tí ó sì kó wọn sínú ilé ọlọ́run+ rẹ̀.
8 Kírúsì ọba Páṣíà sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn jáde wá lábẹ́ ìkáwọ́ Mítírédátì olùtọ́jú ìṣúra, ó sì ka iye wọn fún Ṣẹṣibásà+ tí í ṣe ìjòyè Júdà.+
9 Wàyí o, iye wọn nìyí: ọgbọ̀n ohun èlò onírìísí apẹ̀rẹ̀ tí a fi wúrà ṣe, ẹgbẹ̀rún ohun èlò onírìísí apẹ̀rẹ̀ tí a fi fàdákà ṣe, ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ohun èlò àfidípò,
10 ọgbọ̀n àwokòtò+ kéékèèké tí a fi wúrà ṣe, irínwó ó lé mẹ́wàá àwokòtò kéékèèké onípò kejì tí a fi fàdákà ṣe, ẹgbẹ̀rún àwọn nǹkan èlò mìíràn.
11 Gbogbo nǹkan èlò wúrà àti ti fàdákà jẹ́ ẹgbẹ̀tàdínlọ́gbọ̀n. Gbogbo rẹ̀ ni Ṣẹṣibásà+ kó gòkè wá, pa pọ̀ pẹ̀lú kíkó àwọn ìgbèkùn+ gòkè wá láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù.

