Ẹ́kísódù 35:1-35

35  Lẹ́yìn náà, Mósè pe àpéjọ gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì pátá, ó sì wí fún wọn pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ, kí a lè tẹ̀ lé wọn:+  Ọjọ́ mẹ́fà ni kí a fi ṣe iṣẹ́,+ ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ohun mímọ́ lójú yín, sábáàtì ìsinmi pátápátá fún Jèhófà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ nínú rẹ̀ ni a ó fi ikú pa.+  Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ dá iná nínú ibi gbígbé yín èyíkéyìí ní ọjọ́ sábáàtì.”  Mósè sì ń bá a lọ láti wí fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ, pé,  ‘Láti àárín yín, ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà.+ Kí gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán+ mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Jèhófà, èyíinì ni, wúrà àti fàdákà àti bàbà+  àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti irun ewúrẹ́+  àti awọ àgbò tí a pa láró pupa àti awọ séálì àti igi bọn-ọ̀n-ní  àti òróró fún orísun ìmọ́lẹ̀ àti òróró básámù fún òróró àfiyanni àti fún tùràrí onílọ́fínńdà+  àti òkúta ónísì àti òkúta ìlẹ̀mọ́ ara éfódì+ àti ara aṣọ ìgbàyà.+ 10  “‘Sì jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó ní ọkàn-àyà ọgbọ́n+ láàárín yín wá ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ, 11  èyíinì ni, àgọ́ ìjọsìn pẹ̀lú àgọ́ rẹ̀ àti ìbòrí rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀ àti àwọn férémù rẹ̀, àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀, àwọn ọwọ̀n rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀; 12  Àpótí+ náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀,+ ìbòrí+ náà àti aṣọ ìkélé+ àtabojú; 13  tábìlì+ náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ àti búrẹ́dì àfihàn;+ 14  àti ọ̀pá fìtílà+ ìtànmọ́lẹ̀ àti àwọn nǹkan èlò rẹ̀ àti àwọn fìtílà rẹ̀ àti òróró+ ìtànmọ́lẹ̀; 15  àti pẹpẹ tùràrí+ àti àwọn ọ̀pá rẹ̀; àti òróró àfiyanni àti tùràrí onílọ́fínńdà;+ àti àtabojú ẹnu ọ̀nà fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìjọsìn; 16  pẹpẹ+ ọrẹ ẹbọ sísun àti àgbàyan bàbà tí ó wà fún un, àwọn ọ̀pá rẹ̀ àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀; bàsíà+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀; 17  àwọn àsokọ́ àgbàlá,+ àwọn ọwọ̀n rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀; àti àtabojú ẹnubodè àgbàlá; 18  àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ ti àgọ́ ìjọsìn àti àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ ti àgbàlá àti àwọn okùn wọn;+ 19  ẹ̀wù+ iṣẹ́ ọnà àfọwọ́hun fún ṣíṣe ìránṣẹ́ nínú ibùjọsìn náà, ẹ̀wù mímọ́+ fún Áárónì àlùfáà àti ẹ̀wù àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fún ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.’” 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò níwájú Mósè. 21  Lẹ́yìn náà, wọ́n wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́,+ àti olúkúlùkù ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ ru ú sókè, wọ́n mú ọrẹ Jèhófà wá fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti fún ẹ̀wù mímọ́ náà. 22  Wọ́n sì ń wá ṣáá, àwọn ọkùnrin pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin, gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán. Wọ́n mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àsomáṣọ àti àwọn yẹtí àti àwọn òrùka àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ti obìnrin wá, gbogbo onírúurú ohun èlò wúrà, èyíinì ni, olúkúlùkù ẹni tí ó mú ọrẹ ẹbọ fífì ti wúrà wá fún Jèhófà.+ 23  Àti gbogbo àwọn tí a rí fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù lọ́dọ̀ wọn àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti irun ewúrẹ́ àti awọ àgbò tí a pa láró pupa àti awọ séálì, mú wọn wá.+ 24  Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọrẹ fàdákà àti bàbà ṣe ìtọrẹ mú ọrẹ Jèhófà wá, àti gbogbo àwọn tí a rí igi bọn-ọ̀n-ní lọ́dọ̀ wọn fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn náà mú un wá. 25  Gbogbo àwọn obìnrin tí wọ́n gbọ́n ní ọkàn-àyà+ sì fi ọwọ́ wọn rànwú, wọ́n sì ń mú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù wá gẹ́gẹ́ bí òwú ríran àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà. 26  Gbogbo obìnrin tí ọkàn-àyà wọn sún wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n ran irun ewúrẹ́. 27  Àwọn ìjòyè sì mú òkúta ónísì wá, àti òkúta ìlẹ̀mọ́ ara éfódì àti ara aṣọ ìgbàyà,+ 28  àti òróró básámù àti òróró fún ìtànmọ́lẹ̀ àti fún òróró àfiyanni àti fún tùràrí onílọ́fínńdà.+ 29  Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí ọkàn-àyà wọn ru wọ́n sókè láti mú ohun kan wá fún gbogbo iṣẹ́ tí Jèhófà ti pa láṣẹ láti ṣe nípasẹ̀ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe wá fún Jèhófà.+ 30  Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Wò ó, Jèhófà ti fi orúkọ pe Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọkùnrin Úráì ọmọkùnrin Húrì ti ẹ̀yà Júdà. 31  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n, ti òye àti ti ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà kún inú rẹ̀ 32  àti fún ṣíṣe iṣẹ́ ọnà àwọn nǹkan àfọgbọ́nrọ, fún ṣíṣe iṣẹ́ wúrà àti fàdákà àti bàbà,+ 33  àti ṣíṣe iṣẹ́ òkúta láti tò wọ́n àti ṣíṣe iṣẹ́ igi láti ṣe onírúurú nǹkan tí a fi ọgbọ́n hùmọ̀.+ 34  Ó sì ti fí i sínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé kí ó kọ́ni, òun àti Òhólíábù+ ọmọkùnrin Áhísámákì ti ẹ̀yà Dánì. 35  Ó ti fi ọgbọ́n ọkàn-àyà+ kún inú wọn láti ṣe gbogbo iṣẹ́ oníṣẹ́ ọnà àti ti akóṣẹ́-ọnà-sáṣọ+ àti ti olùhun fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró, àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, àti ti olófì, àwọn ọkùnrin tí ń ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́ tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ọnà àwọn nǹkan àfọgbọ́nrọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé